Awọn agbẹ fẹhonu han si bi awọn Fulani ṣe ya wọ ilu Tede

Spread the love

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa teṣan ilu Tede, ti i ṣe olu-ilu ijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, ni ko jẹ ki erongba awọn agbẹ ni ijọba ibilẹ naa jọ lakooko ti wọn n gbero lati fẹhonu han awọn araalu latari bi awọn Fulani ṣe n wọ ilu awọn wa.
Laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii lawọn agbẹ ko ara wọn jọ pẹlu oriṣiiriṣii akọle lọwọ ninu aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn si gba teṣan ọlọpaa lọ lati beere atilẹyin wọn.
Ninu ọrọ Baalẹ awọn Agbẹ, nijọba ibilẹ Atisbo, Oloye Daniel Oketọla, ṣalaye fun akọroyin wa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja pe ẹkẹta ree ti iroyin to awọn lọwọ pe awọn Fulani n wọle siluu Tede lati ipinlẹ Zamfara, pẹlu ohun ija oloro bii ibọn, ada, ọfa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oloye Oketọla tẹsiwaju pe wiwọle awọn Fulani naa ko ṣẹyin atilẹyin ọba ilu naa to n fun wọn laaye, ti wọn si ti fọrọ naa to o leti ṣugbọn ti ko gbe igbesẹ kankan lori rẹ.
Lakooko to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ọga ọlọpaa agbegbe naa, CSP Moses Ayẹni, sọ pe ni deede aago mẹwaa aarọ ọjọ naa
lawọn ri awọn agbẹ ti wọn to bii aadọta ninu aṣọ ẹgbẹjọda pẹlu
oriṣiiriṣii akọle lọwọ wọn, ti wọn si ni awọn n fẹ atilẹyin awọn lati ṣewọde, ṣugbọn olu-ileeṣẹ ọlọpaa niluu Ibadan, lo lagbara lati fun wọn laaye. O paṣẹ pe ẹnikẹni to ba kọ lati tẹle aṣẹ naa ni yoo ri pipọn oju ijọba. Nitori idi eyi lo fa a ti wọn fi ko ara wọn jọ sileewe girama Progressive, to wa loju ọna Agọ-Arẹ, ko too di pe wọn tuka.
Ninu alaye Onitede ilu Tede, Ọba Rauf Adebimpe Ọladoyin, ṣalaye fun akọroyin wa  pe ahesọ lasan niṣẹlẹ naa.
O tẹsiwaju pe awọn ọta ilu kan lo kora wọn jọ, ti wọn si n gbero lati da omi alaafia ilu ru. O ni ko si Fulani kankan to wọ ilu oun yatọ si awọn Fulani ibilẹ ti wọn jọ n gbe pọ lati bii ogoji ọdun sẹyin lai si wahala rara.
O waa gba awọn ọmọ bibi ilu Tede, nimọran lati kẹ eti didi si ahesọ ọrọ naa, ki wọn si gba alaafia laaye paapaa lakooko ti eto idibo n sunmọ tosi.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.