Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji foju ba kootu

Spread the love

Kamorudeen Ogunsanya ati Oyenuga Taofik, ni awọn ọlọpaa ti wọ lọ si kootu majisreeti to wa ni Ikorodu, niluu Eko, fun ẹsun ole jija, at ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ti o kọja ni wọn taari wọn si kootu. Odusanya, ẹni ọdun mẹtalelogoji, ati Taofik, ẹni ọgbọn ọdun ni wọn fẹsun mẹta ọtọọtọ, to ni i ṣe pẹlu idigunjale, igbimọ-pọ lati huwa ọdaran, ati ole jija kan. Wọn ni ṣe ni wọn ja ọkunrin kan lole owo ti o le ni ẹgbẹrun lọna igba Naira (265,000.00). Agbefọba to n rojọ tako wọn ni kootu, Mary Ajitẹru, sọ pe abule Liadi, nitosi Ikorodu ni wọn ti huwa naa. O ni awọn mejeeji, pẹlu awọn mi-in ti wọn ti salọ bayii, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye, ni wọn ja Akeem Ọladipupọ lole owo ati awọn
nnkan mi-in. Ẹsun naa tako awọn abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo, tọdun 2015.
Awọn afurasi naa ni awọn ko jẹbi awọn ẹsun yii pẹlu alaye.Adajọ W.B Balogun, faaye beeli silẹ fun wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, ati oniduuro meji niye kan naa. O ni awọn oniduuro naa gbọdọ le ṣafihan ẹri owo ori sisan si apo asunwọn ijọba ipinlẹ Eko. Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii lo sun igbẹjọ mi-in si.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.