Awọn adẹtẹ Iberekodo, l’Abẹokuta, beere fun iranlowo ijoba lori ohun amayederun

Spread the love

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Niṣe ni inu awọn eeyan naa n dun, ti wọn ko si ri ara wọn bii ẹni to larun kankan lara, gbogbo ayika wọn si kun fun idunnu. Abule awọn adẹtẹ to wa ni Ibẹrẹkodo, eyi ti wọn tun n pe ni ‘Lepers Colony’,  ni akọroyin ALAROYE ṣabẹwo si lọsẹ to kọja.

Tidunnu-tidunnu ni wọn fi tọka alaga wọn, Jimoh Ahmed, fun wa. Ọkunrin ti ko le ti i ju ẹni ogoji ọdun lọ naa lo tun n ṣiṣẹ awakọ taksi niluu Abẹokuta, lai naani ailera ara rẹ. Jimoh tun ni akọwe ẹgbẹ awọn eeyan abarapaa lawujọ, ẹka ti ipinlẹ Ogun, iyẹn National Association of People with Disabilities (JONAPWD).

Gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ, o fẹrẹ to adẹtẹ mọkanlelọgbọn to n gbe labule naa, bẹẹ lo ni irufẹ abule yii mi-in tun wa ni ilu Ijẹbu-Igbo, nipinlẹ Ogun kan naa.

Ọpọlọpọ iṣoro ni awọn adẹtẹ yii n koju, lara rẹ si ni aisi eto aabo to peye, aini ohun amayed€run, ile wọn to ti di alapa, atawọn iṣoro mi-in.

Jimoh ṣalaye pe ko si ohun to yẹ ko di awọn adẹtẹ lọwọ lati ni ẹkọ to ye kooro bii ti awọn ti wọn pe. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ileewe ti wọn ti n kọ awọn abarapaa lẹkọọ pọ nipinlẹ Ogun, ṣugbọn awọn rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati ṣẹ atunṣe si wọn. Ọkunrin naa ni awọn ni awọn olukọ laarin awọn to le kọ awọn to ba ku-diẹ-kaato (special people), lẹkọọ. O waa rọ ijọba ati awọn ẹlẹyinuju aanu lati ran awọn eeyan naa lọwọ.

Ọna ti wọn n gba ri owo ṣetọju ara wọn

Lọna ati le maa ṣetọju ara wọn, iṣẹ agbẹ lọpọlọpọ ninu awọn adẹtẹ naa n ṣe ju, bẹẹ awọn mi-in n ta ọja laarin abule naa, eyi ti wọn fi maa n kun ẹgbẹrun mẹwaa Naira ti ijọba ipinlẹ maa n san fun ẹnikọọkan wọn loṣooṣu gẹgẹ bii owo itọju (stipends). Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni ijọba gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, lo ṣẹṣẹ fi kun owo naa, nitori ẹgbẹrun mẹta Naira lawọn maa n gba tẹlẹ. Bakan naa, wọn dupẹ lọwọ awọn lajọ-lajọ to maa n wa loree-koree, ti wọn si maa n fi oriṣiiriṣii ẹbun ta wọn lọrẹ lai naani ailera wọn.

Baba Adete to wa lati Iwere-Ile

Iṣoro wọn

Jimoh ṣalaye fun akọroyin wa pe ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti n gba ilẹ mọ awọn adẹtẹ naa lọwọ, ti wọn si fi n kọ ile si i, eyi to mu ko nira fun ọpọlọpọ wọn lati ri ilẹ da oko. Gẹgẹ bo ṣe sọ, “nigba ti wọn da ibi yii silẹ, ẹyin odi ilu ni, koda, o ti le lọgọrun-un ọdun ti wọn ti da a silẹ. Idi ti wọn fi ṣedasilẹ rẹ gẹgẹ bi mo ṣe gbọ ni pe wọn fẹ ki awọn adẹtẹ maa gbe nibẹ, ki wọn ma baa maa gbe laarin ilu. Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọrọ ti wọn maa n sọ pe inu igbo ni adẹtẹ n gbe ti n yipada bayii. Ti ẹ ba wo ayika wa yii, ẹ oo ri i pe awọn ile gbigbe ti wa nibẹ, eyi ti awọn eeyan to da pe naa ti n gbe. Ilu yii ki i ṣe ẹyin odi ilu mọ, o ti di aarin ilu.

