Awọn anfaani to wa ninu ewe ati eso gilọfavvvv

Spread the love

Mo ti bẹrẹ si i ṣe alaye nipa bi awọn eso igi kan ti wulo fun anfaani ara wa ni ọsẹ meji sẹyin. Ni asiko yii, oriṣiiriṣii aiasn lo gbode kan nitori pe awa ọmọ eeyan ti jinna si awọn ounjẹ ti Ọlọrun da lati ṣe ara wa loore. Ti a ba wo awọn ẹda ti Ọlọrun da si orilẹ-ede aye, a o ri i daju pe iyatọ wa ninu eyin awọn ẹranko ati ti awa eeyan. Awọn ẹranko bii kiniun, ẹkun, amọtẹkun, kọlọkọlọ atawọn mi-in ni awọn eyin to wulo fun pipa, gige ati jijẹ ẹran. Bẹẹ ni awọn ẹranko bii agbọnrin, ẹtu, ọya, maalu, ọbọ ati ewurẹ ni awọn eyin to wulo fun gige ati jijẹ koriko pẹlu awọn eso. Ṣugbọn erin ko ni eyin lati fi ge ẹran tabi koriko, nitori naa ni Ọlọrun ṣe fun un ni ọwọ ija lati ka awọn eso fun mimi ni tutu. Awọn eroja kan wa ninu erin to maa n ṣe iranlọwọ lati sọ awọn ewe tabi eso di lẹbulẹbu ninu ẹranko yii.  Ọlọrun naa waa fun awọn ẹyẹ ni ẹnu to wulo lati maa ṣa oriṣiiriṣii eso, ewebẹ ati kokoro fun ounjẹ oojọ wọn. Ṣugbọn awọn ẹyẹ kan wa bii aṣa, awodi ati igun to jẹ pe ẹran ni wọn fi n ṣe ounjẹ jẹ. Ẹlẹdaa tun fun wọn ni ẹbun eekanna ati ẹnu ti wọn le fi mu ẹran to jẹ ounjẹ fun awọn ẹyẹ wọnyi.

Ṣugbọn ni ti awa ọmọ eeyan, Ọlọrun fun wa ni eyin lati maa jẹ awọn koriko ati eso fun idagbasoke ati ilera ara wa. Nitori pe Ọlọrun ko fun wa leyin lati maa jẹ ẹran lo ṣe jẹ dandan fun wa lati se awọn eran ka too le jẹ wọn. Kiniun pẹlu awọn ẹranko ati awọn ẹyẹ to n jẹ ẹran ni tutu n ṣe bẹẹ, nitori pe bi Ọlọrun ṣe yan an fun wọn niyẹn. Ọkan ninu awọn igi to ni ewe ati eso, to si n ṣe awa ẹda Ọlọrun lanfaani ni a n pe ni girọfa (Guava). Orukọ ti a n pe igi yii ti ṣafihan pe ajoji ni lorilẹ-ede Naijiria. Awọn oniṣowo ti wọn wa lati Mexico ni wọn ko eso igi yii yika ilẹ olooru kaakiri agbaye, ti ilẹ wa Naijiria si jẹ ọkan ninu wọn. Ti a ba fẹẹ gbin igi girọfa, a le ge igi rẹ niwọn ẹsẹ bata kan, ka ki i bọ ilẹ ti ko le pupọ, tabi ka gbin koro to wa ninu eso rẹ. Iwadii fi ye wa pe awọn igi ta a gbin koro wọn le to bii ọdun mẹjọ ki wọn too le so eso, ṣugbọn igi ti a ki bọlẹ le mu eso jade lẹyin ọdun mẹta tabi mẹrin.

Awọn igi girọfa kan le ga to bii ogun ẹsẹ bata tabi ju bẹẹ lọ, wọn si tun maa n mu awọn ododo to funfun jade ti wọn ba fẹẹ so eso. Ọpọlọpọ awọn igi eleso ni awọn kokoro buruku kan n ṣakoba fun, ta a nilo oogun apakokoro to n dena awọn aisan ti awọn kokoro wọnyi le ko ba ewe ati eso wọn. Kokoro to n daamu awọn igi eleso yii maa n jinna si igi girọfa, nitori idi eyi ni ko ṣe wọpọ lati maa fin oogun apakokoro si igi yii.

Awọn ewe igi yii wulo pupọ, nitori o n ṣe ara wa loore. Ewe igi girọfa wulo lati dena aisan eyin. Awọn to ba ni aisan eyin le mu ewe igi yii fun gbigbo eyin wọn, ti wọn si le maa n run ẹka rẹ bii pako. Ewe igi yii tun dara fun aisan igbẹ ọrin, aisan itọ ṣuga, to si n dena ọra to maa n wa ni ọna ti ẹjẹ n gba kọja lagọọ ara wa. Ẹ ja ewe igi yii ko pọ, ki ẹ sa a lori iwe tabi ọra to ba mọ daadaa labẹ orule titi ti yoo fi gbẹ. Lẹyin eyi, ẹ fi omi fọ ọ. Ẹ waa fi ọwọ run awọn ewe naa, ki ẹ too ko wọn sinu igo tabi ọra. Fun itọ ṣuga, ẹ bu ṣibi ewe ti ẹ run kan sinu ife omi gbigbona kan, ki ẹ maa mu un laaarọ ati lalẹ. Awọn to ba ni igbẹ ọrin le mu ife kan lẹẹmẹta lojumọ. Fun awọn to ba ni aisan jẹjẹrẹ, ewe yii wulo nipa lilo ṣibi nla meji ninu ife omi gbigbona kan lẹẹmeji lojumọ, lẹyin ti a ba ti sa a to gbẹ daadaa. Eso girọfa yii ni ọpọlọpọ Fitamin C (Vitamin C), nitori o wulo, to si n fun agọ ara wa lokun lati dena awọn aisan keekeeke.

Ẹ ma ṣe gbagbe lati mu ife omi kan tabi meji ni kete ti a ba ji laaarọ.

Ajinde ara yoo ma jẹ

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.