Awọn ṣọja mẹta ni wọn ka mi mọ, ikan gbe ibọn dani, awọn meji to ku si ni ọbẹ alaṣooro lọwọ wọn, wọn fẹẹ pa mi ni – Bẹẹkọ, aburo Fẹla

Spread the love

 

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1977, ni ẹjọ awọn Fẹla tun bẹrẹ niwaju Adajọ Lateef Dosunmu, awọn ero to si wa ni kootu lọjọ naa pọ ju awọn ti wọn ti n wa tẹlẹ lọ. Ṣe ile-ẹjọ naa ti da bii gbọngan nla kan ti awọn onitiata ti n ṣere, nigba ti awọn ero iworan si ti mo pe ọfẹ leleyii, niṣe ni wọn n rọ wa bii omi. Iyatọ to kan wa nibẹ ni pe eleyii ki i ṣe ere itage, ootọ lo n ṣẹlẹ, ko si afiṣere kan nibẹ rara. Ootọ ni wọn dana sun ile Fẹla Anikulapo Kuti ni ọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun naa, ti wọn si ṣe gbogbo awọn eeyan to wa nibẹ ṣikaṣika, ti wọn si gbe igbimọ adajọ kan dide lati wadii ohun ti wọn yoo ṣe. Adajọ kan to n jẹ Kalu Anya ni wọn fi ṣe olori rẹ, igbimọ naa lo si da Fẹla lẹbi, to ni ko yẹ ki ijọba gba iru rẹ laaye laarin ilu, amọran Adajọ Kalu yii ni ijọba si tẹle ti wọn fi gba ile Fẹla.

Ootọ ni pe Fẹla, Iya rẹ, Arabinrin Funmilayọ Ransome Kuti, ati aburo rẹ, Bẹẹkọ Ransome Kuti, ti pe ẹjọ si ile-ẹjọ giga yii lati fi gbẹsan lara ijọba. Wọn fẹ ki wọn sanwo itanran, wọn fẹ ki wọn gba pe awọn lawọn ba ile naa jẹ bo tilẹ jẹ pe igbimọ Kalu ti sọ pe awọn ko mọ awọn ṣọja ti wọn dana sun ile naa, awọn ṣọja kan tẹnikan ko foju ri ni gbogbo wọn. Ṣugbọn awọn Fẹla taku,  wọn ni awọn mọ awọn ṣọja ti wọn dana sun ile tawọn o, wọn ki i ṣe ṣọja kan tẹnikan ko foju ri, Abalti ni baraaki wọn, lẹgbẹẹ ile awọn nibẹ, awọn si mọ Ọgagun Adedayọ to jẹ olori wọn nibẹ. Awọn mọ ṣọja to n jẹ Agwu, awọn si mọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ kọọkan ti wọn jọ dana sun ile naa. Bi awọn ko si mọ wọn, awọn mọ ọga awọn ṣọja pata, awọn mọ akọwe ileeṣẹ ologun atawọn ọga to ku, ọwọ wọn si lawọn ti fẹẹ gbowo ile awọn to jona.

Ootọ ni pe awọn ijọba yii ti kọkọ sa lọ, ti wọn ni awọn ko mọ kinni kan nipa ẹ, ko si si ohun to kan awọn lati waa duro niwaju adajọ kan lati maa jẹjọ niwaju rẹ, nigba ti ki i ṣe awọn lawọn dana sunle, ti awọn ko si ṣetan lati sanwo itanran kankan. Ootọ ni pe niṣe ni Fẹla ati lọọya rẹ, Tunji Braithwaite, fi ẹjọ awọn eeyan ijọba yii sun awọn igbimọ agbaye ti wọn n gbọ ẹjọ awọn ti ijọba kan ba fiya jẹ lọna aitọ ki ijọba Ọbasanjọ too le gba pe awọn yoo wa sile-ẹjọ naa, awọn yoo si jẹ ki wọn ri gbogbo awọn ti wọn darukọ pe wọn lọwọ ninu iwa adanasunle yii, awọn yoo jẹ ki wọn fẹnu ara wọn sọ ohun ti wọn mọ nipa ọrọ naa. Ootọ ni pe lati igba ti ẹjọ yii ti bẹrẹ ni ọjọ kẹrinla, oṣu kejila yii, ni gudugbẹ ọrọ ati aṣiri oriṣiiriṣii ti n tu sita, ootọ si ni pe ọrọ naa ti kuro lawada, nibi to de yii gan-an ni wọn pe ni ojuu-koko.

