Awọn afurasi adigunjale to kọlu banki niluu Ọffa foju ba kootu

Spread the love

L’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, nileeṣẹ ọlọpaa ko awọn afurasi adigunjale ti wọn kọlu banki bii marun-un niluu Ọffa, nibi ti ọpọlọpọ ẹmi ti ṣofo lọ si kootu.
Awọn eeyan naa ni: Ayọade Akinnibosun, Ibikunle Ogunlẹyẹ, Adeọla Abraham, Salaudeen Azeez ati Niyi Ogundiran. Wọn fẹsun kan wọn pe wọn gbimọ-pọ pẹlu awọn afurasi mi-in lati ja awọn banki lole loṣu kẹrin, ọdun 2018.
Adajọ Bio Saliu lo n gbọ ẹjọ naa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni igbimọ-pọ lati huwa ọdaran, idigunjale, gbigbe ohun ija oloro to fa ifẹmiṣofo, eyi to tako ofin.
Nibi iṣẹlẹ idigunjale naa ni awọn ọlọpaa mẹsan-an ati awọn araalu mọkanlelogun ti padanu ẹmi wọn.
Ọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni awọn igaara ọlọṣa yii ya bo ilu Ọffa, ti wọn si da ẹmi awọn eeyan legbodo. Wọn kọlu agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Ọja Owode, awọn banki marun-un mi-in naa si fara gba ninu iṣẹlẹ naa.
Ọlọpaa mẹsan-an ni wọn ṣeku pa ni tesan wọn, bẹẹ ni wọn tun ko awọn ibọn AK47 mọkanlelogun atawọn ohun ija mi-in sa lọ.
Awọn banki ti wọn kọlu lọjọ naa ni; First Bank, Guarantee Trust Bank, Zenith Bank, Eco-Bank, Union Bank ati Micro Finance Bank. Iwe ti ileeṣẹ ọlọpaa fi wọ awọn afurasi naa lọ sile-ẹjọ ṣalaye pe akitiyan ikọ ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ti DCP Abba Kyari ko sodi pẹlu awọn agbofinro mi-in lo ṣiṣẹ ti ọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.
Lasiko iwadii awọn ọlọpaa, wọn jẹwọ pe awọn lọwọ ninu idigunjale ọhun.
Diẹ lara awọn ohun ija oloro ti wọn lo tawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn ni ibọn AK47 meji, ọkọ jiipu Lexus RX 300 ti nọmba rẹ jẹ (Kwara), 143 RM, ọkọ mẹsidiisi kan ti nọmba rẹ jẹ LT 496 KJA ati foonu mẹrin to jẹ ti awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ṣi n lọ lati ri awọn ibọn ati owo ti wọn ji ko naa gba.
Agbẹjọro awọn olujẹjọ naa, Abdulrasheed Lawal, sọ pe oun yoo gbe gbogbo igbesẹ to ba yẹ lori ẹjọ naa, o loun yoo gba ilana ofin nipa kikọ iwe lati beere fun beeli awọn olujẹjọ lọjọ ti ẹjọ ọhun yoo tun waye.
Aṣoju ijọba sọ pe ẹsun ti wọn fi kan wọn jẹ eyi to mu ẹmi lọ, nitori naa, ki i ṣe ohun ti wọn le gba beeli wọn ṣaa.
O ni ẹka to n mojuto idajọ araalu ti Amofin Mumini Adebimpe n dari yoo gbe igbesẹ lati wọ awọn olujẹjọ naa lọ sile-ẹjọ giga lati lọọ jẹjọ. O waa rọ ile-ẹjọ lati fi awọn afurasi naa sahaamọ ọgba ẹwọn.
Adajọ Saliu sọ pe ile-ẹjọ majisreeti ko le gbọ ẹjọ naa, ile-ẹjọ giga nikan lo lẹtọọ labẹ ofin lati gbọ iru ẹsun bẹẹ.
O ni ki awọn afurasi naa ṣi wa lahaamọ titi di ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun yii.

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.