Awọn adigunjale kọlu oludije APC l’Ekiti

Spread the love

Oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC), to fẹẹ ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Ekiti keji nile igbimọ aṣofin ipinlẹ, ỌnarebuTajudeen Akingbolu, lawọn adigunjale kan kọlu lopin ọsẹ to kọja. Nile ọmọ bibi ilu Aramọkọ Ekiti ọhun to wa ni agbegbe Ọlọrunda, Adebayọ, niluu Ado-Ekiti niṣẹlẹ naa ti waye.

Nigba ti alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti tẹlẹ naa n ṣalaye ọrọ, o ni ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja toun dele lawọn eeyan naa ṣakọlu ọhun.

‘’  O da bii ẹni pe awọn meji yẹn tẹle mi lati igboro ni, ero wọn si ni lati ja mi lole tabi ṣe mi nijamba. Bi mo ṣe wọle ni wọn tẹle mi, ṣugbọn emi ti gba tọilẹẹti lọ, ni wọn ba mori le yara igbalejo ti iyawo mi atawọn ọmọ pẹlu awọn mọlẹbi mi-in wa.

‘’Bi wọn ṣe ko wọn ni papamọra ni ọkan ninu wọn bẹrẹ si i beere mi leralera, eyi to fi han pe o ni nnkan to n wa. Nigba ti mo ti mọ awọn to de ba wa lalejo ni mo rọra duro sibi ti mo wa.

‘’Muri Akingbolu to jẹ ẹgbọn mi ati ẹgbọn mi kan tara rẹ ko ya ni wọn jade si wọn. Mo gbọ pe ọkan ninu awọn ole yẹn bo oju, ṣugbọn wọn ri oju ekeji. Wọn na ẹgbọn mi, wọn dẹ tun gba ẹgbẹrun lọna ogoji (40,000), Naira lọwọ ẹ ki wọn too gba ẹgbẹrun mẹtadinlaaadọta (47,000), lọwọ iyawo mi.

‘’ Bakan naa ni wọn gba awọn foonu kan, ninu eyi ti temi gan-an wa. Nnkan to dun mi ni ọmọ mi obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹjọ ti wọn na ibọn si, nitori ẹru ṣi n ba a di akoko yii.’’

Akingbolu ni iyalẹnu lo jẹ nigba tawọn ẹruuku naa n lọ ti wọn pe ẹgbọn oun lati fun un ni foonu iyawo oun, bẹẹ ni wọn tun da foonu ẹni to n ṣaisan pada.

Ẹwẹ, teṣan ọlọpaa to wa ni Oke Ila, l’Ado-Ekiti ni Akingbolu lọ, awọn agbofinro si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.