Awọn Boko Haramu lo ji wa gbe, gbogbo inu igbo to yi ipinlẹ Ondo ka ni wọn wa-Falọdun

Spread the love

Ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe loju ọna Ọwọ si Ikarẹ, lọsẹ bii meji sẹyin, Ọgbẹni Abiọdun Falọdun, ti ṣalaye ohun toju rẹ ri laarin ọjọ mẹrin pere to fi wa ninu igbekun awọn ajinigbe.

 

Falọdun, iyawo rẹ, Ronkẹ, pẹlu iya iyawo rẹ, Abilekọ Ayewumi Ogunsemore, ni wọn bọ sọwọ awọn ajinigbe loju ọna Ọwọ si Ikarẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọ lọhun-un, lasiko ti wọn n pada bọ lati ibi ayẹyẹ kan ti wọn lọ.

 

Gẹgẹ ba a sẹ gbọ, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja loun atawọn ẹbi rẹ jajabọ lẹyin miliọnu mẹwaa Naira ti wọn san fawọn ajinigbe naa.

 

Eyi lawọn ọrọ ti ọkunrin to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ibilẹ naa ba wa sọ nipa iriri rẹ lọwọ awọn ajinigbe:

 

“Ilu Ọgbagi Akoko, nibi ayẹyẹ igbeyawo kan ta a lọ la ti n bọ lọjọ naa nigba ta a deede rin si asiko tawọn oniṣẹẹbi ọhun n ṣọṣẹ lọwọ. Niṣe ni wọn doju ibọn kọ wa, ti wọn si n yin in leralera, leyii to mu ki n tete da ọkọ duro, ti mo si paaki sẹgbẹẹ kan. Loju ẹsẹ ni wọn ti wọ wa jade ninu ọkọ wọ inu igbo lọ, bo saa ṣe di pe a bẹrẹ irinajo tipatipa wa ree.

‘Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni wọn ji wa gbe, a rin irin wakati meji ninu igbo ki wọn too gba ka sinmi diẹ.

Ba a ṣe sinmi diẹ ni wọn tun ti ko wa lọ sibomi-in, nibi ta a ti ba awọn marun-un mi-in ti wọn ti wa ninu igbekun wọn tẹlẹ, nibẹ la si wa titi di Ọjọruu, Wẹsidee, ti wọn tu gbogbo wa silẹ lẹyin ti wọn ti gbowo nla lọwọ wa.

Mi o ti i jẹ iru iya ti mo jẹ lọwọ awọn ajinigbe naa ri lati ọjọ ti wọn ti bi mi, ojoojumọ ni wọn n fi kobooko lu wa lẹyin ti wọn ti fipa mu gbogbo wa kunlẹ, ti wọn si fi okun irin nla kan de wa mọlẹ.

 

‘Nigba mi-in, wọn aa tu wa silẹ pẹlu aṣẹ pe ka fẹyin lelẹ, ka si kọju si oorun, gbogbo bi wọn ṣe n na wa ta a n pariwo ni wọn n gbe foonu si sipika kawọn ẹbi wa le maa gbọ iya ti wọn fi n jẹ wa ketekete.

 

‘Ilu Maiduguri lawọn ajinigbe ọhun sọ fun wa pe awọn ti wa, afaimọ ni wọn ki i ṣọmọ ẹgbẹ Boko Haraamu, pẹlu ohun ti mo ṣakiyesi nipa wọn.

 

‘Wọn mọ apade ati alude gbogbo inu igbo to yi ipinlẹ Ondo ka patapaata, wọn si mọ ayika ati agbegbe awọn igbo naa daadaa ju awọn ọmọ onilẹ lọ.

 

‘Lai lo maapu tabi irinṣẹ ti wọn fi n mọ ọna, soose ni wọn mu wa rin gbogbo ibi ta a rin ninu igbo, wọn ko si ṣina titi ti wọn fi mu wa de ibi ta a duro si.

 

‘Mo gbọ nigba ti wọn n ba awọn eeyan mi sọrọ pe wọn gbọdọ san ọgọrun-un miliọnu Naira ki wọn too tu mi silẹ, ṣugbọn ti wọn bẹ wọn titi ti wọn fi gba miliọnu mẹwaa Naira lọwọ wọn.

 

‘Ọjọ kan naa ni wọn tu awa mẹjẹẹjọ ta a wa nigbekun wọn silẹ, lẹyin ti wọn gba owo nla lọwọ awọn ẹbi wa.

 

‘Ẹ wo o, pẹlu nnkan ti mo foju ara mi ri ninu igbo, o ṣee ṣe ki apa awọn ẹṣọ alaabo ma ka ọrọ awọn ajinigbe yii mọ bi ijọba ko ba tete wa nnkan ṣe si i’

 

Lọjọ kan naa ti iṣẹle eyi ti Ọgbẹni Falọdun n royin rẹ waye naa ni wọn ji olukọ poli Ọwọ mi-in gbe loju ọna Ọwọ si Ikarẹ, ọjọ keji, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja ni wọn tu u silẹ lẹyin tawọn ẹbi re san miliọnu mẹrin Naira gẹgẹ bii owo itanran.

 

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.