Awọn ṣọja rẹpẹtẹ tawọn Boko Haram tun pa

Spread the love

Ki i ṣe pe bi a ti n sọrọ yii ẹnikan le mọ iye awọn ṣọja ọmọ Naijiria ti awọn afẹmiṣofo Boko Haram pa ni agbegbe kan to n jẹ Melete, nipinlẹ Borno, lọsẹ to kọja yii. Bi awọn kan ti n pe wọn yoo to ọgọrun-un ni awọn kan n sọ pe wọn ko ju aadọta lọ, awọn ṣọja funra wọn si sọ pe wọn kan le logoji lasan ni. Iku oro ni wọn ku, iku ti ko dara rara gbaa ni. Fun igba akọkọ, ọrọ naa ba ijọba Naijiria lojiji debii pe ileeṣẹ Aarẹ ko le sọ ohun kan bayii lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye, afi awọn aṣofin ti ọrọ naa ka lara ti wọn gbe igbimọ dide lati wadii ohun to ṣẹlẹ gan-an. Aarẹ Muhammadu Buhari paapaa ti pe awọn olori awọn ọmọ ogun ilẹ yii pe ki wọn waa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ foun, ki awọn si tun jọ fikunlukun lori ohun ti yoo ṣẹlẹ ati ọna ti awọn yoo gba. Ati awọn aṣofin, ati Aarẹ funra rẹ, ohun to dara ni wọn ṣe, ṣugbọn ọrọ wọn ko yatọ si ateyin-rọgbọn aja: aja ti wọn ge leti to n lọọ fi ọbẹ ti wọn fi ge e leti pamọ, ṣe ọbẹ ko ti ṣe iṣẹ to fẹẹ ṣe ni. Ko si ohun to n fa iku rẹpẹtẹ fun awọn ṣọja ilẹ wa bayii ju pe nilẹ yii, ni Naijiria yii, ohun gbogbo to ba ti ba wa, ọrọ oṣelu la fi n ṣe lọ. Kaka ki a mura si ọrọ to ba ṣẹlẹ si wa, ka pariwo sita ohun yoowu to ba n ṣe wa, ọrọ oṣelu ni a oo ti bọ ọ, ti a oo maa pa irọ nla nla fun awọn araalu, ti a oo maa sọ ohun ti ko ṣẹlẹ ati ohun ti a ko ṣe fun wọn, ki wọn le sọ pe a n ṣe daadaa, ki wọn si maa ba ara wọn ja nitori ọrọ ẹgbẹ oṣelu wa. O daju pe itiju ni ko jẹ ki ileeṣẹ aarẹ le mọ ohun ti wọn fẹẹ sọ. Tabi ọjọ meloo lawọn eeyan yii ti fi pariwo pe awọn ti pa Boko Haram run patapata, wọn o tun ni i gberi mọ. Koda bi eeyan ba n gbọ ọrọ lẹnu awọn ọjọgbọn aye bii Lai Muhammed, oluwa-rẹ yoo ro pe ko si ọmọ ẹgbẹ Boko Haram kankan mọ ni gbogbo Naijiria ni. Buhari paapaa n lo eleyii lati fi polongo ibo, pe ijọba oun ti kapa Boko Haram. Bẹẹ ni gbogbo igba ti wọn fi n sọ eleyii, awọn ṣọja wa ninu aginju ti wọn ko ri owo ounjẹ gba deede, ti wọn ko ri owo ọya to tọ si wọn gba, paripari rẹ ni pe wọn ko tun ni irinṣẹ to dara. Eyi to ṣẹlẹ yii, awọn ṣọja ti wọn n sọrọ sori fidio ni awọn ko ni irinṣẹ to dara ni, awọn kan ninu wọn si sọ pe niṣe lawọn to pa wọn waa ba awọn bii ọrẹ ki wọn too doju ibọn kọ awọn, irinṣẹ awọn ko si to tiwọn. Ninu gbogbo eleyii, lati igba to ti han pe apa awọn ọga agba ologun ti a ni nilẹ yii bayii ko ka ohun to n ṣẹlẹ lawọn eeyan ti n gba Buhari nimọran pe ko yọ wọn kuro, eyi ti wọn ti ṣe to, ko fi awọn ẹlẹjẹ tutu ati awọn to mọ nipa ogun afẹmiṣofo bayii si ipo naa ki wọn le ba wa le Boko Haram lọ. Ṣugbọn kaka ki Aarẹ dahun, yoo ni awọn alatako lo n sọ bẹẹ, wọn si le ni awọn ti wọn ko fẹran ẹsin Islam ni, bẹẹ gbogbo aye lo mọ pe awọn ti wọn n paayan yii ki i ṣe musulumi, wọn n fi orukọ ẹsin naa boju lati da ile aye ru ni. Gbogbo aye lo n le wọn nibi yoowu ti wọn ba ti gunlẹ si, Naijiria lo ṣoro fun lati le wọn nitori ijọba wa ti ko kun oju oṣuwọn, nitori awọn ti wọn n ṣe ijọba naa ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe ju oṣelu lasan lọ, wọn ko ṣejọba Naijiria rara. Bi a ko ba fẹ ki awọn afẹmiṣofo yii gba gbogbo ilẹ Hausa tan lọjọ kan, afi ki Buhari mura si ọrọ yii ju bi wọn ti n fi oṣelu ṣe e yii lọ. Ki wọn sọ kinni naa di ogun gidi, ki wọn ra ohun ija igbalode fawọn ṣọja wa naa, ki wọn si ro wọn lagbara debii pe inu wọn yoo dun lati fi ẹmi wọn lelẹ fun Naijiria. Bẹẹ ni ki ijọba Naijiria yee fun awọn Boko Haram lowo mọ nitori ọrọ oṣelu. Bi Boko Haram ba ti ji awọn ọmọ kan ko, ijọba Naijiria yoo ṣeto owo rẹpẹtẹ fun wọn kawọn eeyan le sọ pe wọn n ṣiṣẹ, bi awọn yẹn ba gba owo wa tan, wọn yoo ko awọn ọmọ silẹ, wọn yoo lọọ fi owo ti wọn ba gba ra ohun ija oloro si i. Wọn ti mọ pe Naijiria ko lagbara, wọn mọ pe Naijiria ko si le lagbara nitori wọn ko ni iṣọkan, iyẹn ni wọn ṣe duro ti wa ti wọn ko lọ. Ẹ ma fun Boko Haram lowo mọ. Ẹ sọ ododo ọrọ fun gbogbo ọmọ Naijiria, ki gbogbo wa le jọ jagun naa ko tan. Ka maa fi ẹmi awọn ọmọ ọlọmọ to n ṣe ṣọja ṣofo ni gbogbo igba yii ko ma daa, nitori bo ba n ṣẹlẹ bẹẹ, bo ba ya, ko sẹni ti yoo fẹẹ lọ sileeṣẹ ologun. Abi nibo la fẹẹ gbeyii gba?

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.