Nigba ti Adajọ Dosunmu wọle, lẹyin ti awọn akọwe kootu ti ṣe sẹrẹnrẹn tiwọn, pẹrẹwu ni ẹjọ naa bẹrẹ, ko tilẹ si ọrọ awada rara, o da bii pe ọjọ naa yoo ro ju awọn ọjọ to ti kọja lọ. Nigba ti awọn ara kootu naa ri oju ti adajọ yii gbe wọle, awọn naa sinmi awada, ko si aaye ẹrin-keekee mọ, wọn n wo ẹnu Adajọ Dosunmu, ṣe oun lo lagbara julọ nile-ẹjọ ti gbogbo wọn wa naa, aṣẹ to ba si pa laṣẹ, ko sẹnikan to gbọdọ yi i. Nigba toun naa si ti wo raaraaraa to ri i pe kaluku to wa nile-ẹjọ naa ti mọ ẹwa lounjẹ ajẹsun, wọn ti mọ pe ile agbara lawọn jokoo si, o pe akọwe kootu ko jẹ ki awọn maa ba ẹjọ naa lọ. Akọwe kootu tun ṣalaye pe ẹjọ to wa niwaju awọn ni ẹjọ ti awọn idile Fẹla pe ijọba apapọ ati awọn ọga ṣọja pata, ti wọn ni awọn yoo gba miliọnu mẹẹẹdọgbọn owo Naira nitori ile awọn ti wọn dana sun.

Lẹyin naa ni wọn pe Lọọya Tunji Braithwaite, pe ko maa waa ba ẹjọ rẹ lọ, ko si maa pe awọn ẹlẹrii rẹ jade. Lọjọ naa, ẹlẹrii nla meji ni Braithwaite pe, awọn ẹlẹrii to ni ọrọ naa gan-an ni. Dokita Bẹẹkọ Ransome Kuti ni lọọya naa kọkọ pe, o ni ko waa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ soun lọjọ naa, ki adajọ le tun gbọ, ko si le ri i pe ododo loun atawọn onibaara oun n sọ, ki i ṣe pe awọn kan ji lọjọ kan lawọn ronu lati waa pe ijọba lẹjọ lori ohun ti ko ṣẹlẹ. O ni oun mọ pe nigba ti Adajọ Dosumu funra ẹ ba gbọ ohun to ṣẹlẹ si ọkunrin ti oun fẹẹ pe jade yii, yoo mọ pe owo ti wọn n beere fun yii kere pupọ si ohun ti awọn ṣọja ṣe fawọn onibaara oun, iyẹn Fẹla ati idile rẹ, atawọn ti wọn jọ n ṣere. Bi wọn ti pe Bẹẹkọ loun naa n tẹ yẹnkẹ bọ, to n tiro lẹgbẹẹ kan, o ni ohun toju oun ri lọjọ naa, lati bii oṣu mẹwaa sẹyin, ko ti i san lara oun.

