Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati ADP fija pẹẹta ni Ogbomọṣọ, wọn ṣa ara wọn ladaa yannayanna

Spread the love

Yannayanna lawọn janduku oloṣelu ṣara wọn ladaa, ti ọpọ eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ si farapa nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), atawọn ọmọ ẹgbẹ Action Democratic Party (ADP) fija pẹẹta niluu Ogbomọṣọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

 

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ, iyẹn ni kete ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pari ipolongo ibo wọn niluu Ogbomoṣọ lawọn janduku inu ẹgbẹ naa pẹlu awọn tọọgi inu ẹgbẹ ADP pade ara wọn laduugbo Oke-Elerin, nijọba ibilẹ Ariwa Ogbomọṣọ. Lọgan ni wọn kọlu ara wọn, ti ija ọhun si dija igboro gidi.

 

O ṣee ṣe ki ija ọhun ba nnkan jẹ kọja ohun ti eeyan le fẹnu royin bi ki i ba ṣe pe awọn ọlọpaa tete debẹ lati pana ija ọhun. Toun ti bẹẹ naa, awọn onija yii ti fi ada dara sira wọn lara jinna ki awọn agbofinro too de. Atọmọ ẹgbẹ kin-in-ni ati ikeji lo si fara gbọgbẹ nla nla.

 

Lọgan lawọn ileewosan to wa lagbegbe naa bẹrẹ si i gbalejo awọn to fara gbọgbẹ lọkọọkan ejeeji.

 

Awọn ẹgbẹ mejeeji ti n naka aleebu sira wọn lori iṣẹlẹ yii,  kaluku n sọ pe jẹẹjẹ awọn lawọn n lọ, awọn ẹgbẹ keji gan-an leku ẹdá to da wahala silẹ.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin, alaga ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Bukọla Badmus, sọ pe, “a ṣe ipolongo ibo lọ si awọn adugbo kan nijọba ibilẹ yii. Nigba ta a pari ni nnkan bii aago mẹfa lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADP doju ija kọ awọn eeyan wa kan laduugbo Oke-Elerin.

 

“Awọn eeyan wa n gbiyanju lati beere pe ki lo faja. Nigba yẹn gan-an ni wọn waa bẹrẹ ija gan-an, ti wọn si ṣa wọn ladaa yannayanna. Bẹẹ lawọn eeyan mi-in naa tun farapa.

 

“Inu awọn ọmọ ẹgbẹ ADP ko dun si bi awọn oloṣelu kan to jẹ ogunna gbongbo ọmọ ẹgbẹ wọn l’Ogbomọṣọ ṣe darapọ mọ ẹgbẹ wa (APC), laipẹ yii lara ṣe n kan wọn. Wọn fẹẹ da wahala silẹ ki awọn eeyan ma baa jade lọjọ idibo”.

 

Awọn ADP paapaa sọ ninu awijare tiwọn naa pe awọn APC lo deede fiya jẹ awọn eeyan awọn nibi ti wọn ti n lọ jẹẹjẹ wọn.

 

Gẹgẹ bi Ọnarebu Bimbọ Ọladeji to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa Ogbomọṣọ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ṣe sọ, o ni awọn paapaa n ṣe ipolongo ibo lọjọ naa ni, ati pe oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADP, Ọtunba Adebayọ Ala-Akala, funra ẹ lawọn tọọgi ẹgbẹ APC fẹẹ ṣe leṣe ti wọn fi kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn.

 

Obinrin naa fidi ẹ mulẹ pe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn ṣa ladaa yanna yanna, ati pe Lati Kilani ni ọkan ninu awọn eeyan awọn ti awọn APC ṣe leṣe n jẹ. Ọkunrin naa si wa nileewosan lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ yii.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.