Awọn alaṣeju baba aṣetẹ: Wọn fẹẹ da’ja Buhari pẹlu Ọṣinbajo silẹ o

Spread the love

Kinni kan ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, nnkan naa ko daa jare. Lọjọ naa ni awọn apaṣẹ ẹgbẹ APC ti wọn n pe ni NEC (National Executive Council) ṣepade wọn ni olu ile-ẹgbẹ naa ni Abuja. Iroyin to kọkọ jade si gbogbo ilu laaarọ ọjọ yii ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ati Aṣiwaju Bọla Tinubu ti gunlẹ sibi ipade naa, eyi mu inu awọn eeyan dun, nitori wọn ti mọ pe ipade naa yoo lagbara niyẹn. Nigba ti awọn oniroyin to wa nibẹ si ti ri awọn mẹtẹẹta yii, wọn mọ pe awọn aṣaaju APC lo wa nikalẹ, ohun ti wọn ba sọ nibẹ ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ yoo ṣe. Ṣugbọn iyanu lo jẹ fun awọn oniroyin ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC mi-in nibẹ, nigba ti wọn ri i pe Tinubu ko si nipade ọhun mọ.

Awọn kan kọkọ ro pe o ti lọ ni, afi nigba ti awọn mi-in ri i pe ninu yara kan nibẹ ni wọn fi i si to ti da jokoo, to n gbatẹgun ni tirẹ. Ohun to si ṣẹle nipade naa ko ye wọn rara. Nigbẹyin ni Alaroye gbọ pe awọn gomina kan ninu ẹgbẹ APC, paapaa awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa, awọn ni wọn sopanpa, ti wọn si le Tinubu jade nipade awọn apaṣẹ APC. Bi ọrọ naa ti jẹ ni pe Tinubu lo kọkọ de, o ṣaaju awọn Ọṣinbajo ati Buhari de sipade naa, o si ti lọọ jokoo si ori aga nibi ti wọn kọ orukọ rẹ si, nibẹ ni awọn mi-in si ti n de ba a. Ṣugbọn nigba ti awọn gomina Hausa kan de, inu wọn o dun pe Tinubu wa nipade naa, nitori ki i ṣe ara ọmọ igbimọ apaṣẹ, oye Aṣaaju APC ti wọn si fi n pe e ki i ṣe oye kan to wa ninu ofin ẹgbẹ yii, wọn kan n pe e bẹẹ lasan ni. Iyẹn lawọn gomina yii n sọ laarin ara wọn.

Nibi ti wọn ti n sọrọ yii ni Buhari ti de, gẹgẹ bii aṣa rẹ, Tinubu si jade lati lọọ pade Buhari. Ṣugbọn ko too de ni Nasir El-Rufai ti i ṣe gomina Kaduna ti pe ọga alaboojuto ni Sẹkiteeria wọn, to si laali rẹ pe ki lo de to jẹ ki wọn fi orukọ Tinubu sipade nigba to mọ pe ki i ṣe ọmọ igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ awọn, o ni ko lọọ yọ orukọ naa danu kia. Bakan naa ni awọn kan ninu awọn gomina yii lọọ ba Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga ẹgbẹ wọn pe ko sọ fun Tinubu ko ma pada wọle mọ o, nitori bo ba pada wọle, awọn yoo le e funra awọn, ko ma da bii arifin. Nigba naa ni Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu ti iyẹn jẹ ọmọ Yoruba sare lọọ ba Tinubu, to si ṣalaye ohun to n lọ fun un, o ni ko ma jẹ ki awọn ọmọ Hausa kan ri oun fin, ko ma wulẹ wọle si ipade wọn. Diẹ lo si ku ki ọrọ naa di wahala gidi.

Awọn gomina kan wa ti wọn ko fẹran Tinubu, wọn ko si fẹ ọrẹ yoowu to le maa ba Buhari ṣe. Ipade ti wọn si lọọ ṣe yii, wọn fẹẹ sọrọ lori ọna ti wọn yoo fi dibo lati yan awọn to fẹẹ dije lorukọ ẹgbẹ wọn ni, ọrọ naa si ti da’ja silẹ laarin awọn gomina ati awọn aṣofin to wa ni Abuja. Awọn gomina wọnyi n binu pe awọn aṣofin ti awọn yan lati ipinlẹ awọn, ti wọn ba ti de Abuja ni wọn yoo sọ ara wọn di ọga, ti apa awọn ko si ni i ka wọn mọ. Nitori bẹẹ ni wọn ṣe n wa ọna lati yọ wọn kuro, wọn ti mọ pe bi awọn ko ba ti jẹ ki wọn wọle ninu ibo abẹle ti wọn ba di, ko si bi wọn yoo ṣe dije lorukọ APC, wọn yoo maa pada bọ nile ni. Iyẹn ni wọn ṣe sọ pe awọn ko fẹ ibo ojukoju, eyi ti wọn n pe n Direct Primary, ti wọn ni ibo bonkẹlẹ, iyẹn Indirect Primary, lawọn fẹ.

