Awọn iṣẹ ti ko ṣe anfaani faraalu lo pọ ninu ohun ti ijọba ṣe Ajimọbi- Akala

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Ọtunba Adebayọ Alao-Akala ti ṣapejuwe iṣejọba Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ti i ṣe gomina ipinlẹ naa gẹgẹ bii eyi ti ko faaye gba igbaye-gbadun awọn araalu.

 

Ninu ipade oniroyin to ṣe ni gbọngan Jogor Centre lati kede erongba iṣejọba ẹ fun gbogbo aye gẹgẹ bii oludije dupo gomina ipinlẹ ọhun ninu idibo ọdun 2019 lorukọ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party (ADP), lo ti sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja

 

Nigba to n gbe iṣejọba Ajimọbi leri oṣuwọn, Akala ṣalaye pe “gbogbo ẹ ni ko daa. Ewo lo daa ninu gbogbo ijọba rẹ? Ẹ sọ fun mi. Ṣe eto ẹkọ lo daa ni abi eto ọgbin, abi eto ọrọ aje? Ara n ni araalu. Ṣe bo ṣe ri lasiko ijọba temi niyi? Ta a ba da gbogbo eto iṣejọba ẹ (Ajimọbi), si ọna ọgọrun-un, ida aadọrun-un ninu ẹ lo tako igbaye-gbadun awọn araalu. Gbogbo ẹ pata ni mo fẹẹ tun ṣe. Eto ẹkọ ni mo si maa kọkọ mojuto ni kiakia.”

 

Njẹ ki lo de ti ko ba gomina sọrọ nigba to jẹ pe ọrẹ ni wọn, oludije lorukọ ẹgbẹ ADP yii fesi, o ni “mo sọ sọ sọ ko gbọ ni, nigba ti ki i gbamọran.”

 

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu eto ti ijọba Ajimọbi ṣẹṣẹ gbe kalẹ lati maa gbowo-ori lọwọ awọn ileejọsin gbogbo. O ni bii igba ti eeyan ba fẹẹ maa fi ara ni awọn eeyan Ọlọrun nigbesẹ ọhun, paapaa nigba ti ki i ṣe okoowo ni wọn n fi mọṣalaṣi ati ṣọọṣi ṣe.

 

Nibi eto ọhun lo ti ṣafihan Ọjọgbọn Abideen Ọlaitan Ọlaiya gẹgẹ bii igbakeji ẹ, to si kede Oloye Wale Ohu gẹgẹ bii oludari igbimọ ipolongo ẹ.

 

Diẹ lara awọn igi-lẹyin-ọgba Akala to kopa nibi eto ọhun ni iyawo ẹ, Oloye Arabinrin Kẹmi Akala pẹlu awọn eekan oloṣelu bii Ọnarebu Temitọpẹ Ọlatoye Sugar, Dokita Fọla Akinọṣun, Pasitọ Dare Ojo, Alhaja Risikat Oyebimpe Alabi to ṣe kọmiṣanna feto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ lasiko ijọba rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Orin ti wọn si n kọ seti awọn araalu ni pe “ẹ gbàgbálẹ̀ lọwọ wọn, ẹ gba’gbalẹ lọwọ wọn, k’an too gba’re Ọyọ danu, ẹ gbàgbálẹ̀ lọwọ wọn”.

 

Ta o ba gbagbe, ọrẹ ni Ajimọbi ati Akala n ṣe lati bii ọdun meji sẹyin, inu ẹgbẹ APC ni wọn si jọ wa titi ti ipinya fi de ba wọn. Akala fi ẹgbẹ naa silẹ nigba to ti mọ pe ọrẹ oun ko ni i gba oun laaye lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn ọhun.

 

 

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.