‘‘Bakan naa, a ni iṣoro omi. A ki i ri omi gidi mu nibi yii. Gbogbo ọna ti omi gba wọ abule wa yii lo ti bajẹ. Omi odo la maa n mu, bo tilẹ jẹ pe iṣoro kan gboogi ni omi jẹ ni ilu Abẹokuta.

‘‘ Ẹ jẹ ki n fi ọrọ temi ṣe apẹẹrẹ mi-in fun yin. Emi gẹgẹ bii ẹnikan, o wu mi ki n pada lọ si ileewe, ṣugbọn ko si owo lọwọ mi. Owo ajọ ti mo n da ni mo fi ra ọkọ taksi ti mo fi n gbe ero kaakiri ilu.

‘‘A ni ọpọlọpọ laarin wa ti wọn maa n lọọ ra ọja epo niluu mi-in bii Ọja-Ọdan ni Yewa, ti wọn si maa n tun un ta fun awọn eeyan. Awọn mi-in wa ti wọn n ṣe ọṣẹ ti awọn ajọ alaadani kan kọ wọn, ṣugbọn wọn ko ri owo ṣe owo naa rara.”

Ọdun mẹrindinlaaadota ni mo ti lo labule yii- Ojoawo

Ọkan ninu awọn to tun wa nibẹ ni Alagba John Ojoawo, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin. Ilu Iwere-Ile, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti gbe baba naa wa si ilu Ibẹrẹkodo. Ọkunrin naa ni jita ati awọn irinṣẹ orin mi-in loun maa n lo fun awọn olorin niluu Ọyọ ki aisan naa too kọlu oun lọdun 1973. Ọkunrin naa ni oun ko fẹẹ maa ṣiṣẹ agbe nigba ti ẹtẹ naa kọlu oun, idi niyẹn toun si ṣe wa ọna de abule awọn adẹtẹ naa. O dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun fun bi wọn ṣe da iru abule yii silẹ.

Nigba to n sọ iriri rẹ ni abule yii fun akọroyin wa, baba ni, “laye ijọba Western Region, Naira mẹfa ni wọn maa n fun wa loṣooṣu. Nigba ti mo kọkọ de ibi, ilẹ pọ gan-an ti awọn eeyan fi maa n ṣe iṣẹ agbẹ. Gomina akọkọ to kọkọ fi kun owo-oṣu ti a n gba nigba naa ni Seidu Ayọdele Balogun. Ko too di pe o de ipo naa, Naira mẹrin ni awọn ijọba ibilẹ maa n san fun wa, ṣugbọn lọjọ ti gomina naa ṣabẹwo si ọdọ wa ni wọn sọ owo wa di ogun Naira. Laye ijọba gomina Ọṣọba, o fi kun owo naa lati ẹẹdẹgbẹta Naira si ẹgbẹrun kan aabọ Naira. Nigba ti gomina Gbenga Daniel de,  o sọ ọ di ẹgbẹrun mẹta Naira. Lasiko iṣakoso gomina Amosun, o sọ di ẹgbẹrun mẹwaa Naira lati ẹgbẹrun mẹta to wa tẹlẹ.”

Nigba ti a beere boya o n gburoo ile, ọkunrin naa ni awọn eeyan oun maa n waa wo oun loree-koree.

Ni ti Ọlaitan Sunday, ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ni latọdun 2005 loun ti wa labule naa, nibẹ si ni awọn dokita ati nọọsi ti gba oun nimọran lati pada sileewe. “Ipele kẹta (JSS3), ni mo wa nileewe sẹkọndiri ti aisan kan kọlu mi nibi ẹsẹ. Awọn dokita ni wọn maa ge ẹsẹ mi danu. Lẹyin ti wọn ge e tan ni wọn sọ fun mi nileewe ti mo n lọ pe mi o ni i le tẹsiwaju mọ nitori ki i ṣe ileewe ti wọn ti n kọ awọn ti wọn ni ipenija ara (disabiltiy school).’’

Nigba ti a beere nipa bi awọn eeyan ṣe maa n wo wọn nita, o ni nitori itan adẹtẹ inu bibeli ti awọn eeyan ka ni wọn fi maa n foju buruku wo awọn nita. Igbagbọ wọn ni pe inu igbo ni adẹtẹ n gbe, idi niyẹn ti ọpọlọpọ eeyan si ṣe maa n sa fun awọn.”

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.