Awọn oludije ninu ẹgbẹ APC Ọyọ ko gba funra wọn, wọn ni ibo lawọn yoo fi yanju ẹ

Spread the love

Ninu awọn mẹtadinọgbọn (27) to n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nikan, pupọ ninu wọn mọ pe oun ko kaju ẹ, awọn ti ko si mọ paapaa ko rẹni sọ fun wọn, afi lọjọ Aiku, Sannde, ijẹrin, nigba ti gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, ba wọn sọ ootọ ọrọ, o ni ki wọn ma tan ara wọn jẹ, ki wọn ro o ki wọn too kori bọ ọ, ko ma ja si pe wọn yoo kan sunwo nina lasan.

Iroyin to ti kọkọ gba igboro kan ni pe niṣe ni gomina pepade naa lati le din awọn to n dije dupo ku si mẹrin ṣugbọn Ajimọbi sọ pe oun ko gbero lati ṣe bẹẹ, awọn ti wọn ni oun sọ bẹẹ ko gbọ oun ye ni.

Gẹgẹ bii ododo ọrọ ti gomina yii ba awọn ondupo naa sọ, “awọn kan wa ninu yin to n dupo to jẹ pe wọn mọ lọkan ara wọn pe awọn ko ni nnkan ti wọn fi n ṣe gomina lara, yala ni towo, ni ti gbigabjumọ tabi ni tọgbọn ori. Mo fẹ ki kaluku yin gbe ara ẹ yẹwo,‎ ki ẹni to ba si mọ pe oun ko kaju ẹ tete gba fun awọn to ba to o i ṣe.

“Ẹni ti ko ba ni miliọnu mejilelogun abọ Naira lọwọ lati gba fọọmu, to si n dupo gomina, tabi ẹni ti ko ni iye miliọnu ti wọn fi n gba fọọmu dupo aṣofin apapọ lọwọ, to jẹ pe awọn kan lo ṣeleri fun un pe awọn maa fun un lowo tabi dawo jọ fun un lati gba fọọmu, o maa daa ki iru ẹyin bẹẹ ro o lẹẹ meji kẹ ẹ too ṣe e, nitori owo tẹ ẹ ṣi maa na lasiko ipolongo idibo gbogboogbo ki i ṣe kekere.

“Ki i ṣe owo nikan leeyan fi n dupo oṣelu to fi n wọle. ẹni ba maa ṣe gomina ni lati jẹ ẹni to gbajumọ, ti awọn eeyan si tẹwọ gba. Ẹlomi-in wa nibi to jẹ pe wọn ko mọ ọn laduugbo to n gbe gan-an, ka ma ti i sọ ni gbogbo ipinlẹ Ọyọ, ṣe iru ẹni bẹẹ lo maa sọ pe apoti idibo gomina lo ku ti oun fẹ gbe?

“Tẹ ẹ ba gbe ara yin yẹwo funra ara yin, ẹni to ba mọ lọkan ara ẹ pe oun ko le ṣe e, ko tete jawọ nibẹ ka wa nnkan kan mi-in fun un. Ẹlomi-in, owo to ni lọwọ to rọra fi n maneeji aye ẹ lo maa na danu lori pe n o dupo, owo to yẹ ko rọra maa fi jẹun jẹẹjẹ.

“Purogirẹsiifu oloṣelu lemi. Mo ṣoṣelu labẹ awọn ọga wa ti wọn jẹ purogirẹsiifu daadaa. To ba jẹ Ọga wa Lam Adeṣina (gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri),  ni, iwe ni wọn maa mu dani ti wọn maa kọ orukọ awọn ti wọn ba fẹ ko dije dupo lorukọ ẹgbẹ silẹ, ko lọrọ ibo didi kankan ninu. Bẹẹ naa ni baba wa Adedibu, iwọ too ba tiẹ tun kọ to o ni ko tẹ ẹ lọrun, to o ba ṣọra, o tun le jiya nibẹ. Ṣugbọn emi fi aaye ibo didi silẹ kẹ ẹ ma sọ pe emi ni mo fi tulaasi gbe ẹnikan le yin lori.”

Pẹlu gbogbo imọran ti gomina yii gba awọn ondupo naa, ko si ẹni to gba lati fẹyin silẹ fun ẹni kan ninu gbogbo wọn ti wọn fi tuka lọjọ Satide ijẹrin.

Nnkan kan ko yipada nigba ti ipade ọhun tẹsiwaju  lọjọ Sannde ijẹta. N ni gbogbo wọn ba kuku fẹnu ko si ibo didi. Wọn ni ki gbogbo ẹni to ba da ara ẹ loju jade si gbangba, ibo lawọn yoo fi yanju ẹ lati mọ ẹni kan ṣoṣo ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ yii ninu idibo gomina to n bọ.

Yatọ si minisita fun eto ibanisọrọ nilẹ yii, Amofin Adebayọ Shittu, ti ko yọju sibi ipade naa nitori ko si njile, gbogbo awọn ṃẹrindinlọgbọn (36) yooku ni wọn peju pesẹ pẹlu Gomina Ajimọbi funra ẹ atawọn oloye ẹgbẹ APC ipinlẹ naa eyi ti Alaga wọn, Oloye Akin Ọkẹ ko sodi.

Lara wọn ni gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Ọtunba Adebayọ Alao Akala; akọwe agba ijọba ipinlẹ naa, Ọlalekan Alli; kọmiṣanna fun eto iṣuna, Dokita Azeez Adedunta; Kọmiṣana fun ọrọ ilẹ, Isaac Ọmọdewu; Joseph Tegbeh; Amofin-agba Niyi Akintọla; Adebayọ Adelabu;, Ọmọwe Morounkọla Thomas; Kẹhinde Ọlaoṣebikan ati bẹẹ bẹ lọ

Ajimọbi tun ṣe iru ipade yii kan naa pẹlu gbogbo awọn to n fifẹ han lati dupo sileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, atawọn ileegbimọ apapọ mejeeji niluu Abuja lọjọ Sannde ijẹta, lẹyin ti wọn pari ipade awọn ondupo gomina. Abajade ipade ọhun naa ko si yatọ si eyi to waye ninu ipade awọn to fẹẹ dupo gomina. Wọn ni ẹnikan o ni i fẹyin silẹ̣ fun ẹnikan, ibo ṣaa lawọn maa di lati yan awọn ti yoo ṣoju ẹgbẹ APC ipinlẹ Ọyọ ninu idibo gomina atawọn ileegbimọ aṣofin gbogbo.

Irufẹ ibo ti wọn fẹnu ko le lori naa ni eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo yan aṣoju lati ijọba ibilẹ gbogbo lati wa dibo yan awọn oludije dupo lorukọ ẹgbẹ naa.

 

 

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.