Atiku pariwo: BUHARI FẸẸ ṢOJOORO IBO YII NI O APC ni: Irọ lo n pa o, ẹ ma da a lohun!

Spread the love

Lanaa yii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019, ta a wa yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ifilọlẹ igbimọ nla ti yoo ṣeto ipolongo ibo rẹ, Buhari fẹẹ du ipo aarẹ Naijiria lẹẹkeji, ṣugbọn iṣoro wa fun un nitori awọn ẹgbẹ alatako n binu, awọn eeyan kọọkan laarin ilu naa si sọ pe ko yẹ ko tun ṣejọba lẹẹkeji. Baba naa ko gba, o ni oun ko ti i pari iṣẹ oun, koda oun ko ti i ba iṣẹ ohun debi kan, iyẹn lo si ṣe gbe igbimọ nla dide ti yoo ṣeto ipolongo rẹ, awọn alagbara inu ẹgbẹ APC ati awọn saraki saraki ilu mi-in lo si ko jọ soju kan. Igbimọ nla gbaa ni. Alaga meji ni igbimọ naa ni, nitori bi oun Buhari funra rẹ ti jẹ alaga, bẹẹ ni Bọla Ahmed Tinubu naa jẹ alaga. Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga APC ati Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo to n jẹ igbakeji Buhari naa ni wọn yoo ṣe igbakeji awọn alaga igbimọ yii.

Ko tan sibẹ, awọn eeyan nla nla bii Raji Faṣọla, Bisi Akande, John Oyegun, Ọlọrunibẹ Mamora atawọn eeyan nla nla bẹẹ ni wọn ko jọ sinu igbimọ naa, pẹlu gbogbo awọn aṣofin pata ati awọn gomina APC ti wọn ti fipo silẹ, ati awọn olori ile-igbimọ aṣofin. Ohun ti wọn fẹẹ ṣe naa ni ki wọn ṣe ipolongo ti yoo gbona, awọn ipolongo ti yoo mi gbogbo Naijiria titi, ti awọn araale yoo fi gbọ, ti wọn yoo sọ fun awọn ara-oko pe nnkan n bẹ. Wọn ni Buhari gbọdọ wọle lẹẹkeji, ko si ohun to gbọdọ di i lọwọ. Ṣugbọn lati ibẹrẹ lo jọ pe iṣoro kan ti wa o, iṣoro kan ko si ti ita wa, lati inu ile lo ti wa. Ọkunrin kan wa ti wọn n pe ni Rotimi Amaechi. Ọkunrin yii ni Ọga Agba pata fun ileeṣẹ to n ṣeto ipolongo idibo fun Buhari lẹẹkeji. Oun naa lo ṣe olori igbimọ naa nigba to fi n ṣe gomina ipinlẹ Rivers lọdun 2015, minisita eto igbokegbodo ọkọ si ni bi a ti n wi yii, Buhari lo n ba ṣiṣẹ.

Ṣugbọn lọsẹ to kọja yii, awọn aye gbe fidio kan jade, fidio naa jẹ nibi ti ọkunrin naa ti n sọrọ, to n bu Buhari. Ọkan ninu awọn agbẹnusọ fun aarẹ ana, Goodluck Jonathan, ti wọn pe ni Reno Omokiri lo gbe e jade. O ni o pẹ ti awọn eeyan bii Rotimi Amaechi yii ti n fẹnu wọn ja waya kaakiri, ti wọn si n sọ fun Buhari pe awọn fẹran rẹ ju iya ati baba awọn lọ, ṣugbọn oun fẹẹ fi han gbogbo aye, ki Buhari funra rẹ naa si mọ pe irọ ni wọn n pa fun un. Iyẹn lo ṣe kọkọ gbe fidio naa jade lẹgbẹẹ kan, eyi to si gbe jade ni ibi ti Amaechi ti sọrọ Buhari lai daa. O ni, “Aarẹ wo le tiẹ n sọ? Aarẹ ti ko gbọran, bẹẹ ni ko mọ ohun to n lọ! Ṣe oun tiẹ le kawe kankan ni!” Bi Amaechi ti wi ninu fidio naa ti awọn aye ju u sori ẹrọ ayelujara niyẹn. Ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ ni ileeṣẹ Aarẹ ti ni fidio naa ki i ṣe tuntun, wọn ni Jonathan ni Amaechi n ba wi.

