Awon afurasi ole sa mo Sajenti lowo l’Osogbo

Spread the love

Sajẹnti ọlọpaa kan nipinlẹ Ọṣun, Ajayi Sunday, ẹni ọdun mejidinlogoji, ti wọ wahala bayii pẹlu bi awọn olujẹjọ meji, Kaseem Ọladẹhinde ati Idowu Hazzan Adedapọ, ṣe sa lọ lakata rẹ.
Ọlọpaa naa ni wọn fẹsun kan pe o mọ si bi awọn afurasi naa ti wọn n jẹjọ ẹsun ole jija, didoju ija kọ eeyan (asault), biba nnkan oni nnkan jẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣe sa lọ.
Ẹsun meji ọtọọtọ ni wọn fi kan Ajayi, yatọ si pe wọn ni o mọ si bawọn olujẹjọ ṣe sa lọ, ko tun jafafa lẹnu iṣẹ, eleyii to mu ki nnkan to ṣẹlẹ lọjọ naa waye.
Gẹgẹ bi Inspẹkitọ Elijah Olusẹgun to n ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa lori ọrọ naa ṣe sọ nile-ẹjọ, ilu Oṣogbo niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun to kọja.
Oluṣẹgun ṣalaye pe iwa ọlọpaa naa lodi si abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun, bẹẹ nijiya si wa fun un.
Nigba ti wọn beere lọwọ olujẹjọ boya o jebi ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi, Ajayi ni oun ko jẹbi.
Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Taiwo Adekunle rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ lati gba faaye beeli silẹ fun un nitori pe ko sẹni to le pe e ni arufin, ayafi ti ile-ẹjọ ba too ṣe idajọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Adajọ majisreeti naa, Arabinrin A.O Ajanaku, faaye beeli silẹ fun Ajayi pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, pẹlu oniduro meji ni iye kan naa.
O ni ọkan lara awọn oniduuro yẹn gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba apapọ onipele kẹrinla, nigba ti ikeji gbọdọ ni ilẹ to ni iwe ẹri (C of O).
O waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun, ọdun yii.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe titi ti ile-ẹjọ fi ṣiwọ lọjọ naa, Ajayi ko ti i lanfaani lati ri oniduuro kankan, idi niyẹn ti wọn fi taari rẹ sinu mọto to gbe awọn afurasi lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa.

(49)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.