Njẹ ki lo de o, bawo lọrọ ti ṣẹlẹ, Braithwaite ni ki Beko fẹnu ara rẹ sọ fadajọ ati gbogbo ero iworan. Ọkunrin dokita oyinbo naa ni ọjọ naa ki i ṣe ọjọ daadaa kan foun ni toun rara. O ni ohun to ṣẹlẹ soun lọjọ naa ko ṣẹlẹ si oun ri, nitori oun ko mọ pe iru rẹ ṣee ṣe, tabi pe o le ṣẹlẹ sẹnikan. O ni lọjọ naa ni wọn ju oun jade lati oju windo, wọn ju oun bii ẹni to ju oko ni, wọn ko si ronu pe oju windo ti awọn ju oun gba, irin ati gilaasi ibẹ le ṣe oun leṣe. O ni awọn ṣọja ni wọn ṣe bẹẹ, ki i ṣe eeyan lasan, nitori bo ba jẹ awọn eeyan kan lati ibi kan ti ko si si aṣọ ijọba lọrun wọn ni, awọn iba jọ mu nnkan nilẹ, awọn iba si jọ na an tan bii owo ni. Ṣugbọn awọn ti wọn ya bo ile awọn lojule kẹrinla, Agege Motor Road, ni Mọṣalaṣi, lọjọ naa, ki i ṣe awọn to ṣee ba di mu, ṣọja ni gbogbo wọn pata, wọn ko si ba tere wa, wọn fẹẹ paayan ni.

Aburo Fẹla naa ni ki oun sọ tootọ, oun ko mọ pe oun tun le wa laye lati duro niwaju adajọ maa sọrọ, nitori lilu ti wọn lu oun buru ju, wọn ko si gbọdọ lu ẹranko paapaa bẹẹ ko ma ku pata, Ọlọrun nikan to ni oun ṣi ni nnkan i ṣe laye ni ko jẹ ki wọn lu oun pa. O ni pẹlu pe wọn ko pa oun naa yii o, gbogbo ara loun fi ṣeṣe, oun ko si jẹ eeyan fun ọjọ pipẹ, ẹyin ti wọn ti fi lilu fọ oun leegun. O ni ọrọ ọjọ naa ki i ṣe ọrọ to pamọ ti wọn yoo ṣẹṣẹ maa beere pe boya o ṣẹlẹ tabi ko ṣẹlẹ, o ni titi di oni ti oun n sọrọ yii, iroyin ọrọ naa ko ti i tan ni Muṣin ati gbogbo agbegbe rẹ, bi eeyan si beere ohun to ṣẹlẹ gan-an lọwọ ọmọ ana, yoo royin, yoo maa tọ ilẹ la ni. O ni gbogbo eeyan to wa lagbegbe naa lo ri i bi awọn ṣọja ti ṣe di gbogbo ọna to wọ ile awọn pa, lẹyin ti wọn si ti di ọna naa patapata, ti ẹnikan ko le ba ibẹ kọja ni wọn ṣe ohun ti wọn ṣe.

O ni loootọ ni pe gbogbo bi awọn ṣọja naa ṣe n ṣe wahala lati wọle lawọn n wo wọn, nitori ẹgbọn oun kilọ fawọn pe awọn ko gbọdọ ṣilẹkun fun wọn, nitori oun ko mọ wọn, ati ohun ti wọn n wa nile awọn, wọn ko si ni iwe ijọba kankan lọwọ lati fi wọ ile awọn, bi wọn ba si wọle ti wọn ṣe awọn leṣe, wọn yoo pada purọ mọ awọn ni. Bẹẹkọọ ni ni gbogbo igba ti wọn fi n fa wahala nita yii ni Fẹla ti n wa ọna bi oun yoo ṣe le pe ọga ṣọja kan, tabi ti oun yoo ri ọga ọlọpaa nla kan pe, ko le wa sibẹ, bi awọn ba ti ri eeyan gidi kan ti gbogbo araalu mọ to ba yọju, awọn yoo ṣilẹkun naa fun wọn. O ni ṣugbọn awọn ṣọja naa ko gba, wọn ṣaa n ṣe bii eera to fẹẹ wa ibi ti yoo ba de idi ṣuga ni, pe niṣe ni wọn n yi gbogbo ile po, ti awọn si n gbọ ti wọn n fẹnu ara wọn sọ ọ pe awọn yoo foju awọn ri atalaata baba alaruba bi awọn ba ribi denu ile naa.

