Awọn adigunjale to ja owo gba niwaju banki yoo foju ba ile-ẹjọ

Spread the love

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti sọ pe oun ko ni i dẹyin lẹyin awọn afurasi adigunjale meji kan, Boniface Ewerem, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ati Joseph, ẹni ọdun mejilelogoji, ayafi toun ba tẹle wọn de kootu.

Lọjọ ọdun Keresi kọla, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun, oṣu to kọja yii, lawọn ọlọpaa teṣan Sadiku, to wa ni Ilasamaja, ri awọn mejeeji, nibi ti wọn gẹgun sori ọkada wọn. Ireti awọn afurasi yii ni lati ja baagi awọn to ba n jade nileefowopamọ gba, ki wọn si sa lọ. Ṣugbọn, ṣe ni awọn mejeeji ko sọwọ ikọ ọlọpaa to n ṣọ agbegbe naa nitori ọdun to wa nita, lẹyin naa ni wọn si n ka boroboro.

Nigba ti Boniface n jẹwọ fun awọn ọlọpaa, o ni owo ti awọn yoo fi ṣọdun Keresi ati ọdun tuntun ni awọn n wa ti awọn fi di ẹni to n ṣọ awọn to n jade ninu banki, ki awọn le ṣakọlu si wọn. Lasiko ti ọkunrin kan jade pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta din nirinwo (350,000.00), ni nnkan bii aago meji ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni awọn mejeeji kọlu u pẹlu ibọn, ti wọn si paṣẹ fun un pe ko ko owo ọwọ rẹ wa.

Niṣe ni wọn ni Joseph yinbọn soke, to si ja owo naa gba lọwọ ọkunrin yii, lẹsẹkẹsẹ ni wọn si ta le ọkada wọn. Ariwo ti ọkunrin naa pa lo ta awọn eeyan lolobo, ti awọn eeyan fi n ho le wọn lori bi wọn ṣe n lọ, ko too di pe awọn ọlọpaa teṣan Ilasamaja, eyi ti ọga wọn ko sodi de, ti wọn si gba ti wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Chike Oti, ẹni to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, sọ pe ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to tete de ibi iṣẹlẹ naa, awọn eeyan ko ba ti pa wọn. Oti ni ninu ọrọ ti awọn gba silẹ lẹnu ọkan ninu awọn afurasi yii sọ pe ọdun to wa nita lawọn fẹẹ fi owo naa ṣe, ati pe awọn ko ni i lọkan lati pa ẹnikẹni. Ibọn ilewọ kan ati ọta lo ni awọn ri gba pada lọwọ wọn, pẹlu owo ti wọn ji, eyi ti awọn ti da pada fun ẹni to ni in.

Ṣa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe wọn ti ko awọn afurasi yii si ọdọ awọn ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale ti ijọba apapọ (F-SARS), laipẹ ni wọn yoo si foju ba ile-ẹjọ.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.