Awọn araalu n binu sijọba nitori ọga ileewe to n ja fẹtọọ rẹ ti wọn gbe ju si abule

Spread the love

Lati ọsẹ to kọja ni iroyin naa ti tan kalẹ pe ijọba ipinlẹ Kwara ti gbogun ti Ọga ileewe alakọọbẹrẹ to jẹ ti ijọba to wa ni Ipata, niluu Ilọrin, Arabinrin Lawal Halimat. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe obinrin naa sọrọ lodi si Adari oṣelu nipinlẹ Kwara, Bukọla Saraki.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o mu ki ijọba gbe ọga ileewe naa kuro nileewe Ipata Primary School, to wa niluu Ilọrin, lọ ju sinu oko kan ni Lajiki, nijọba ibilẹ Ilọrin East,lati le  fiya jẹ ẹ fun ohun ti wọn lo ṣe naa.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Kwara ti ni igbesẹ toun gbe naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu nnkan tawọn ẹẹyan sọ pe ọga ileewe naa sọ lodi si Saraki, ṣugbọn ọrọ ọhun so mọ ara wọn pupọ to si jẹ pe oko ọrọ lawọn araalu to gbọ nipa iṣẹlẹ naa n sọ lu ijọba.

ALAROYE gbọ pe akẹẹkọ ileewe ẹkọṣẹ olukọ kan, Kingsley College of Education, to wa lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, to n ṣeto idanrawo, iyẹn teaching practice lo gbọ ibi ti Lawal Halimat ti n sọrọ tako awọn adari oṣelu nipinlẹ Kwara, iyẹn lo fọgbọn ka ohun rẹ kalẹ sori foonu to si gbe e lọ si ọfiisi ipolongo Saraki, iyẹn Mandate Constituency Office ti Alhaji Musa Abdullahi n dari.

Bi wọn ṣe ni Abdullahi gbọ bi Halimat ṣe n sọ ọrọ lu Saraki atawọn adari oṣelu Kwara lo fa ibinu ti ọrọ ọhun fi de ẹti ijọba to gba ọga ileewe naa sẹnu iṣẹ.

Lai fi akoko ṣofo bi wọn ṣe paṣẹ fun ọga ileewe naa lati fi ibi to wa silẹ ko si kọri sileewe alakọọbẹrẹ Lajiki, to jẹ ọkan lara awọn abule Ilọrin lati maa ṣakoso nibẹ.

Akọroyin wa gbọ pe akẹẹkọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Soliu Balikis, ti n wa ojurere ni Mandate yii tẹlẹ, nigba to gbọ bi Arabinrin Lawal ṣe n sọko ọrọ lu ijọba nitori bi wọn ko ṣe sanwo oṣu fawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ lo lo anfaani naa lati le wọle si wọn lara ni ọfiisi ABS to wa ni Mandate naa.

Igbesẹ tijọba gbe lati fiya jẹ ọga ileewe naa ni ko dun mọ awọn araalu ninu, wọn ni o jẹ ohun itiju fun ijọba lati maa fiya jẹ oṣiṣẹ to n beere fun ẹtọ rẹ.

Awọn araalu ni ọrọ bi ijọba ko ṣe le san owo oṣu ki i ṣe ohun to pamọ fawọn araalu rara, ohun to daju kedere ni, nitori naa ko yẹ ki ijọba fiya jẹ ẹnikẹni to ba sọrọ nipa rẹ. Wọn ni bi wọn ko ba fẹẹ ki awọn eeyan sọrọ nipa rẹ o yẹ ki wọn wa gbogbo ọna lati san ohun ti wọn jẹ fawọn oṣiṣẹ wọn.

Awọn araalu waa kesi ijọba lati da obinrin naa pada sileewe to wa tẹlẹ, bi wọn ba si fẹẹ ṣi i nipo o gbọdọ jẹ lọna to tẹle ofin, ki i ṣe lati ọfiisi Saraki lo yẹ ko ti waye.

Ninu awijare rẹ, Oluranlọwọ pataki Gomina Ahmed l’ẹka iroyin, Muideen Akorede, sọ pe ọfiisi Sẹnẹtọ Saraki ko lọwọ ninu iṣakoso awọn oṣiṣẹ ijọba, nitori naa ẹsun ti wọn fi kan Alhaji Abdullahi ko lẹsẹ nilẹ rara.

Akorede sọ pe: “A ti n gbọ kaakiri paapaa julọ lori ẹrọ ayelujara pe ọfiisi ipolongo adari ile igbimọ aṣofin agba, Dokita Bukọla Saraki, Mandate lo gba lẹta iṣipopada fun Arabinrin Lawal Halimat to jẹ ọga ileewe, Ipata Primary School A, Ilorin, lọ si Lajiki Primary School, pe nitori to n sọrọ tako Saraki ati ijọba Kwara. Irọ patapata ni o.

“Loootọ ni wọn ṣi Arabinrin Lawal nipo pada, ṣugbọn Iyẹn ojuṣe ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ jale-jako, SUBEB ni. Iṣpopada yii ko lọwọ ẹnikẹni laarin ijọba tabi lode ninu rara.

“Ọfiisi Saraki’s Mandate Constituency ko ni aṣẹ kankan lori iṣipopada olukọ tabi ọga ileewe ijọba kankan. Bakan naa ni ọfiisi ọhun ko lọwọ ninu bi wọn ṣe gbe ọga ileewe naa kuro”.

O ni iṣipopada ọga ileewe naa ti ajọ SUBEB ṣe jẹ ọna lati mu isakoso ileewe naa lọ daadaa ni, wọn si ṣe e lai lọwọ ẹnikẹni ninu.

 

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.