Awọn aṣekupani paayan marundinlaadọta eeyan ni Kaduna

Spread the love

Titi di akoko yii, inu fuu, aya fuu, lawọn eeyan Jamruwa, nijọba ibilẹ Birnin Gwari, nipinlẹ Kaduna, ṣi wa nitori bi awọn aṣekupani ṣe ya wọ abule naa, ti wọn si pa eeyan marundinlaaadọta, ti wọn tun ba ọpọ nnkan ini wọn jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i ju ọsẹ kan lọ tawọn aṣekupani yii ti kọkọ lọọ da ẹmi awọn eeyan legbodo labule naa, sibẹ, ni airotẹlẹ ni wọn tun ya wọ inu abule naa lọ.

Iwadii fi ye wa pe ọpọ awọn ti wọn pa naa lo jẹ awọn to doju ija kọ awọn aṣekupani naa nigba ti wọn wọnu abule, bẹẹ lawọn ọmọde ti wọn ko le sa asala fẹmi wọn naa tun baa rin.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ to ba oniroyin sọrọ sọ pe ipinlẹ Zamfara to jẹ amugbalẹgbẹ Kaduna lawọn to ṣiṣẹ ibi naa gba wọle.Ọpọ awọn tori ko yọ paapaa ti wọn jẹ obinrin ni wọn ti sa asala fẹmi wọn ni wọn ti wa ni Doka bayii.

Ohun ti ọkan lara awọn fijilante to n sọ agbegbe naa sọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe ni nnkan bii aago meje alẹ lawọn wa pẹlu awọn ṣọja ni Gwaska lati fẹẹ de abule Kuiga, tawọn bere si ni gbọ iro ibọn ni kikan kikan ṣugbọn ọga awọn ṣọja paṣẹ pe kawọn si ṣe suuru nitori ibẹ ṣokunkun

Eyi lo mu kawọn fijilante naa pada pẹlu awọn tori ko yọ,wọn ni ti ki i ba ṣe awọn ni, awọn to ku ko ba ju bẹẹ lọ. Wọn wa rọ ijọba atawọn alaṣẹ lati tete ba wọn wa nnkan ṣe sawọn aṣekupani to n yawọ abule naa ti wọn si n pawọn eeyan nipakupa.

Bakan naa ni agbẹnusọ fawọn ọlọpaa nipinlẹ Kaduna,Muktahir Aliyu ti sọ pe awọn si n ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ to waye naa,nitori oun ko ti le sọ pato nnkan to mu kawọn aṣekupani naa sọ abule naa di ibudo ipaayan.

(42)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.