Awọn ṣọja ba ọna mi-in yọ, Wọn ni wọn ba ibọn lọwọ Fẹla ni wọn ṣe dana sunle ẹ

Spread the love

Ija rẹpẹtẹ ni nile-ẹjọ. Laarin awọn lọọya meji ni, Ọgbẹni Tunji Braithwaite ati Ọgbẹni M. Egegele. Nitori Fẹla ni, Fẹla Anikulapo-Kuti olorin. Ọjọ Tusidee lọjọ ọhun bọ si, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 1977. Lẹyin ti awọn ṣọja kan ti dana sun ile Fẹla ni, ti wọn si lu u ni aludaku, ti wọn lu iya rẹ, aburo rẹ ati gbogbo awọn ti wọn ba nile naa, ti wọn si ṣe wọn leṣe gidi, ti wọn waa ko gbogbo wọn sitimọle, ti wọn fi awọn to ku silẹ, ṣugbọn ti wọn ko fi Fẹla silẹ ni tiẹ, ti wọn ni olori awọn ọdaran ni. Ṣebi nitori pe wọn dana sun ile rẹ, wọn ba gbogbo irinṣẹ to fi n ṣere kiri jẹ, ti wọn si sọ gbogbo ohun to ni pata di eeru ni inu ṣe bi Fẹla, ti ọrọ naa si ka iya rẹ, Arabinrin Funmilayọ Kuti, lara pe wọn ba aye ọmọ oun jẹ ni wọn ṣe ni awọn ko ni i gba, ti wọn si gba ile-ẹjọ lọ.

Aṣẹ ni wọn sọ pe ki adajọ pa. Wọn ni ko paṣẹ pe ki olori ijọba, Ọgagun Agba Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ati olori awọn ṣọja pata, Ọgagun T. Y. Danjuma, san ogoji miliọnu fawọn nitori dukia awọn ti wọn bajẹ ati iya ti wọn fi jẹ awọn. Eleyii ja ijọba laya, nitori bi Fẹla ba jare nibẹ, afi ki wọn san owo naa, iyẹn lawọn naa ṣe yaa sare, ni wọn ba pe Fẹla lẹjọ. Lati inu itimọle to wa ni wọn ti gbe e wa si kootu, wọn si fẹsun kan an pe o n sin awọn tọọgi nile rẹ bii ẹni to sin ẹran ewurẹ. Wọn ni oun ni ko ko awọn ọmọ ẹyin rẹ meji nijaanu, ti ko kọ wọn lẹkọọ bo ṣe yẹ ki wọn huwa lawujọ, iyẹn lo ṣe jẹ ki wọn ṣe ṣọja kan, Mari Abu Bau, leṣe, ti wọn si ba alupupu rẹ jẹ, maṣinni ti owo rẹ n lọ si bii ẹgbẹrin Naira (N800). Awọn ọmọ Fẹla meji ti wọn tori ẹ pe e lẹjọ yii ni Mgbanyi Adorogh ati Owolabi Balogun.

Ọrọ naa ya gbogbo eeyan lẹnu, nitori ni bayii, o jọ pe esuru ti paju da, o n le aja lọ: ẹni to yẹ ki wọn mu ni imu ọdaran lo ku to n mu ni ni ọdaran, awọn ṣọja to yẹ ki wọn wọ dele ẹjọ ni wọn tun wọ Fẹla lọ. Wọn ni maṣinni olowo nla lawọn ọmọ Fẹla bajẹ yẹn, awọn eeyan si n lanu pe ninu maṣinni ẹyọ kan, ati mọto rẹpẹtẹ, ati odidi agbala nla ti ile bii meji mẹta wa nibẹ, ati jẹnẹretọ nla meji, ati awọn nnkan mi-in bẹẹ bẹẹ, ewo lo waa jẹ olowo nla o. Ṣugbọn ijọba mọ-ọn-mọ ṣe bẹẹ ki wọn le ko airoju ati airaaye ba Fẹla ati iya rẹ ni. Lọrọ kan, nigba ti wọn gbe ẹjọ naa de iwaju adajọ, Ọgbẹni Egegele fo dide, iyẹn lọọya ijọba, o ni ki wọn ma gba beeli Fẹla. N ladajọ ba ni ki lo de. O ni bi wọn ba gba beeli Fẹla, ṣe wọn mọ pe eeyan kan to lagbara, to si lẹnu niluu ni, yoo da oju ẹjọ naa ru mọ awọn lọwọ ni o.