Bẹẹkọọ sọ f’adajọ ati gbogbo ero to wa ni kootu pe nigba ti oun ti ri i pe awọn ṣọja naa ribi wọle, ti wọn si ti wa ninu ile, ti awọn kan si n goke bọ sibi ti oun wa, oun jade funra oun lati lọọ pade wọn, oun si ka ọwọ oun mejeeji soke, ki wọn fi le mọ pe ko si nnkan kan lọwọ oun, bẹẹ ni oun ko si mura ija, oun fihan wọn pe oun sọrẹnda fun wọn ni. Ṣugbọn kaka ki wọn gbọ tabi ki wọn dahun, niṣe ni wọn ṣe bii ẹni ti ko mọ itumọ ohun ti oun ṣe, ni wọn ba ko igbaju igbamu bo oun, ti wọn si na oun titi ti wọn fi tun ti oun wọnu ile, nibi ti oun ti n sa fun wọn. O ni nigba ti wọn ti oun wọle tan ti wọn tun na oun, ti oun si sa si ẹgbẹ kan bayii lati fi ara ti ogiri nitori oun fẹẹ ṣubu, nigba naa ni awọn meji ninu wọn sun mọ oun, wọn si palẹ oun mọ yau lẹẹkan naa, wọn si fi oun lakalaka, afi lau ti wọn ju oun gba oju windo lọ.

Bẹkọ ni oun mọ awọn ṣọja ti wọn waa ba oun yii daadaa, ko si ibi ti oun ko ti le foju ara oun ri wọn ti oun ko ni i da wọn mọ, nitori ki i ṣe pe wọn da nnkan boju nigba ti wọn n na oun, awọn jọ feesi ara awọn bayii ni. O ni ohun to si gba agbara ija lọwọ oun ti oun fi n sa kiri bẹẹ ni pe awọn mẹta ni wọn waa ba oun lẹẹkan, ẹni kan si wa ninu wọn ti oun gbebọn dani, ẹnu ibọn naa lo si fi n gba oun sọtun-un ati si osi, to n pariwo pe oun fẹẹ yinbọn, oun fẹẹ yinbọn, kawọn ẹgbẹ oun to ku jẹ ki oun yinbọn. O ni awọn meji to ku ti wọn jọ wa, ko si eyi ti ko si ọbẹ lọwọ rẹ ninu wọn, niṣe ni awọn naa si n fi ọbẹ naa lọ ti wọn n fi i bọ, bii igba pe wọn ti fẹẹ fi da ifun oun lu ni. Bẹẹkọọ ni ohun ti wọn tilẹ fẹẹ ṣe niyẹn, wọn fẹẹ gun oun pa ni, Ọlọrun lo le emi eṣu naa jade lọkan wọn to fi jẹ lilu ni wọn n lu oun bii bara.

O ni nigba ti wọn ba oju windo ju oun lati oke sisalẹ yii, bi oun ṣe tun balẹ, niṣe loun ro pe alaafia diẹ yoo wa foun. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ rara, nitori aarin awọn ṣọja mi-in loun tun balẹ si, awọn eleyii si pọ ju awọn mẹta to n le oun bọ lati oke lọ. O ni awọn ti oun ba yii gbe oun tan nilẹ, wọn si tun sọ oun mọlẹ pada gbii, nibẹ ni wọn ti bẹrẹ si i da igi jọ foun. O ni oun naa mọ pe wọn fẹẹ lu oun pa ree, n loun ba sare dide ti oun n sa lọ fun wọn, ṣugbọn bi oun ti sa sọtun-un, awọn ṣọja wa nibẹ, wọn yoo lu oun laluṣubu ni, bi oun tun dide toun sa si osi, awọn ṣọja ibẹ naa aa tun ki oun mọlẹ, lilu ni wọn yoo si fi pade oun nibikibi ti oun ba yi si, nitori ko si ibi ti oun yi si ti awọn ṣọja naa ko si, wọn ti pọ ju ti wọn wọ ile awọn lọjọ naa. O ni pupọ ti wọn pọ yii kọ ni wahala, ko si eyi ti ko sohun ija oloro lọwọ ẹ ninu wọn.

