Awọn eeyan ṣedaro lẹyin Dokita Faṣehun, oludasilẹ ẹgbẹ OPC to ku

Spread the love

Ọkan o jọkan awọn eeyan ni wọn ti n fi imọlara wọn han, ti wọn si tun n ranṣẹ ibanikẹdun si idile Dokita Fredrick Fasheun, oludasilẹ ẹgbẹ OPC, to dagbere faye laaarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

 

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lo kọkọ fi atẹjade kan sita, ninu eyi to ti juwe Oloogbe Faṣehun bii akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo ti iru rẹ ṣọwọn laarin awọn eeyan.

 

O ni oloogbe ọhun jẹ ẹnikan to ko ara rẹ nijaanu, ti ko si fẹran irẹjẹ bo ti wu ko mọ, o fi kun un pe iku rẹ ba gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ondo lojiji, o si tun jẹ adanu nla fawọn eeyan orilẹ-ede yii pe wọn padanu iru eeyan bii Dokita Faṣehun lasiko ti a nilo ọgbọn rẹ.

Akeredolu sọ pe titi aye lawọn eeyan yoo maa ranti ipa manigbagbe to ti ko ninu eto oṣelu ati ilana yiyan aṣaaju rere to fi lelẹ ko too dagbere faye.

 

Gomina ana nipinlẹ Ondo, Oluṣẹgun Mimiko, naa sọ ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ pe yoo pẹ pupọ kawọn to le rẹni ti yoo di alafo ati aaye ti Dokita Fasehun fi silẹ lọ.

 

Oun naa juwe rẹ bii ẹni to fi igboya koju awọn amunisin ati ijẹgaba ki ijọba dẹmokiresi ta a wa yii baa le fẹsẹ mulẹ. Mimiko  ni iku rẹ dun oun pupọ pẹlu bo ṣe jẹ pe asiko tawọn eeyan orilẹ-ede yii fẹẹ mọ pataki ṣiṣe atunto, eyi ti oloogbe naa ti n ja fitafita fun latẹyinwa ni iku wọle to mu un lọ.

 

Ninu atẹjade ti Ẹgbẹ Afẹnifẹre fi sita ni wọn ti sọ pe ko si ani-ani pe adanu nla ni iku Dokita Faṣehun jẹ fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii pata.

 

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams, naa ko gbẹyin ninu awọn to fi ẹdun ọkan wọn han lori iku Oloogbe Faṣehun.

 

Ọga awọn OPC ọhun sọ pe bo tilẹ jẹ pe Faṣehun ti fi ipa ati ogun rere lelẹ ko too lọ, sibẹ, ajalu nla niku rẹ lasiko ta a wa yii fun iran Yoruba, Naijiria ati gbogbo agbaye pata.

Ile Dokita Faṣehun to wa lagbegbe Lọgara, loju ọna Marosẹ ilu Ondo si Ọrẹ la kọkọ ṣabẹwo si, ṣugbọn a ko ba ẹnikẹni ninu ile naa, a tun lọ si eyi to kọ si adugbo Dada, lagbegbe Jolaco, loju ọna Marosẹ Ondo si Ileefẹ.

 

Mama agbalagba kan to jẹ aburo Dokita Fasehun nikan la ba nigba ta a ṣabẹwo sile baba rẹ to wa lojule kọkanlelogun, adugbo Okedibo, niluu Ondo, to si jẹ ko ye wa pe ko ti i pẹ pupọ ti aburo rẹ mi-in to n ṣiṣẹ lọọya jade.

 

Akiyesi ta a ṣe ni pe mama ọhun torukọ rẹ n jẹ Adetinunkẹ Osiwekomi (Ọmọ Fasehun), ko ti i rẹni sọ fun un nipa iku ẹgbọn rẹ.

 

Ninu alaye ti mama naa ṣe fun wa lo ti jẹ ka mọ pe ọmọ baba kan naa loun ati Dokita Fasehun, ati pe Oloye Akindojutimi Fasehun, ti i ṣe Lomafẹ ilu Ondo ni baba to bi awọn.

 

 

 

 

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.