Awakọ tasin fi mọto ṣeeyan leṣe n’Ibadan, ladajọ ba sọ ọ sẹwon

Spread the love

Ahamọ ọgba ẹwọn ni awakọ tasin kan, Azeez Ismail, wa bayii pẹlu bo ṣe fi mọto wọ obinrin kan, Raji Mariam, nilẹ tuurutu, ti iyẹn si fara pa yannayanna ni nnkan bii aago kan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala oṣu kin-in-ni, ọdun yii, laduugbo Ọja’ba, n’Ibadan.

 

 

Adajọ kootu ibilẹ onipo kin-in-ni to wa ni Mapo, n’Ibadan, Onidaajọ I. T. Akindoroye, lo sọ awakọ naa ti nọmba iṣami ẹ jẹ KSH 517 XA (Ọyọ), si ahamọ ọgba ẹwọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

 

 

Sajẹnti Ayẹni Ayọdele, ọlọpaa to gbe arufin naa lọ sile-ẹjọ, ṣalaye pe aawọ kan lo ṣẹlẹ laarin Ismail ati obinrin ọhun to n jẹ Raji Mariam laduugbo Ọjaba, n’Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019 yii.

 

O ni nibi ti wọn ti n ba ara wọn fa a lọwọ ni Ismail ti ṣina fun ọkọ rẹ, ti ibi kan lara ilẹkun mọto naa fi kọ iya naa laṣọ, to si bẹrẹ si i wọ ọ lọ. Sibẹ, awakọ yii ko duro, afigba to ri i pe awọ ara onitọhun ṣi mọlẹ daadaa, to si fara ṣeṣe rẹpẹtẹ.

 

 

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ lo ṣẹlẹ lỌja’ba lọjọ naa ti Abilekọ Mariam fi deede gburoo pe mọto kan kọlu ọkọ oun latẹyin. Bo ṣe sọ kalẹ lọọ ba Ismail, iyẹn onitasin to kọlu u lariyanjiyan bẹ silẹ nitori ti iyẹn ko gba pe oun jẹbi.

 

 

Wọn ni bi iya naa ṣe pada sinu mọto ẹ lo ri i pe wọn ti ji owo ati foonu oun lọ. Nitori eyi lo ṣe pada lọọ ba awakọ ero naa ti nọmba iṣami ẹ jẹ KSH 517 XA (Ọyọ). Ọrọ yii ni wọn n fa lọwọ ti onitasin fi ṣina fun ọkọ rẹ, bẹẹ ẹni ti wọn jọ n sọrọ ṣi rọgbọku le ilẹkun tasin naa ti ko ti i kuro nibẹ. N ni mọto ba bẹrẹ si i wọ ẹni-ẹlẹni lọ nilẹ tuurutu.

 

 

Ẹsun ifiyajẹni lọna aitọ ati ole ni wọn fi kan onimọto ọhun ni kootu, ṣugbọn ọkunrin naa loun kọ jẹbi ọkankan ninu ẹsun mejeeji.

 

 

Sajẹnti Ayọdele ṣalaye pe Ismail lawọn fura si pe o ji baagi Mariam gbe. O ni ẹgbẹrun mẹrin ati igba Naira (N4,200) pẹlu ẹrọ ibanisọrọ ti owo ẹ to ẹgbẹrun marundinlogoji Naira (N35,000), ati kaadi igbowo lẹnu ẹrọ lo wa ninu baagi naa. Nitori naa, yatọ si pe olujẹjọ yii ti ṣe obinrin naa leṣe, o ti daran owo ti apapọ ẹ jẹ ẹgbẹrun mọkandinlogoji ati igba Naira (N39,200).

 

 

Onidaajọ Akindoroye faaye silẹ fun olujẹjọ lati gba beeli ara ẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (150,000), ati oniduuro meji ti wọn jẹ onipo kẹjọ lẹnu iṣẹ ijọba. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si Ọjọruu, Wẹsidee, ọla.

 

Ṣugbọn olujẹjọ ko lagbara owo beeli naa, n lawọn agbofinro ba mu un lọ si ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.