O ni bi awọn kan ti n fi idi ibọn lu oun, bẹẹ ni awọn mi-in n na oun ni igi tabi kondo, awọn mi-in si wa ninu wọn to jẹ okuta ati oko nla nla ni wọn n sọ lu oun, afi bii ẹni pe oun jale, wọn mu oun ni. O ni awọn ero ti wọn ti rọ jọ n woran, ṣugbọn ko si ẹni to le sun mọ awọn ṣọja yii, nitori awọn naa ri i pe ibi ti awọn wa jinna daadaa sitosi awọn ṣọja yii, bi wọn ba yiju si wọn ki wọn le tete gbe ere nla da si i ni. O ni ko si ohun ti oun le ṣe si i mọ, nigba ti lilu naa pọ ju, niṣe ni oun kuku ṣubu lulẹ, ti oun ko le dide mọ. Ṣugbọn nigba ti oun yoo fi ṣubu yii, iwaju ọkan ninu awọn ọga wọn loun ṣubu si, oun si mọ pe mejọ ni, igbẹyin loun ṣẹṣẹ mọ pe Major Dauda ni wọn n pe e, ọga ṣọja to ṣaaju wọn wa ni. Bẹẹkọ ni Mejọ Dauda yii lo ni ki wọn ma lu oun mọ, ki wọn maa gbe oun niṣo ni baraaki.

O ni ṣugbọn awọn ṣọja naa gbọ ni, ko jọ pe wọn gba, nitori lẹyin ti wọn lu oun titi si i ni wọn bẹrẹ si wọ oun, wọn si n fa oun lọ bii igba ti wọn ba n fa apo irẹsi tabi apo gaari nilẹ ni, wọn ko si ronu pe oun le fi ẹsẹ kọ igọ tabi okuta, tabi nnkan ṣoṣoro mi-in. O ni ta ni yoo tilẹ ronu bẹẹ ninu wọn nigba to jẹ bi wọn ti n wọ oun lọ yii naa ni wọn tun n lu oun, ti wọn si n gba oun lẹṣẹẹ bii pe o n ya wọn lẹnu pe oun ko ti i ku, nitori wọn fẹ ki oun ti ku tipẹ. Bẹẹkọ ni o da bii pe kiku ti oun ko ti i ku yẹn n bi wọn ninu lọtọ, nigba ti wọn si wọ oun de baraaki, wọn ju oun lulẹ gbii, wọn ni ki oun kọju si oorun, oun ko gbọdọ yi ẹgbẹ pada, bi oun ba yira pada pẹnrẹn, wọn yoo jẹ ki ọta ibọn gbigbona dahun lara oun ni. Ohun ti wọn n sọ ni pe wọn yoo yinbọn pa oun bi oun ba yira pada, iyẹn loun si ṣe sinmi jẹẹ sinu oorun nibẹ.

Ọkunrin aburo Fẹla ti wọn jọ n gbele yii sọ pe nigba ti wọn kọju oun soorun bayii, ati wọn mi-in ti wọn tun ko wa pẹlu awọn ti oun ba nibẹ ti gbogbo wọn jẹ eeyan Fẹla, oun n reti pe ki oun ri ọga wọn kan ki oun si bi i leere idi ti wọn ṣe n ṣe gbogbo eleyii fawọn, nitori oun ṣa mọ pe iwa ti wọn n hu ko ba ofin mu, ṣugbọn oun ko le sọ fun awọn ṣọja puruntu ti wọn ko gboyinbo yii, iru ọrọ bẹẹ ko ni i ye wọn. O loun ko ri ọga kankan o, afi nigba ti Ọgagun Adedayọ ti i ṣe ọga pata ni Baraaki Albati yii deede jade sawọn lojiji. O ni bi oun ti ri i loun ṣẹwọ si i, ṣugbọn ko waa ba oun, kaka bẹẹ, niṣe lo kọju si awọn ṣọja to n fiya jẹ awọn, to si beere pe, “Ṣe awọn ti wọn ko wa lati Agege Motor Road niyi?” Awọn ṣọja to beere ọrọ lọwọ wọn da a lohun pe bẹẹ ni, lo ba tun paṣẹ fun wọn, “O daa bẹẹ, ẹ maa ṣe e lọ!”