“Oluwa mi, ṣe ẹyin naa ko mọ Fẹla ni, tabi ẹ ko gbọ orukọ rẹ ri. Bi ẹ ba gba beeli rẹ, to ba fi wa lominira, ti ẹ ni ko maa ti ile wa si ile-ẹjọ yii, mo fẹẹ sọ fun yin pe ko si bi a oo ṣe ri ojutuu ẹjọ yii mọ. Nitori kin ni? Fẹla yoo mọ bi yoo ti le gbogbo awọn ẹlẹrii ti a fẹẹ lo danu ni, a ko si ni i ri ẹlẹrii kan ti yoo waa jẹrii ninu ẹjọ yii mọ, nitori bi wọn ko ba bẹru Fẹla, wọn yoo bẹru awọn ọmọ rẹ, ohunkohun lo si le ṣẹlẹ si wọn. Iyẹn ni mo ṣe sọ pe ki ẹ ma fun un ni beeli, nitori bi ẹ ba fun un ni beeli, ẹjọ bajẹ niyẹn!” Bi oun ti n sọrọ rẹ ni Tunji Braithwaite to jẹ agbẹjọro fun Fẹla n gbọn ẹsẹ popo, o n wo o pe ki lọkunrin Egegele yii n sọ lẹnu ti ko dun yii, nitori yatọ si pe o jẹ lọọya fun Fẹla, ọrẹ timọtimọ loun ati Fẹla, o si mọ ohun tawọn ṣọja yii ṣe, ati ohun to ti bajẹ nile Fẹla, o mọ pe afi ki ọkunrin naa ṣẹṣẹ tun bẹrẹ aye rẹ lati ibẹrẹ.

Iyẹn lo ṣe fo dide, o si sọ fun adajọ pe gbogbo ohun ti ọgbẹni yii to kalẹ ko to lati tori ẹ ma fun Fẹla ni beeli, nigba ti ki i ṣe pe o paayan. O ni ki adajọ yẹ iwe ofin wo daadaa o, nitori bi ẹjọ ki i baa ti i ṣe ẹjọ ti eeyan ku sinu ẹ, ti ki i ṣe pe ẹni ti wọn mu wa paayan, ko si ofin to sọ pe ki wọn ma fun ẹni naa ni beeli. “Oluwa mi, Fẹla to duro niwaju yin yii, o duro bii alailẹṣẹ ni, o digba ti ile-ẹjọ ba dajọ pe o ṣẹ si ẹṣẹ kan ko too di arufin, nigba naa la si too le mu un bii arufin. Ṣugbọn bo ṣe wa yii, a ko le foju arufin wo o rara. Oluwa mi, ẹyin naa ẹ gbọ iru ẹjọ woroworo ti awọn to pe e lẹjọ n ro yii, wọn ni ko ko awọn kan nijaanu, awọn ti wọn n sọrọ rẹ yii, agbalagba ni wọn, wọn fi awọn yẹn silẹ, Fẹla ti wọn wa lọdọ ẹ ti wọn n ba ṣiṣẹ, ti wọn si n gba owo oṣu wọn ni wọn waa mu. Ṣe ẹyin naa ri i pe ọrọ naa kọju sibi kan!”

Braithwaite ni ijọba funra rẹ ti gbe igbimọ kan dide o, igbimọ naa si ti n wadii ohun to ṣẹlẹ, ẹnu ta ni wọn yoo waa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ ju ẹnu Fẹla lọ. Abi itimọle ni yoo ti maa waa jade ti yoo maa waa ba igbimọ naa sọrọ ni. Ọkunrin lọọya yii ni eleyii ko le ṣee ṣe, yoo kan da bii igba ti awọn kan jokoo sibi kan ti wọn n fiya jẹ alaiṣẹ ni, oun ko si fẹ ki adajọ naa ba wọn da si iru ẹ, ko ma lọwọ si i rara. O ni ***ile-ẹjọ ti awọn ọlọpaa ti mu Fẹla pamọ lati bii ọjọ mejila ki wọn too waa gbe e jade yii, ni gbogbo igba ti wọn si mu un pamọ, oore ki lo ṣe fun wọn, tabi wahala wo lo da si wọn lọrun, ki waa ni wọn yoo kan maa pa iṣẹ rẹ lara si, ti wọn yoo ti i mọle lai nidii kan gidi. O ni ko si ohun meji to yẹ ki adajọ ṣe ju ko da ọrọ Ọgbẹni Egegele nu lọ, ko si da Fẹla silẹ, ko gba beeli rẹ, ki ọkunrin naa le lọ sile, ko lọọ ro bi yoo ti ṣe aye rẹ ti wọn daru si.

