Awọn afọbajẹ fẹhonu han lori ọrọ ọba tuntun n’Irun Akoko

Spread the love

Oluṣẹyẹ Iyiade, Ondo

 

Wahala to n waye niluu Irun Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, lori ọrọ yiyan ọba Onirun tuntun gbọna mi-in yọ lọsẹ to kọja yii pẹlu bawọn oloye kan ṣe fẹhonu han tako bi awọn kan ṣe n gbegi dina eto naa, eyi to n mu ki ọrọ ọba jijẹ falẹ lati ọdun mẹjọ sẹyin ti ọba wọn ti waja.

Iwe ẹhonu kan lawọn oloye ọhun kọkọ fi sita lọsẹ diẹ sẹyin, ninu eyi ti wọn ti rọ ọga ọlọpaa to jẹ Eria Kọmanda Ikarẹ Akoko lati tete wa nnkan ṣe si rogbodiyan to ṣee ṣe ko suyọ lori ọrọ ọba yiyan ilu naa.

Awọn oloye ọhun fẹsun kan ọkan ninu awọn afọbajẹ ilu yii pe o n lo ipo rẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, lati fipa fa ọmọ-oye le awọn araalu lori.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan amugbalẹgbẹẹ gomina ọhun ni pe o n dọgbọn lati ṣeto awọn afọbajẹ meji lati inu idile kan ṣoṣo, bẹẹ ni wọn lo fẹẹ lo agbara ijọba lati din awọn afọbajẹ mẹsan-an to wa bayii ku si marun-un pere.

Eyi ni wọn lo ṣokunfa ẹjọ kan ti wọn pe si ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ondo, eyi ti adajọ fagile, ṣugbọn ti awọn ti pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori rẹ.

Wọn sọ ninu lẹta ọhun pe, ọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun yii, ni amugbalẹgbẹẹ gomina naa gbimọ pọ pẹlu ọkan ninu awọn idile mẹrin to n jọba ni Irun Akoko lati yan ọmọ-oye labẹnu, lai jẹ kawọn idile yooku gbọ nipa rẹ, ṣugbọn ti gbogbo igbesẹ ti wọn gbe naa pada ja si pabo lọjọ ọhun.

Ni ipari lẹta ọhun ni wọn ti bẹ ọga ọlọpaa naa lati tete wa nnkan ṣe sọrọ naa, ko si kilọ fun gbogbo awọn to n wa ọna lati da omi alaafia ilu ru pe ki wọn jawọ.

Bi ọrọ ọhun ṣe ka awọn oloye tinu n bi naa lara to lo ṣokunfa bi wọn tun ṣe ko awọn araalu kan jọ l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, lati fẹhonu han, ki gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, le gbọ nipa ohun to n ṣẹlẹ ninu ilu ọhun.

Oloye Raphael Oguntade, Salaja ti Ogo Irun ati Oloye Agba Rufus Ajakaye, Olisa tilu Irun Akoko, ti wọn gbẹnu sọ fawọn to n fẹhonu han naa sọ pe lati inu oṣu kọkanla, ọdun 2011, ti Ọba Williams Adeusi ti waja ni gbogbo akitiyan awọn lori yiyan Onirun tuntun ti n fori sanpọn.

Wọn ni idile Ọmọwa ni ọba to gbesẹ ti wa, ati pe awọn ẹbi Bada, Aguda ati Fagbolu ti wọn wa lati idile ọba Oke Ose lo yẹ ki ọpọn oye ọhun sun kan.

Wọn fidi rẹ mule pe awọn mẹjọ lawọn afọbajẹ ti ofin faaye gba niluu Irun, yatọ si awọn marun-un pere ti awọn eeyan kan fẹẹ lo lati mu ifẹ ọkan tara wọn ṣẹ.

Awọn to n binu naa ni ki Akeredolu paṣẹ fun alaga afun-n-sọ ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko lati tete gbe igbesẹ lori bi yoo ṣe mu ifẹ awọn araalu ṣẹ lai fi akoko falẹ mọ nitori pe ohun itiju ni fun wọn ki odidi ilu wa lai ni ọba tabi adele lati bii ọdun gbọọrọ sẹyin.

Wọn ni ọpọ iwe ẹhonu lawọn ti kọ si awọn ẹṣọ alaabo, ṣugbọn to jẹ awọn tinu n bi gan-an ni wọn tun n doju ija kọ.

Gbogbo akitiyan wa lati ri akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Ṣẹgun Ajiboye, ba sọrọ lo ja si pabo pẹlu bo ṣe kọ ti ko gbe foonu rẹ nigba ta a pe e. Bakan naa ni ko fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i.

Ṣugbọn Alaaji Bisi Agboọla to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ondo ninu ọrọ tirẹ sọ pe aipẹ yii loun ṣẹṣẹ gbọ nipa ọrọ ọhun, o ni ka foun laaye diẹ koun fi ṣiṣẹ le e lori.

Ohun ta a ri gbọ ninu iwadii ti ALAROYE ṣe ni pe ni kete ti Ọba Williams Adeusi ti waja lọdun bii mẹjọ sẹyin ni ọkan-o-jọkan wahala ti n suyọ lori ati yan ẹlomi-in ti yoo rọpo rẹ, ṣugbọn lọdun 2015 lawọn afọbajẹ kan dibo yan ọkan ninu awọn ọmọ kabiyesi ọhun, iyẹn Ọmọọba Adeusi, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i ṣe iwuye fun un to fi jade laye.

Ohun to ba awọn araalu ọhun lẹru julọ ni bi adele ọba ti wọn yan lẹyin iku Ọmọọba Adeusi tun ṣe fo ṣanlẹ, to si ku lojiji, lẹyin oṣu diẹ to gori aleefa adele.

O jọ pe eyi lo ṣokunfa bi ko ṣe si ọba tabi adele to n ṣakoso ilu iṣẹnbaye ọhun lati bii ọdun mẹrin sẹyin.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.