O ni itumọ “Ẹ maa ṣe e lọ” to sọ fun awọn ṣọja yii ni pe ki wọn tubọ maa fi iya jẹ awọn lọ, nitori bi awọn ṣọja naa ti gbọ bẹẹ, bi wọn ti tun bẹrẹ si i ko bẹliiti bo awọn, ti wọn n sọ idi ibọn mọ oun ni gbogbo ara ree, ti ọkan ninu awọn eeyan naa si fo soke, to n jo lori oun pẹlu bata konko to wọ. Bẹẹkọ ni nigba ti iya naa pọ to debi kan, oun ko tilẹ mọ boya aye ni oun wa tabi ọrun, oun ṣaa n sọ pe bi kinni naa ba fẹẹ ja siku ko tete ja siku, nitori iya to n jẹ oun yii pọ ju fun ẹmi oun. Ọkunrin naa ni bi oun o si ṣe ku ṣi n jẹ iyanu foun titi di asiko ti oun n sọrọ nile-ẹjọ naa, nitori oun ko tun ro pe ẹni kan wa ninu awọn ọmọ Fẹla tabi ẹbi rẹ ti wọn lu to oun, boya nitori wọn ti mọ oun tẹlẹ ni o, tabi nitori oun ati Fẹla jọra, iyẹn ni wọn ṣe da oju sọ oun, ti wọn si fẹ ki oun ku si awọn lọwọ, bẹẹ oun ko ṣe nnkan kan fun wọn.

O ni bo ba tilẹ jẹ nidii lilu yẹn nikan ni wọn ti dawọ ẹ duro, ṣe ọrọ naa ko ni i di eyi ti awọn n fa mọ ara awọn lọwọ ni ile-ẹjọ, ṣugbọn ohun ti wọn ṣe tun buru ju bẹẹ lọ ni. O ni wọn jale, ti wọn ji gbogbo dukia oun ko, bẹẹ ni wọn dana sun ile ti oun ti n ṣe iṣẹ iṣegun oun jẹẹjẹ. O ni dokita oyinbo loun, oun si kọ ile kekere kan si aarin ọgba ile Fẹla yii, ki oun le maa tọju awọn eeyan nibẹ ni. O ni iṣẹ ti oun n ṣe nibẹ niyẹn, yatọ si ti oun ba lọ si ọsibitu to jẹ tijọba ti oun ti n ṣiṣẹ. O ni ko si ologun kan ti i kọlu ọsibitu ni gbogbo aye, afi ti awọn ṣọja Naijiria loun ri ri, nitori awọn ologun mọ pe bi awọn ba farapa, dokita ni yoo tọju awọn, ati pe ile itọju ati iwosan fun gbogbo eeyan, ẹnikan ki i fi iru ile bẹẹ da wọn lagara. Bẹẹkọ ni awọn eeyan naa ji owo oun ati dukia oun ko, wọn dana sun ile ti oun fi n ṣe ọsibitu, wọn si ba irinṣẹ iṣegun oun gbogbo jẹ, owo iyẹn si n lọ si bii ogoji ẹgbẹrun loun nikan.

Nibi to sọrọ de ti Adajọ Dosunmu fi ni ko bọ silẹ ree, o ni ọrọ to sọ naa to, ko ma tori awijare, ki itọ tan lẹnu, gbogbo ohun to sọ pata loun gbọ. Bi oun ti sọrọ ni wọn pe Fẹla funra rẹ, wọn ni ko maa bọ waa ṣalaye oun to ṣẹlẹ si i lọjọ yii o. Niṣe ni gbogbo kootu kun lọ gbuuu, ti awọn ero iworan si n pariwo, “Ọmọ Iya Ajẹ! Ọmọ Iya Ajẹ!” N ni akọwe kootu ba tun ti ariwo rẹ bọnu, o ni, “Ọọọọdaaaa!”

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.