Ọrọ ti Braithwaite sọ yii mu adajọ lọkan, n lo ba kọwe hẹrẹhẹrẹ, o ni ko si ṣiṣe ko si aiṣe, oun gba beeli Fẹla, ko maa lọ sile ẹ, ko si maa ti ile wa lati jẹjọ ti wọn pe e, nitori ofin kan ko sọ pe ki awọn ti i mọle nitori iru ẹjọ kekere bayii. N lariwo nla ba sọ nita, gbogbo awọn ololufẹ Fẹla to ti wa nita, awọn ọmọọleewe, awọn oṣere ati awọn araadugbo wọn ti wọn ti gbọ pe wọn n gbe e bọ ni kootu ti wọn si waa pade ẹ, inu gbogbo wọn lo dun, wọn si n ki i ku oriire. Nigba to jade si gbangba ti oun naa si ri ero, inu rẹ dun, niṣe lo bẹyin kẹẹ si wọn, bi ara ẹ ko si ti ya to, o juwọ soke si gbogbo wọn, awọn naa si fi idunnu han si i nipa kikọ awọn orin rẹ to kọ, paapaa awọn to ti fi bu awọn ṣọja, ati eyi to ti fi kilọ fun ijọba ologun nipa iwa ibajẹ oriṣiiriṣii. Beeyan ba ti ri wọn ni yoo mọ bi Fẹla ti gbajumọ to, nitori idunnu han loju gbogbo wọn.

 

Ṣugbọn idunnu naa ki i ṣe ti ọlọjọ pipẹ, koda ki i ṣe ti oni wakati kan, idunnu oniṣẹju diẹ ni. Idi ni pe olobo ti ta awọn ọga awọn ṣọja lọhun-un pe bi ẹjọ ti n lọ yii, wọn yoo gba beeli ọkunrin Fẹla yii o, ko si si ohun ti awọn yoo le ṣe, apa awọn ko ni i ka a. Nigba naa ni wọn paṣẹ ologun, wọn lo dikirii (Decree) fun un, wọn ni aṣẹ ologun ti gbe e, ohun ti aṣẹ naa si sọ ni pe ko si iye igba ti wọn ko le fi gbe e timọle si ọgba ẹwọn yoowu ti wọn ba fẹ. Nibi ti ofin naa waa le si ni pe ko si ile-ẹjọ kan to gbọdọ gba beeli rẹ, nitori ofin lati ọdọ awọn olori ijọba patapata ni. Adajọ to n dajọ ko mọ pe wọn ti n ṣeto iru ofin bẹẹ, koda lọọya ijọba Egegele ko mọ, ka ma ti i waa sọ lọọya awọn Fẹla funra ẹ. Niṣe lawọn ro pe ọrọ naa ti yanju sibẹ, Fẹla n lọ sile, bawọn eeyan si ti n ki i ni wọn n gba aarin wọn kọja lati fi mọto gbe Fẹla lọ.

Ẹ wo o, jibiti ti wa lọwọ awọn ọlọpaa, o to ọjọ mẹta. Ṣe ẹ mọ pe ni gbogbo igba ti awọn eeyan fi n jo ti wọn n juwọ si Fẹla yẹn, awọn ọlọpaa wa nibẹ, nigba ti wọn si ri Fẹla to jade, wọn ko sun mọ ọn, wọn mọ pe iyẹn le bi wahala mi-in, ko ma di pe awọn eeyan rẹ yoo bẹrẹ wahala pẹlu wọn. Amọ wọn n ṣọ wọn o, wọn n wo Fẹla ati lọọya rẹ, wọn n wo o bi wọn ti n lọ sidii mọto mẹsidiisi ti iyẹn gbe wa. Ṣe Braithwaite ki i ṣe akuṣẹẹ lọọya, lọọya to rihun ja jẹ yatọ si pako ni: mẹsidiisi lo fi n ṣe ẹsẹ rin, ọkọ awọn olowo nla. Inu mẹsiidiisi yii naa lo gbe Fẹla wọ nigba ti nnkan mi-in tun ṣẹlẹ. Bi Fẹla ti ba ọtun wọle, bẹẹ ni ọga ọlọpaa kan ba osi wọle, awọn eeyan to duro ko si mọ, wọn ro pe ọlọpaa to n sin Fẹla lọ sile ni. Ṣugbọn nigba ti wọn ṣi mọto ni ọga ọlọpaa naa sọ pe olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa Eko lawọn n lọ, ni Lion Building taara.

