Awọn afurasi adigunjale ti wọn pa oniṣowo nla n’Ilọrin dero ahamọ

Spread the love

Awọn afurasi adigunjale mẹta ti wọn yinbọn pa obinrin oniṣowo nla kan, Rasheedat Jimoh, lẹyin ti wọn ja a lole niluu Ilọrin nile-ẹjọ Magisreeti paṣẹ ki wọn ṣi wa lahaamọ.

Aminu Ibrahim atawọn akẹgbẹ rẹ, Abubakar Sa’adi, to n gbe ni Odota, ati Oche Ella, ti abule Agbeyi, niluu Markudi, nipinlẹ Benue, nileeṣẹ ọlọpaa wọ lọ sile-ẹjọ lọsẹ to kọja.

Awọn ẹsun ti wọn n jẹjọ le lori ni; igbimọ pọ lati huwa ọdaran, idigunjale, gbigbe ohun ija oloro ati iṣekupani.

Iwe ti wọn fi wọ wọn lọ sile-ẹjọ ṣalaye pe lẹyin tawọn olujẹjọ naa gba owo ti ko sẹni to ti i mọ pato iye to jẹ ati foonu lọwọ obinrin naa ni wọn yinbọn pa a.

Lasiko iwadii lọwọ tẹ Ibrahim niluu Ilọrin pẹlu ibọn-ilewọ ti wọn fi pa oniṣowo naa.

Nigba tọwọ pada tẹ afurasi keji, Abubakar, o ni afurasi kẹta, Ella, lo ta ibọn naa foun, toun si gbe e fun Ibrahim.

Awọn mejeeji jẹwọ pe awọn lọwọ ninu iṣẹlẹ idigunjale naa. Wọn ni awọn gba owo ati awọn kaadi ipe lọwọ obinrin yii kawọn too pa a.

Ọlọpaa to ṣoju ijọba, Yusuf Nasir, sọ fun ile-ẹjọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ẹjọ naa.

O ke si ile-ẹjọ lati ma gba beeli wọn, nitori bi adajọ ba gba oniduuro wọn, o ṣee ṣe ki wọn tun lọọ da ọran mi-in.

Agbẹjọro olujẹjọ kin-in-ni, Ọgbẹni A. I. Orisankoko, tako ẹbẹ agbefọba naa. O rọ ile-ẹjọ lati faaye beeli onibaara rẹ silẹ.

Adajọ Muhammed Ibrahim paṣẹ ki awọn olujejọ naa wa lahamọ ọgba ẹwọn.

 

 

 

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.