Awọn akẹkọọ ati SARS doju ija kọra n’Ijẹbu-Ode

Spread the love

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, lawọn akẹkọọ ileewe Tai Ṣolarin University of Education (TASUED), to wa ni Ijagun, ni Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, doju ija kọ awọn ọlọpaa SARS, ti wọn si dana sun ọkọ wọn. Inu ọgba ileewe naa ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, lasiko ti awọn agbofinro yii n gbiyanju lati mu awọn ti wọn fura si pe wọn n ṣe ‘Yahoo-Yahoo’ nileewe naa.

Akọroyin wa ri i gbọ pe ṣe ni awọn SARS naa le awọn akẹkọọ yii wọ inu ọgba ileewe wọn to wa ni Ijẹgun, lawọn to ku ba sare ṣugbaa awọn eeyan wọn.

Awọn akẹkọọ lọọ gbegi dina ẹnu ọna abawọle ileewe naa, wọn ni awọn ọlọpaa naa ko ni i jade. Ibinu iwa yii lo mu ki awọn agbofinro bẹrẹ si i yinbọn soke leralera lati tu wọn ka.

Awọn akẹkọọ ba ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry ti awọn SARS naa gbe wa jẹ, lẹyin naa ni wọn sọ ina si i.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Oyeyẹmi ni awọn oṣiṣẹ SARS ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ti wa laahamọ awọn, iwadii si ti bẹrẹ lori rẹ lẹsẹkẹsẹ. O ni awọn gbọdọ wadii boya awọn akẹkọọ lo jẹbi tabi awọn oṣiṣẹ SARS. Oyeyẹmi ni ti o ba jẹ pe awọn akẹkọọ lo jẹbi, o di dandan ki ileewe wọ wọn jade lati waa koju ijiya to tọ. O ni ti iwadii ba si fi han pe awọn oṣiṣẹ awọn naa jẹbi, awọn maa fi iya to tọ jẹ wọn ni ilana to ba ofin mu.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.