Awọn aṣofin tinu n bi kọwe ẹhonu Wọn lafi kawọn ọlọpaa mu alaga ẹgbẹ awakọ ipinlẹ Ondo

Spread the love

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lawọn aṣofin ipinlẹ Ondo mẹrindinlogun tinu n bi fi atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti fẹhonu han tako bi awọn ọlọpaa ṣe kuna lati fi panpẹ ọba gbe Alaga ẹgbẹ awakọ ipinlẹ Ondo, Jacob Adebọ, tawọn eeyan mọ si Idajọ.

 

Ninu atẹjade ti Olori awọn ọmọ ile to pọ julọ, Olugbenga Araoyinbo, Igbakeji abẹnugan, Fajolu Abimbọla, ati Ọlamide George to jẹ abẹnugan fọwọ si ni wọn ti sọ pe ọga agba awọn ọlọpaa l’Abuja gbọdọ tete wa nnkan ṣe lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn lọwọ awọn tọọgi to n lepa awọn.

 

Awọn ọmọlẹyin Idajọ mi-in ti wọn tun sọ pe o yẹ kawọn ọlọpaa fi panpẹ ọba gbe ni; Ibrahim, Lamidi, Abiyamọ, Alaba, Badiru ati Niyi Ẹniba ti gbogbo wọn jẹ oloye ẹgbẹ awakọ ipinlẹ Ondo.

 

Awọn aṣofin ọhun fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni mejidinlogun ninu awọn mẹrindinlọgbọn yẹ aga mọ abẹnugan ile ọhun tẹlẹ, Bamidele Ọlẹyẹlogun ati igbakeji rẹ, Irọju Ogundeji nidii lọjọ kẹsan-an, oṣu yii.

 

Eyi lo sọ pe awọn n ṣe lọwọ ti Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olugbenga Adeyanju, fi ko ọlọpaa de, ti wọn si n pariwo pe niṣe ni awọn waa ba wọn yanju rogbodiyan to n ṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe ko sohun to jọ bẹẹ rara ti wọn fi pari iyọnipo ti wọn fẹẹ ṣe.

 

Wọn ni ko pẹ sigba ti awọn ọlọpaa de lọjọ naa ni Idajọ ṣaaju awọn tọọgi ẹgbẹ awakọ kan de lati ṣakọlu si awọn ti wọn si tun ba dukia to jẹ ti ile-igbimọ aṣofin ati tiwọn jẹ.

 

Gbogbo akọlu yii ni wọn lo ṣoju kọmisanna ọlọpaa yii, ṣugbọn to kọ lati ṣe ohunkohun nipa rẹ titi tawọn tọọgi ọhun fi ṣe ifẹ inu wọn tan.

 

 

Awọn aṣofin ọhun sọ pe ojoojumọ lawọn tọọgi n lepa ẹmi awọn ati idile awọn lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

 

Dipo tawọn ọlọpaa iba si fi gbe igbesẹ lati fi panpẹ ọba gbe Idajọ atawọn ọmọlẹyin rẹ, iwe ni wọn sọ pe wọn ri gba lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, nibi ti wọn ti fi dandan le e pe awọn gbọdọ yọju si ọfiisi wọn lori ẹsun ṣiṣe ayederu ibuwọlu awọn aṣofin ẹgbẹ awọn.

 

Awọn aṣofin naa waa rọ ọga agba patapata lorilẹ-ede yii lati gbe igbesẹ kiakia lori ọrọ Idajọ atawọn alatilẹyin rẹ, nitori pe ko sẹni to yẹ ko kọja ofin.

 

Bakan naa ni wọn ni awọn ti ṣetan lati pada sile igbimọ aṣofin naa lati maa ba iṣẹ awọn lọ lai kọ ohun to le tẹyin rẹ jade, wọn ni awọn ko ni i gba ki awọn mẹsan-an pere maa dari awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn.

 

Ninu atẹjade mi-in ti Olugbenga Araoyinbo fi lede lorukọ awọn ẹgbẹ rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, lo ti fidi ẹ mulẹ pe Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajọ, ati Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti pe awọn lati ba wọn sọrọ.

O ni ko si ninu adehun ti wọn ṣe pẹlu wọn pe ki Ọlẹyẹlogun ati igbakeji rẹ, Irọju, tẹsiwaju gẹgẹ bii olori ile igbimọ naa, bo tilẹ jẹ pe loootọ ni wọn gba si wọn lẹnu lati pada sile igbimọ ọhun.

 

Ninu ipade naa lo ni awọn ti sọ fun Igbakeji Aarẹ pe awọn ti gba lati da Olẹyẹlogun ati Irọju pada saaye wọn ti wọn ba le gba lati kọwe fipo silẹ loju ẹsẹ ti wọn ba ti n da wọn pada.

 

Bakan naa lo ni awọn sọ fun Gomina Akeredolu pe ko gba awọn laaye lati tu ile ka, ki awọn si yan awọn oloye tuntun mi-in, ati pe awọn ṣetan lati fun Gomina lanfaani lati yan ẹlomi-in to ba wu u yatọ si Ọlẹyẹlogun ati Irọju, ṣugbọn Gomina Akeredolu ko gba aba awọn wọle.

Araoyinbo ni awọn ko figba kankan ṣe ayederu ibuwọlu Sunday Ọlajide ati Oluṣọla Oluyẹde gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ kiri. O ni awọn aṣofin mejeeji wa lara awọn mejidinlogun to buwọ lu iwe iyọnipo Ọlẹyẹlogun ati igbakeji rẹ. Laipẹ lo sọ pe wọn yoo gbe gbogbo awọn to n fẹsun ṣiṣe ayederu ibuwọlu kan awọn lọ sile-ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.