Iyatọ wa ninu ibo ojukoju yii ati ibo bonkẹlẹ. Ninu ibo bonkẹlẹ, awọn aṣoju agbegbe kọọkan ni wọn yoo waa dibo yan ẹni ti wọn ba fẹ ko dije lorukọ ẹgbẹ wọn, aaye si wa fun gomina lati yan awọn aṣoju yii ni agbegbe kọọkan, nidii eyi, ẹni to ba fẹ ki wọn dibo fun naa ni wọn yoo dibo fun, nigba to jẹ oun lo yan gbogbo wọn. Ṣugbọn bo ba jẹ ibo ojukoju ni, gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni yoo lẹtọọ lati dibo ni gbogbo agbegbe fun ẹni ti wọn ba fẹ, wọn yoo gbe fọto tọhun siwaju, ti awọn eeyan yoo si to sẹyin fọto naa ni. Wọn yoo waa ka iye awọn ti wọn to sẹyin fọto kọọkan, ẹni ti ero tirẹ ba si pọ ju ni ẹgbẹ yoo fa kalẹ. Ninu iru ibo bayii, gomina ko le ṣe nnkan kan, ẹni to ba lero lẹyin ju ni yoo wọle. Iru ibo bayii ni Tinubu fẹ, oun lo si dabaa eto naa pe ki awọn fi mu awọn eeyan tawọn ninu APC.

Loootọ awọn nnkan mi-in wa to n bi awọn El-Rufai ninu si Tinubu, ṣugbọn eyi to ṣe yẹn ko tẹ wọn lọrun, wọn si mọ pe bo ba sun mọ Buhari ju bẹẹ lọ, ohun to ba sọ fun Buhari lori ọrọ ibo ni baba naa yoo ṣe. Iyẹn ni wọn ṣe pepade ọtẹ, ti wọn si le e jade nipade wọn. Ṣugbọn ẹni ti ọrọ yii dun ju ni Yẹmi Ọṣinbajo, igbakeji Buhari. Oun ko fẹ ọna ti wọn fi fi Tinubu wọlẹ yii rara, o ni bi wọn ba mọ pe ko lẹtọọ lati wa sipade, ko yẹ ki wọn ranṣẹ si i rara ni. Yatọ si eyi, ko fẹ bi awọn gomina ilẹ Hausa wọnyi ko tilẹ ṣe fun oun ni ọwọ to yẹ, nigba ti wọn mọ pe Tinubu ni aṣaaju oun to fa oun kalẹ lati waa ṣe igbakeji fun Buhari, oun funra rẹ ri gbogbo ohun ti awọn El-Rufai ṣe yii bii ọna lati fi fi abuku kan oun naa ni, eleyii si tun kun awọn ohun iwọsi ti oun naa ti n ri lati ọjọ yii wa lọdọ awọn ọmọọṣẹ Buhari.

Ẹyi to tilẹ n ja ran-in ran-in bayii, to si han pe yoo da ija gidi silẹ laarin Ọṣinbajo ati ọga rẹ ni ọrọ olori awọn ọtẹlẹmuyẹ, iyẹn awọn agbofinro DSS, Lawal Daura, ti Ọṣinbajo le kuro nipo rẹ lasiko ti Buhari ko si nile. Ọmọ ilu kan naa ni Daura yii ati Buhari, nitori bẹẹ lo ṣe jẹ pe ko si ohun to ṣe ninu ijọba Buhari ti ki i ṣe aṣegbe. Oun ni awọn awo-imulẹ ti wọn sun mọ Buhari to maa n lo lati ṣe ohunkohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Ṣugbọn ọkunrin naa ṣe aṣeju, nitori o ran awọn ọmọ ologun DSS yii lati lọọ ti ile-igbimọ aṣofin Naijiria pa, bẹẹ ni ko sẹni to fun un laṣẹ lati ṣe bẹẹ, Ọṣinbajo to si jẹ adele aarẹ nigba naa ko tilẹ mọ nnkan kan si i. Iyẹn ni inu ṣe bi Ọṣinbajo, o ni ọga meji ko ṣa le maa wa mọto kan naa, lẹyin to si ti fi ọrọ naa to Buhari leti, ti Buhari si fọwọ si i, Ọṣinbajo le Daura danu lẹnu iṣẹ.

Inu awọn ti wọn jọ wa ninu imulẹ lẹyin Buhari yii ko dun si i o, wọn fẹẹ ba Ọṣinbajo ja nigba naa, ṣugbọn ko sohun ti wọn le ṣe. Lati igba ti Buhari ti waa de yii lawọn eeyan naa ti n lo gbogbo ọgbọn ati ete lati da Daura pada sipo rẹ, ki wọn si le adele ti wọn ti yan sibẹ bayii, Mathew Seiyefa, kuro kia. Ninu oṣu keje, ọdun 2019, to n bọ ni asiko ifẹyinti ọga awọn DSS yii ṣẹṣẹ to, ṣugbọn awọn eeyan Buhari yii fẹẹ le e ko too digba naa. Akọkọ ni pe wọn ni ki i ṣe Hausa, ẹẹkeji ni pe ipinlẹ Bayelsa kan naa loun ati aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti wa, awọn eeyan naa si ro pe yoo di awọn lọwọ bi awọn ba fẹẹ ṣe ojooro kan lati ri i pe Buhari lo wọle dandan. Niṣe ni wọn sọ fun Buhari pe ọkunrin naa yoo di ati-wọle rẹ lẹẹkeji lọwọ bi awọn ko ba yọ ọ, ẹnu ọrọ naa ni wọn ṣi wa titi di bi a ṣe n wi yii.

Awọn ti wọn n wo sakun ọrọ sọ pe aaṣa ti yoo ba oogun ọba jẹ gan-an ree, pe bi wọn ba ṣe bẹẹ, abuku nla ni wọn fi kan Ọṣinbajo yẹn, iyẹn si fi han pe ko jẹ nnkan kan ninu ijọba yii niyẹn. Awọn kan ni yoo fi ipo rẹ silẹ ni, bi ko ba si fi ipo silẹ, ija gidi yoo bẹ silẹ laarin oun ati Buhari. Boya Buhari yoo jẹ ki iru ẹ ṣẹlẹ tabi ko ni i jẹ, iyẹn ni ko sẹni to le sọ.

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.