Awọn araalu ti omiyale ba dukia wọn jẹ n beere iranlọwọ ijọba

Spread the love

Ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye lo bajẹ lopin ọsẹ to kọja yii, nigba ti omiyale ya wọ awọn adugbo kan.

Lara awọn agbegbe to fara gba nibi iṣẹlẹ naa ni; Kulende, Harmony Estate, Akerebiata, Garin Alimi ati Isalẹ-Koko.

Bakan naa ni awọn ilu kan nijọba ibilẹ Ẹdu naa fara gba nibi iṣẹlẹ ọhun, nitori ṣe ni omi ba awọn ire oko wọn jẹ, bẹẹ lo si tun wọ awọn ohun-ọsin wọn lọ.

Bii ọsẹ meji sẹyin nijọba ipinlẹ Kwara ati ajọ to n wo bi oju ọjọ ṣe n ri ti n pariwo fun awọn to n gbe lagbegbe ibi ti odo wa lati kuro fun igba diẹ nitori iṣẹlẹ omiyale naa.

Awọn ọkọ ati ile to ri sinu omi naa ko niye. Titi di akoko yii ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ṣi n kabaamọ awọn dukia wọn ti wọn padanu.

Alaga ijọba ibilẹ Edu, Ọgbẹni Umar Belle, rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ naa lati dide iranlọwọ fun awọn to fara kaasa iṣẹlẹ omiyale naa.

Belle sọ pe iṣẹlẹ naa ti sọ ọpọlọpọ awọn to n gbe agbegbe naa di alaini ile lori mọ.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.