Awọn agbaagba Iwọ-Oorun ipinlẹ Ogun ati Ẹgbẹ Labour ni GNI ni awon mu

Spread the love

Bi idibo sipo gomina ṣe ku diẹ ko wọle de, atilẹyin oriṣiiriṣii ti n yọju si ondije dupo naa labẹ oṣelu Africa Democratic Congress(ADC),  nipinlẹ Ogun, iyẹn Ọmọọba Gboyega Nasir Isiaka (GNI), pẹlu bawọn agbaagba nilẹ Yewa ṣe fontẹ lu u lọjọ Satide to kọja yii, ti apa kan ẹgbẹ Labour naa tun ni oun ni awọn fa kalẹ bii ondije lẹgbẹ awọn.

 

Nibi ipade awọn alẹnulọrọ ọmọ ilẹ Yewa to waye n’Ilaro, lọjọ Satide naa ni Aṣiwaju ilẹ Awori, Sẹnetọ Ayọ Ọtẹgbọla, ati Aṣiwaju ilẹ Yewa, Ọjọgbọn Anthony Aṣiwaju, ti ṣalaye pe dandan ni atilẹyin tawọn fun GNI yii jẹ.  Wọn ni lasiko yii to jẹ Yewa lo kan, ti ko si ọmọ Yewa to jẹ gomina Ogun ri lati ogoji ọdun le diẹ ti wọn ti da ipinlẹ yii silẹ, afi kawọn ti i lẹyin ko depo naa bii ọmọ Yewa akọkọ.

 

Wọn pe fun atilẹyin awọn eeyan Yewa, ki ọmọ wọn le debẹ lẹẹkan yii. Lara awọn eeyan Yewa to tun fọwọ si i lọjọ naa ni Ẹkẹrin ilu Ọta, Oloye B.A Ọṣunlabu, Ọtunba Ilaro, Ọmọwe SAJ Ibikunle, minisita obinrin akọkọ fun aato ilu labẹ ijọba apapọ Naijiria, Abilekọ Ẹbun Ọyagbọla, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iroyin to fara pẹ eyi ni ti apa kan ẹgbẹ Labour nipinlẹ Ogun ti wọn nawọ Gboyega soke pe oun lawọn fa kalẹ bii ondije dupo gomina ti yoo waye lọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii.

 

Ọjọ Ẹti ni wọn ṣe eyi ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa l’Adatan, l’Abẹokuta, abala Alaga ẹgbẹ naa, Oloye Biọdun Owolabi, lo nawọ GNI soke, bẹẹ ni akọwe ẹgbẹ, Sunday Ọginni, naa ko gbẹyin nibẹ pẹlu awọn eeyan wọn.

Ohun ti wọn sọ ni pe lẹyin gbogbo ayẹwo ati ajọsọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ yooku, awọn fẹnuko pe ko tun sẹlomi-in to yẹ kawọn ti lẹyin ninu awọn to n dupo yii ju Gboyega Nasir lọ, nitori  jijẹ ọmọluabi rẹ atawọn iwa rere ti Ọlọrun fi fun un.

 

Ohun kan to fa awuyewuye lori ondupo ti wọn ti lẹyin yii ni bawọn eeyan ṣe n sọ pe abala to fonte lu GNI yii ko lẹnu nibẹ rara. Wọn ni bawo ni wọn yoo ṣe fa ọwọ rẹ soke nigba ti Alaga igun keji, Abayọmi Arabambi ati alaga tẹlẹ, Bọde Simeon, ko si nibẹ, wọn ni kinni ọhun ko yẹ ko ri bẹẹ rara.

Ṣugbọn Ọginni ati alaga sọ ọ di mimọ pe awọn ko da igbesẹ naa gbe rara, wọn ni ifẹnuko gbogbo ẹgbẹ lẹyin ifikunlukun ati ajọsọ ni, ti kaluku naa si mọ pe ko si ondije dupo to kunju oṣuwọn naa lasiko yii ju GNI lọ.

GNI naa sọrọ nibẹ, o loun gbọ pe wọn fẹẹ dibo wọn foun loun ṣe waa dupẹ. O ni bẹẹ naa ni ki wọn ṣe fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ ADC to n dije ninu eto idibo to n bọ.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.