Awọn ara ijọba ibilẹ Moro tako igbega tijọba ṣe fawọn ọba

Spread the love

Awọn ara ijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, ti ni bii ẹni fari apa kan da apa kan si lọrọ igbega awọn ọba alaye atawọn oloye tijọba ṣe laipẹ yii lẹkun ***Kwara South jẹ.

Laipẹ yii ni Gomina Abdulfatah Ahmed ṣegbega fawọn ọba to wa nipele kẹrin, to si fun wọn niwee igbega wọn. Bakan naa lawọn oloye ilu kan naa gbawe iyansipo wọn.

Gẹgẹ bawọn araalu ṣe sọ, igbesẹ to dara nijọba gbe nipa igbega awọn ọba, nitori ipa ti wọn n ko lori ipese aabo, mimu alaafia jọba niluu, ati bi wọn ṣe n ṣatilẹyin fun ijọba. Ṣugbọn awọn ri i gẹgẹ bii ohun ti ko tọna lati ṣe bẹẹ lẹkun Gusu Kwara nikan.

Wọn ni gbogbo awọn ọba atawọn oloye ilu kaakiri ipinlẹ Kwara lo n kopa kan naa lagbegbe wọn, nitori naa, ohun to yẹ awọn ẹlẹgbẹ wọn tijọba ṣe agbega fun yẹ awọn naa.

Labẹ asia awọn ọmọ ijọba ibilẹ Moro tọrọ kan, awọn eeyan ọhun ni gbogbo awọn ijọba to ti jẹ sẹyin ni wọn ti gba awọn ọba agbegbe naa sẹgbẹẹ, ti wọn n fi ẹtọ wọn du wọn.

Wọn ni lara wọn ni Ọhọrọ tilu Shao ati ọba ilu Jebba tawọn alakooso ijọba igba naa lọdun 1903 da mọ, ti wọn si tun ṣegbega fun wọn. Bẹẹ nijọba Adamu Attah lọdun 1983 ṣe.

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn ijọba ologun ti ọdun 1985 ati ijọba alagbada ọdun 2003 tako igbega naa lai nidii kan pato ti wọn fi ṣe bẹẹ.

Eyi waye lẹyin tijọba Mohammed Lawal da awọn ọba naa pada sipele kẹta to yẹ ki wọn wa. Wọn ni lati ọdun 2014 tile-ẹjọ giga tilu Ilọrin ti paṣẹ lati da igbega Ọba Jẹbba, Alhaji Abdulkadir Adebara, pada, ijọba kọ lati tẹle aṣẹ naa.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.