Njẹ ki lode, wọn ni Fẹla ni awọn iwe kan ti yoo fọwọ si ki awọn too jẹ ko lọ. Bo jẹ ti ifọwọ-siwee, iyẹn ki i ṣe nnkan to le, iṣẹju meloo leeyan yoo fi ṣe iyẹn. Ni wọn ba ni ki wọn maa lọ. Ohun ti awọn ko si mọ ni pe ọkọ mi-in wa lẹyin wọn to jẹ awọn ọlọpaa ni wọn kun inu rẹ bamu. Igba ti wọn gbe Fẹla de Lion Building ni wọn fọgbọn mu un wọle, bi wọn si ti mu un wọle tan ni wọn fa iwe yọ, wọn mu un fun lọọya rẹ. Braithwaite kawe naa, o miri titi. ‘Ki lo wa ninu ẹ?’ Fẹla beere. Lọọya naa sọ pe ditẹnṣan ọda (Detention Order) ni wọn fun un, iyẹn ni pe ijọba ologun ti paṣẹ pe ki wọn ti i mọle fun igba yoowu to ba ti wu awọn lati ṣi i silẹ. Fẹla mi kanlẹ, iyẹn lẹni to ti ro pe oun ti n lọ sile. Paripari rẹ ni pe wọn ko kuku tilẹ ri ọga ọlọpaa to mu wọn debẹ mọ, iyẹn ti ka a nilẹ, o farapamọ fun wọn, awọn ọlọpaa mi-in ni wọn n ri.

Bayii ni wọn ṣe tun mu Fẹla ti wọn ti i mọle o, itimọle tẹni kan o mọjọ ti wọn yoo ṣi i silẹ. Awọn eeyan si n fọwọ-luwọ nigba ti ariwo sọ nijọ keji pe wọn ti tun gbe Fẹla lọ si ile-ẹjọ o, lasiko yii, ile-ẹjọ majisireeti mi-in ni wọn gbe e lọ. Njẹ ki lo tun ṣe. Oun naa ko mọ, lọọya rẹ naa ko si mọ, ojiji lo gbọ pe wọn ti tun n gbe Fẹla lọ, n lo ba sare ko ẹwu awọn amofin sọrun, o di ere lẹlẹ. Ohun to waa ya wọn lẹnu ju ni pe nigba ti wọn yoo tun debẹ, iyẹn ni kootu Saint Ann’s Magistrate Court, Ọga ọlọpaa, Ọgbẹni Egegele, ni wọn tun ba nibẹ. Ọrọ naa ya Tunji Braithwaite paapaa lẹnu, nitori o mọ pe awọn araabi naa ṣẹṣẹ sare to ẹjọ naa papọ ni, bi ko ba sa jẹ bẹẹ, ṣebi awọn jọ wa ni kootu lanaa ni. Ọga ọlọpaa naa ko wo oju Braithwaite, a ki i ti kootu bọ ka ṣọrẹ, iwe to n kọ lo gbájúmọ́, o n reti ki ẹjọ bẹrẹ.

Nigba ti ẹjọ bẹrẹ, ẹsun ọtọ pata ni wọn fi kan ọkunrin olorin yii, iyẹn Fẹla. Egegele dide, o ni lọjọ ti awọn ṣọja lọ si ile rẹ ni ojule Kẹrinla, opopona Agege Motor Road, ni Mọṣalaṣi, lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 1977, iyẹn lọjọ ti wahala ti wọn n sọ yii ṣẹlẹ, wọn ba ibọn rifọọfa kan nile rẹ, ibọn naa le paayan meji mẹta lẹẹkan bi wọn ba bẹrẹ si i yin in, ko si yẹ ki akọrin kan ni iru ibọn bẹẹ nile rara. O ni o lodi si ofin ilẹ wa fun iru ẹni bẹẹ lati ni ibọn nla bẹẹ yẹn nile, ki lo n fi i ṣe o. O ni iyẹn ni ijọba ṣe mu un wa sile-ẹjọ, ki wọn le fi iya to tọ jẹ ọdaran to ba nibọn nile nigba ti ko yẹ ko nibọn. Adajọ beere lọwọ Fẹla pe ṣe o gbọ ọrọ naa daadaa, iyẹn ni oun kuku n gbọ. O tun bi i pe ṣe ọrọ naa ye e yekeyeke, oun naa si dahun pe bẹẹ ni. Nigba naa lo waa bi Fẹla pe ṣe o jẹbi tabi ko jẹbi. Niyẹn ba ni, “Ẹbi kẹ, Oluwa mi, emi o jẹbi o!”

