Awọn alaṣẹ Poli Oke-Ogun fun awọn olukọ ileewe naa nisinmi tipatipa

Spread the love

Lọwọlọwọ bayii, awọn alaṣẹ ileewe Poli Oke-Ogun ti fun awọn lọgaa-lọgaa nileewe naa ni isinmi tipatipa, ọdun mẹrin gbako ni wọn si ni ki ẹni kọọkan wọn lọọ ṣe nile rẹ.

Eyi ko ṣẹyin wahala to ṣẹlẹ laarin wọn pẹlu awọn ẹgbẹ olukọ nileewe naa, eyi to si mu awọn olukọ bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni awọn alaṣẹ ileewe naa paṣẹ yii, lẹsẹkẹsẹ ni wọn si yan awọn adari tuntun. Awọn ti wọn yan gẹgẹ bii adari ileewe naa bayii ni Ọgbẹni Fẹmi Samson Alabi, ẹni ti wọn fi jẹ ọga agba, ti Ọgbẹni Y.O Fasasi si jẹ igbakeji rẹ. Oloye Jimoh Adigun ni wọn yan gẹgẹ bii adele akọwe agba tuntun fun ileewe naa, nigba ti wọn yan Ọgbẹni Gbọlagade Ayanbisi gẹgẹ bii adari eto inawo.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan adari ti wọn yọ nipo naa ni pe ọwọ yẹpẹrẹ lo fi mu iṣẹ rẹ, eyi to fa a ti awọn oṣiṣẹ fi gun le iyanṣẹlodi.

Awọn oṣiṣẹ ileewe ọhun to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe oriṣiiriṣii ẹsun ikowojẹ ni wọn fi kan ọga agba naa. Gbogbo akitiyan akọroyin wa lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lẹnu Ọgbẹni Matthew Ọladeji ti i ṣe ọga agba nileewe naa tẹlẹ lo ja si pabo, nitori nọmba rẹ ko lọ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.