Awọn PDP tako oludije dupo gomina ẹgbẹ wọn nipinlẹ Ọyọ ni kootu

Spread the love

Bi ile-ẹjọ ko ba ni i paṣẹ fun ajọ eleto idibo lati yọ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, kuro ninu awọn akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ n dupo naa ṣaaju idibo, oni yii lọkunrin naa yoo bẹrẹ awijare lati gba ara ẹ silẹ.

 

Ninu igbẹjọ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lawọn oloye ẹgbẹ African Democratic Congress (ADC), meji kan, Wasiu Ẹmiọla ati Abiọdun Adedọja, ti wọn ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ti jẹrii tako Makinde nile-ẹjọ, wọn ni idibo abẹle to gbe e wọle gẹgẹ bii oludije lorukọ ẹgbẹ Alaburada lọwọ kan magomago ninu.

 

Ṣaaju lawọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọn ṣi wa ninu ẹgbẹ ọhun dasiko yii ti lọọ jẹrii tako o ni kootu ninu igbẹjọ to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

 

Ẹni to pe ẹjọ yii, Sẹnetọ Ayọ Adeṣeun, lo rọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ lati fagi le idibo to gbe Makinde wọle, ki wọn si fi orukọ oun rọpo ẹ gẹgẹ bii ẹni ti ẹgbẹ PDP yoo fa kalẹ lati dije dupo gomina lorukọ wọn ninu idibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ naa ninu oṣu kẹta, ọdun yii.

 

 

Awọn ẹlẹrii ti Adeṣeun  ko lọ si kootu lọjọ Tusidee ni wọn sọ pe loootọ ọmọ ẹgbẹ PDP lawọn,

ti awọn si kopa ninu idibo to gbe Makinde wọle, ṣugbọn awọn ko lẹtọọ lati ṣe bẹẹ nitori awọn ki i ṣe ọmọ ipinlẹ Ọyọ, lati ilu Iwo, ni ipinlẹ Ọsun, lọkunrin naa ti lọọ ko awọn waa dibo n’Ibadan, bẹẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn jẹ awọn eeyan ipinlẹ kọọkan nikan lo lẹtọọ lati dibo yan oludije fun ipo gomina wọn.

 

Nigba to n tọka si awọn aiṣedeede to wa ninu ọna ti Makinde gba di ọmọ oye ẹgbẹ ninu idibo gomina ipinlẹ yii, akọwe ẹgbẹ ADC, Wasiu Ẹmiọla, sọ pe gbogbo nnkan ti awọn PDP ṣe lasiko idibo abẹle wọn ni ko bofin mu. O ni apẹẹrẹ iru ẹ ni ti bi wọn ṣe yọ orukọ oun kuro lara awọn oloye.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ninu oṣu kọkanla, ọdun 2017, mo kopa ninu idibo abẹlẹ ẹgbẹ PDP ta a di nileetura Whatershed, n’Ibadan, ninu eyi ti emi funra mi ti dupo akọwe, ti mo si wọle gẹgẹ bii akọwe ẹgbẹ. Ṣugbọn lojiji ni mo ri i ninu iweeroyin pe wọn ti yọ mi nipo. Titi di bi mo ṣe n sọrọ yii, ko si ẹni to sọ fun mi pe wọn ti rọ mi loye, afi ninu iweeroyin nikan tio mo ti ka a.”

 

Bakan naa ni Abiọdun Adedọja sọ pe oun naa wọle idibo gẹgẹ bii akọwe eto iṣuna ẹgbẹ PDP, ṣugbọn oun gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oloye egbẹ ọhun ko mọ nnkan kan nipa bi tikẹẹti idije gomina ṣe dọwọ Makinde titi ti oun fi fi egbẹ ọhun silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADC ti oun wa bayii.

 

 

Igbẹjọ ọjọ Tọsidee yii lo jẹ opin ọjọ awijare fun olupẹjọ atawọn ẹlẹrii ẹ.

Agbẹjọro fun oludije, Amofin Michael Lana, sọ pe awijare awọn ẹlẹrii mẹrẹẹrinla ti awọn ko wa si kootu yii yoo jẹ ki ile-ẹjọ gba pe niṣe ni wọn dọgbọn si iwe orukọ awọn oludibo to gbe Makinde wọle.

 

 

O ṣe e ṣe ki Makinde paapaa ko awọn ẹlẹrii tiẹ naa lọ sile-ẹjọ lonii lati jẹ ki gbogbo aye mọ pe ki i ṣọna eru loun fi gba tikẹẹti,

ẹgbẹ PDP lo mọ-ọn-mọ dibo yan oun lati ṣoju wọn ninu idibo gomina to n bọ yii.

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.