Ọmọkiri naa ko duro, kia loun naa ṣalaye pe fidio ti oun ju sita yẹn, ẹgbẹ kan ni, oun si mọ-ọn-mọ ṣe bẹẹ ni. O ni oun ti mọ pe ileeṣẹ Aarẹ yoo sọ pe irọ loun n pa, iyẹn loun ṣe ge diẹ ku ninu fidio akọkọ, o ni fidio ẹlẹẹkeji ni yoo tu aṣiri Amaechi. N lo ba ju iyẹn naa sori atẹ. Ninu fidio keji yii, Amaechi ni, “Aarẹ wa ki i gbọrọ sẹnikẹni lẹnu, ko si kia, ohun to ba wu onikaluku lo le kọ, ṣe oun tiẹ n kawe ni! Ani lọjọ kan, mo wa ninu ẹronpileeni pẹlu ẹ nibi ti ọkunrin ẹlẹran kan ti n binu pe oun ko ri ẹran ọdun ta nitori ijọba Buhari. Mo ni ṣe aarẹ n gbọ, o ni ki lo kan oun pẹlu ẹlẹran to wa l’Onitsha!” Fidio naa si fihan gedegbe pe Buhari ni Amaechi n ba wi. Ko sẹni to le sọrọ ninu APC, ọrọ naa si fihan pe kọlukọlu ti ba wọn nileeṣẹ Aarẹ. Kaluku awọn aṣaaju APC lo n sa kijokijo bayii, wọn ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ rara.

Ariwo ti wọn n pa lọwọ ree ti awọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo fi dide, ti wọn ni awọn yoo ṣe iwọde agbayanu kan, bi ọga ọlọpaa pata ko ba fẹyinti titi di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu ta a wa yii. Ohun ti wọn ṣe sọ bẹẹ ni pe lati ọjọ kẹta, oṣu yii, lo ti yẹ ki Ibrahim Idris, ọga ọlọpaa yii, fẹyinti ninu iṣẹ ọlọpaa, nigba to jẹ ọjọ naa lo pe ọdun marundinlogoji to ti wọ iṣẹ ọhun, ọjọ to si yẹ ko fẹyinti niyẹn. ṣugbọn ọkunrin naa bẹrẹ si i paara ọdọ Aarẹ Buhari, titi di bi a si ti ṣe n wi yii, ko sẹni to gbọ kinni kan, tabi to mọ ohun ti Aarẹ da ọga ọlọpaa yii duro si. Wọn ko tilẹ mọ boya Aarẹ lo da ọga ọlọpaa naa duro abi oun funra rẹ ni ko fẹẹ lọ. Iyẹn lawọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo to ku nilẹ yii ṣe sọ pe awọn yoo ṣe iwọde nla, ki ọkunrin naa le tete maa lọ. Awọn ọmọ Atiku tilẹ ti sọrọ, wọn ni lara irinṣẹ ti Buhari fẹẹ lo lati fi ṣojooro ibo to n bọ yii ni Idris, ọga ọlọpaa pata.