Nibi ti wahala mi-in ti tun bẹrẹ niyẹn. Tunji Braithwaite ni nigba to ti le jẹ awọn ọlọpaa funra wọn ni wọn tun wọ Fẹla wa sile-ẹjọ yii, ti ẹṣẹ rẹ si jẹ eyi to ṣee gba beeli rẹ, ki adajọ fun un ni beeli kiakia, ko ma wulẹ da a duro iṣẹju kan. Ọgbẹni Victor Famakinwa ni adajọ ọjọ naa, o si wo Braithwaite titi, lo waa bi i pe anfaani wo ni beeli ti oun ba fun Fẹla yoo ṣe e, nigba ti ijọba apapọ ti ni ki wọn ti i mọle, wọn ko si gbọdọ ṣi i silẹ, ko si ile-ẹjọ kan to si gbọdọ paṣẹ lori ẹjọ naa. Braithwaite ni ẹjọ iyẹn kọ lo wa niwaju adajọ yii, ẹjọ mi-in ni wọn gbe wa, awọn ti wọn si gbe e wa sa mọ bẹẹ ki wọn too gbe e wa, ko fun onibaara oun ni beeli ko maa lọ o jare. Ọgbẹni Egegele, ọlọpaa lọọya yii, ko jẹ ki ọrọ naa tutu to fi yaa sare dide. O sọ fadajọ pe ara ohun ti oun n wi ree o, njẹ o yẹ ki awọn tun maa sọrọ o ṣe beeli ko ṣe beeli nibi.

Ọkunrin naa ni ọrọ ti ko la ariwo lọ ni, ẹni to gbe panla ti jẹwọ, ki lawọn yoo waa maa sọ asọlaagun ọrọ si, nigba ti ki i ṣe pe nnkan mi-in wa nibẹ. O ni wọn ti paṣẹ, aṣẹ to si wa nilẹ, aṣẹ ologun to ga ni. Ohun ti aṣẹ naa si wi ni pe wọn ko gbọdọ tu Fẹla silẹ ni ọgba ẹwọn ti wọn ba fi i si, adajọ kan ko si lẹtọọ lati gba beeli rẹ, pe ṣe ki i ṣe pe ọkunrin lọọya awọn Fẹla yii fẹẹ koba oluwa oun ni. Egegele ni ẹjọ to wa nilẹ yii ko le pẹ rara, nitori awọn ti to gbogbo ẹri jọ, paapaapaa lawọn yoo si ṣe kinni ọhun bii ẹni to n ra ireke ninu mọto ni Papa, nitori ẹri ti wa nilẹ, awọn ẹlẹrii naa si pọ pẹlu, gbogbo wọn lo mọ pe Fẹla nibọn, ẹran to fi n pa nikan lawọn ko ti i mọ, awọn yoo si wadii ẹ delẹdelẹ ni. O ni eyi ti awọn tilẹ n ba bọ lati ẹyin, ṣe adajọ paapaa ri i pe eremọde ni, eyi to waa wa nilẹ yii lo le ju, ko si yẹ ki wọn jẹ ki Fẹla lọ sibi kan.

 

Adajọ Famakinwa wo oju Tunji Braithwaite, o ni yoo ṣe suuru gidigidi ni o. Idi ni pe ẹjọ to wa nilẹ naa ko ṣee kanju da, bi oun ba fẹẹ da a, oun yoo wadii daadaa, nitori ko si anfaani kan ninu ki oun fi ọrọ ṣofo danu, ọrọ ti adajọ ba sọ gbọdọ ṣẹ ni. Nitori bẹẹ, o ni bo ba di ọjọ keji, iyẹn ni ọjọ kẹta, oṣu kẹta, oun yoo ti mọ bi Fẹla yoo gba beeli bi ko ni i gba a, awọn yoo si mọ boya ki awọn maa ba ẹjọ naa lọ ni kiakia ni. Ọrọ naa ka Braithwaite lara, nitori lọọya ti ko fẹ ẹgbin tabi iwọsi ni, ṣugbọn o jọ pe adajọ ti sọ ododo ọrọ, ko si ere kan ti ẹnikan yoo jẹ ninu ki adajọ sọ pe oun gba beeli Fẹla, ṣugbọn ki ijọba ologun sọ pe ko le jade. Aye ṣọja la wa, o yatọ si aye awọn oloṣelu, laye oloṣelu lawọn eeyan ti n ṣe palapala. N lo ba jade ni kootu, o si fajuro.

Amọ ẹrin ni Fẹla n rin ni tirẹ bi awọn ọlọpaa ti n ṣe girigiri, o kan n wo wọn, o n fi wọn ṣe yẹyẹ ni. O ni kọmọ kan foun ni siga, lara awọn ọlọpaa naa si ṣana si i fun un. Awọn araalu ṣaa n wo o naa ni, awọn ololufẹ rẹ si n sọrọ, wọn n pe, nibo ni ọrọ yii yoo ja si Olodumare.

 

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.