Awọn ara Oke-Ogun beere fun ileewe giga to jẹ tijọba apapọ lagbegbe wọn

Spread the love

Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ṣeleri lati wa nnkan ṣe si bi ileewe giga to jẹ tijọba apapọ yoo ṣe de agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ.

 

Ileri ọhun ko deede waye bi ko ṣe nitori bi awọn ara agbegbe naa ṣe n rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati da ileewe giga kan silẹ lọdọ tiwọn naa.

 

 

Lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja ni Ọjọgbọn Ọṣinbajo fi ileri ayọ naa to wọn leti lasiko abẹwo ẹ si aafin Bagii ti ilu Ṣaki, ni ipinlẹ Ọyọ.

 

Baagi tilu Ṣaki, Agba-oye Adegoke Ghazaal Abdul-Rasheed, ti i ṣe igbakeji ọba ilu naa ti sọ pe pẹlu bi agbegbe Oke-Ogun ṣe tobi to lati da duro laaye ara wọn gẹgẹ bii odidi ipinlẹ kan, o ṣe ni laaanu pe ko si nnkan kan ti wọn le tọka si lagbegbe ọhun lati fi han pe ijọba mọ riri wọn lorileede yii.

 

 

Abdul-Rasheed, ẹni to gbẹnu awọn ara agbegbe naa sọrọ ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu ki oju ọna ọkọ oju irin ta a mọ si reluwee kan gba agbegbe Oke-Ogun kọja, tabi ki ijọba apapọ tiẹ fi ileewe giga kan da wọn lọla.

 

 

Nigba to n fesi si ibeere ọhun, Ọjọgbọn Ọṣinbajo sọ pe bi ilu ba ṣe tobi to, ati bi awọn eeyan ba ṣe pọ to nibẹ lo maa n tọka si irufẹ iṣẹ idagbasoke ti ijọba apapọ maa ṣe fun wọn ati pe ni ti agbegbe Oke-Ogun, ko si aniani pe agbegbe naa ti tobi to lati janfaani ileewe giga kan to jẹ tijọba apapọ.

 

O ni oun yoo gbe igbesẹ lori bi kinni naa yoo ṣe tẹ wọn lọwọ.

 

Bakan naa lo sọrọ lori ọja agbaye kan ti wọn n pe ni Okerete Transborder International Market ti wọn fẹẹ da silẹ niluu Ṣaki, ṣugbọn ti ijọba ti pati lati ọjọ yii. O loun yoo ri i pe ijọba fi ọrọ ọja naa sinu aba eto iṣuna ọdun to n bọ, ki wọn le rowo kọ ọ pari.

 

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.