Awọn lọbalọba gbọdọ ṣıṣẹ lori idasilẹ ọlọpaa agbegbe__Ooni

Spread the love

Ko sẹni ti yoo de agbegbe aafin Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi lọjọ Satide to kọja ti ko ni i mọ pe alejo nla kan wọ ilu naa wa. Ṣe ti awọn elere ibilẹ ti wọn wa nisọri-isọri ni ka sọ ni, tabi ti awọn ẹṣọ alaabo ti wọn duro wamuwamu.
Alejo Ọba Ewuare Keji latilẹ Benin ni Ọjaja gba lọjọ naa, lati nnkan bii aago mẹwa owurọ ni gbogbo aafin ti n rọkẹkẹ, awọn lọbalọba kaakiri ilu nipinlẹ Ọṣun ti jokoo pẹlu aṣọ to joju ni gbese lati darapọ mọ Ọọni gbalejo naa.
Bo tilẹ jẹ pe Ọọni ana, Ọba Okunade Ṣijuwade, ati Ọba ti Benin ana, Erediuwa maa n wa ara wọn daadaa, ti ibaṣepọ to dan mọnran si wa laarin wọn, sibẹ, abẹwo eleyii ni yoo jẹ akọkọ ti Ọba Ewuare yoo ṣe siluu Ileefẹ lati ọdun to kọja to ti de ori oye.
Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ pe ọpọ nnkan lo baramu laarin Ileefẹ ati Benin; bẹrẹ lati imura awọn ẹṣọ ọba, titi de ori awọn onijo ibilẹ ti wọn n yẹ ọba si.
Nnkan bii aago mejila kọja ni Ọba Ewuare de sinu aafin tilutifọn, gbogbo awọn araalu ti wọn si ti jokoo kaakiri tẹlẹ bẹrẹ si i rọ wọnu Ile Oodua kẹtikẹti lati ri ọba naa.
Lẹyin ti awọn elere ibilẹ lati ilu mejeeji fi ere da awọn eeyan laraya tan ni Ọba Ewuare sọrọ, o ni eredi abẹwo naa ni lati tubọ mu ki okun ifẹ le dan-in dan-in si i laarin ilu mejeeji, nitori pe ọpọlọpọ nnkan lo so ilu mejeeji papọ.
Ọba Benin lo asiko naa lati gboriyin fun Aarẹ Mohammadu Buhari fun ipa to n ko lori ọrọ eto aabo lorileeede yii, ṣugbọn o ni o ṣe ni laaanu pe ojoojumọ ni ipaniyan n waye latọwọ awọn Fulani darandaran, ti ede aiyede ko si dinku laarin awọn agbẹ bakan naa.
Ewuare ni ko si amojuto to peye lawọn ibode to wọle sorileeede yii, eleyii to mu ki irinajo ifiniṣẹru (child trafficking) ati idigunjale pọ, paapaa lagbegbe Ila-Oorun Ariwa orileede yii.
O waa rọ Aarẹ Buhari lati wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo naa ko ma baa pagi dina ibaṣepọ to dan mọnran laarin awọn ọmọ orileede yii.
Ọọni Ogunwusi fi idunnu rẹ han si abẹwo Ọba Benin, o ni ẹbi kan naa ni Ileefẹ ati Benin, ati pe awọn yoo ṣiṣẹ tọ abẹwo naa, yoo si mu eso rere jade.
Ọọni ni lara ohun to mu ki itan ilu mejeeji papọ ni pe Oranmiyan jẹ ọba ni ilu Benin, Ọyọ ati Ileefẹ, bi ki i baa si ṣe ti asiko, o yẹ ki wọn ṣabẹwo si ibi ti wọn sin Ọranmiyan si.
Ni ti eto aabo orilẹede yii, paapaa niha Ariwa ti Ọba Ewuare mẹnuba, Ọọni Ogunwusi ni iṣẹ naa kọja eyi tijọba nikan le da ṣe, awọn ori-ade naa gbọdọ ṣetan lati kun ijọba lọwọ.
O ni awọn lọbalọba gbọdọ ṣıṣẹ lori idasilẹ ọlọpaa agbegbe, ki onikaluku si bẹrẹ si i ṣọ agbegbe rẹ.
Lẹyin eyi lawọn ọba mejeeji ṣabẹwo si “ọrun ọba ado” nibi ti wọn nigbagbọ pe wọn sin awọn ọba ilẹ Benin kan si ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin ko too di pe awọn oyinbo amunisin fagile aṣa naa.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.