Awọn araalu lawọn ko fẹ ọba tuntun niluu Owo *Afi bijọba ba yanju iku Olowo tawọn kan pa

Spread the love

Ijọba ibilẹ Guusu Yewa ni ilu kan ti wọn n pe ni Owo wa, nipinlẹ Ogun. Kabiyesi Ọba Patrick Oyeniran Fasinu lọba wọn nibẹ titi di ọdun 2017 tawọn kan pa a nigba to n bọ lati ipade awọn ọba.

Ilu naa leto ti bẹrẹ lati fọba mi-in jẹ bayii, gẹgẹ bi a sẹ gbọ, ṣugbọn awọn araalu ti fariga funjọba.

Ọjọbọ,ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin yii, lawọn eeyan kan kuro ni Owo, ti wọn wa si ọfiisi awọn akọroyin to wa l’Oke-Ilewo, l’Abẹokuta, pẹlu oriṣiiriṣii akọle ti wọn fi n kede pe awọn ko fẹ ọba tuntun niluu Owo, afi kijoba kọkọ wa awọn to pa ọba awọn to waja jade.

Iwọde wọn naa ki i ṣe tija, wọọrọwọ ni. Aburo ọba to waja naa, Ọmọọba Matthew Ọlanipẹkun Fasinu, to ba awọn akọroyin sọrọ lorukọ awọn ti wọn jọ wọde ṣalaye pe awọn ko fẹ ki ọba tuntun jẹ ni Owo lasiko yii.

O  ni kijọba ṣi dawọ ẹ duro na. Ọmọọba naa ṣalaye pe awọn to fẹẹ fọba tuntun jẹ yii ko tẹle ilana, bii igba ti wọn kan fẹẹ la le araalu lọwọ ni.

O fi ibanujẹ rẹ han si bo ṣe jẹ pe awọn ti wọn pa Ọba Fasinu ti n jaye ori wọn kiri ilu, o ni ijọba ipinlẹ Ogun ko ṣe nnkan kan fun wọn mọ. Ọba mi-in ni wọn fẹẹ fi jẹ lai yanju ohun to fa iku ẹgbọn oun.

Loootọ lọrọ iku Ọba Fasinu Patrick wa ni kootu, ti wọn si mu ọpọlọpọ afurasi lori iku ẹ nigba to ṣẹlẹ, ṣugbọn ẹjọ naa ko ti i pari.

Eyi naa lo fa a tawọn eeyan ilu fi ni awọn ko fẹ ọba mi-in, kijọba Amosun ṣi duro titi tile-ẹjọ yoo fi yanju iku ọba to waja latọwọ awọn aṣekupani.

Ipade awọn lọbalọba ti wọn ṣe n’Ilaro ni Ọba Partick Fasinu lọ, igba to n bọ lawọn eeyan kan da a lọna, ti wọn si pa a.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bashir Makama, lawọn to wọde yii ni kawọn oniroyin ba awọn sọ fun, pe ko ma jẹ ki ẹnikẹni waa fọba jẹ niluu awọn o, ko ma baa di pe wahala yoo ṣẹlẹ, tabi ti itajẹsilẹ yoo waye.

Lati gbọ ti ẹnu ijọba lori ọrọ yii, ALAROYE pe kọmiṣanna fọrọ oye jije nipinlẹ Ogun, Oloye Jide Ojuko. Baba naa ko gbe ipe rẹ, lẹyin naa la fi atẹjiṣẹ ranṣẹ, ṣugbọn ko ti i fesi titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.