Awọn ọmọ Atiku yii ni ọrọ ti awọn n wi lati ọjọ yii ree o, ti awọn n sọ pe ko si ohun meji ti Buhari gbojule ju ojooro to fẹẹ ṣe lọ. Wọn ni bi eeyan ba ti gbọ ohun ti Amaechi sọ, tọhun yoo ti mọ pe ẹgbẹ APC ko le wọle ibo, nigba to jẹ oun ni alakooso agba fun ileeṣẹ to n ṣeto ipolongo ibo aarẹ, to si fẹnu ara rẹ sọ pe aarẹ awọn ko mọ ohun to n lọ, ki i kawe, ko si n gbamọran ẹnikẹni. Atiku ni bi a ba ti yọwọ awọn ṣọja, ọlọpaa ati INEC to gbojule, ko si ẹni ti yoo dibo fun un lati gbe e wọle lẹẹkeji. Wọn ni ohun ti awọn ṣe pariwo ni ti ọrọ INEC naa niyẹn. Ni tododo, ariwo ti wọn pa lori ọrọ ileeṣẹ to n ṣeto idibo yii, iyẹn INEC, ti wọn n sọ yii, ko ti i tan nilẹ rara, kinni naa n ja ran-in ran-in, ọrọ naa si ti di ohun ti gbogbo awọn alagbara Naijiria n da si. Ọrọ obinrin kan ni, obinrin ti wọn n pe ni Amina Zakari.

Lojiji ni INEC kede pe awọn ti yan Zakari gẹgẹ bii olori ẹka ti yoo ka gbogbo ibo ti wọn ba di lasiko ibo ọdun 2019. Ọrọ naa ko ba ti la ariwo lọ, bi ko ṣe pe agbara nla wa lọwọ ẹni ti wọn ba pe lolori awọn ti yoo ka ibo, paapaa nitori bi a ṣe n ṣe nnkan tiwa ni Naijiria nibi, to jẹ ẹni to ba jẹ alaga ibi kan naa ni gbogbo agbara maa n wa lọwọ rẹ. Ko ba ti si ariwo pupọ nidii ẹ bi ko ṣe pe nigba ti wọn darukọ obinrin yii, ariwo ta, nitori pe ọmọ ẹgbọn Buhari funra rẹ ni. Ohun to bi awọn ọmọ Atiku ninu ree, wọn ni ile awọn Zakari, lọdọ ẹgbọn rẹ to fẹ ọba ilẹ Hausa kan, ni Buhari funra rẹ gbe titi ko too di bọisi. Wọn ni Buhari lo si yan Amina Zakari si INEC, nigba ti aarẹ Jonathan ni ko fa eeyan kan kalẹ ti yoo wa ni INEC bii aṣoju rẹ. Ṣugbọn ileeṣẹ Aarẹ ni ọrọ naa ko ri bẹẹ, wọn ni loootọ lawọn eeyan naa kanra, ṣugbọn ko le to bi wọn ti n sọ ọ yẹn.

Nigba ti aṣiri ọrọ naa si ti tu pata, ileeṣẹ Aarẹ ko le wi kinni kan mọ, nitori bi wọn ti n sọrọ kan ni awọn ti wọn mọ itan Buhari ati Amina Zakari n ja wọn. Iyẹn ni Atiku atawọn eeyan rẹ fi mu ariwo nla bọnu, wọn ni o ti han gbangba pe Buhari fẹẹ ṣojooro ibo yii ni. Wọn ni gbogbo ọna pata lo ti la kalẹ lati ri i pe awọn eeyan ṣojooro ibo naa foun. Ọmọ ẹgbọn rẹ lo wa ni INEC ti yoo ṣeto ibo kika, awọn ṣọja yoo wa laarin ilu ti wọn yoo maa fibọn halẹ, ọga ọlọpaa ti yoo ṣeto aabo ni ko lọ yii, bẹẹ asiko rẹ ti to lati fẹyinti, wọn tun waa ni wọn ko ni i jẹ ki ẹnikẹni gbe iye ibo ti wọn ba di nile idibo jade, afigba ti INEC ba ka gbogbo ẹ tan ti wọn kede ẹ funra wọn. Atiku ni awọn n pariwo bayii karaalu le mọ pe Buhari fẹẹ ṣojooro ibo to n bọ yii ni o. Amọ Festus Keyamo to jẹ alukoro awọn APC ti sọrọ, o ni bo ba jẹ ọrọ Atiku leeyan n feti si, oluwarẹ yoo kan maa da ọkan rẹ laamu ni, nitori irọ nla lo n pa, oun gan-an si lolori awọn olojooro.

Ọrọ naa ti loyun sinu bayii o, iru ọmọ ti yoo bi lẹni kan o ti i le sọ.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.