Atiku kigbe lojiji: Ẹ ma jẹ ki Buhari du ipo aarẹ mọ o *Ẹ ma da a lohun, oniyẹyẹ lasan ni – Lai Muhammed

Spread the love

Bi kinni kan ba wa to ṣẹru ba Alaaji Atiku Abubakar to fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP lọsẹ to kọja yii, awọn ero rẹpẹtẹ ti wọn n wọ bii omi lati pade Aarẹ Muhammadu Buhari ni ilu Kano ni. Ero naa pọ ju debii pe lati ọjọ ti wọn ti n ṣe kampeeni idibo to n bọ yii, ko ti i sibi ti ero ti pọ to bẹẹ yẹn ri. Awọn eeyan naa pọ debii pe ọpọ awọn ti wọn wa ni ọwọ isalẹ ko le gbọ ohun yoowu ti Buhari ba sọ, nitori ko si iye gbohungbohun ti wọn le gbe debẹ ti yoo de ọdọ wọn, awọn ero naa gbe ohun Buhari funra rẹ mi patapata. Ohun to fa ibẹru ni pe awọn oloṣelu gbogbo naa mọ pe bi awọn eeyan naa ba jade, ti wọn ba dibo bi wọn ṣe to nni, ko si ẹgbẹ oṣelu ti yoo le rọwọ mu nibẹ rara. Loootọ Atiku naa ti de Kano yii, oun naa si ri ero tirẹ ni iwọnba, ṣugbọn awọn ero ti Buhari pe wa ode yii, wọn yoo to ilọpo marun-un ti Atiku.

Bii ẹni pe awọn ti wọn n ta ọja nibẹ ti mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ ni, nitori bẹẹ ni gbogbo ọlọja ṣe ti ṣọọbu wọn pa. Awọn ọlọja ti wọn wa ni agbegbe Muritala Muhammed General Hospital, awọn ti wọn wa ni ọja Kwari, ti wọn ti n taṣọ ati lawọn ibomi-in to sun mọ papa iṣere nla ti Sani Abacha ti Buhari yoo ti ṣe kampeeni rẹ, gbogbo wọn ni wọn ti ṣọọbu wọn pa pinpin, awọn naa n wo ohun ti yoo ṣẹlẹ nigba ti Buhari ba de. Nigba ti Buhari yoo fi de loootọ, gbogbo adugbo naa lo ti kun akunfaya, ko si sẹni kan ti wọn bi daadaa ti yoo ni oun ṣi ṣọọbu, tabi oun n ta ọja kan nitosi nibẹ, wọn yoo jẹ igba rẹ run lẹsẹkẹsẹ ni. Nigba ti Buhari funra rẹ si foju kan awọn ero ti wọn waa pade rẹ, oun naa ni oun ko mọ ohun toun fẹẹ sọ fun wọn ju pe oun waa dupẹ, ki oun si sọ fun wọn pe bi wọn ṣe ṣe ni 2015 naa ni ki wọn tun ṣe.

Ohun to faja gan-an niyẹn. Awọn eeyan Atiku ni gbogbo ṣakara ti Buhari ati awọn eeyan rẹ n ṣe, ibo Kano ni wọn gbojule, wọn ni ibo ti wọn yoo di nibẹ ki i si i ṣe ibo kan daadaa, ibo to maa n ni makaruu ninu ni. Wọn ni ki i ṣe gbogbo awọn tawọn eeyan ri ni Kano yẹn ni ọmọ ẹgbẹ APC tabi ọmọ Naijiria ti wọn fẹran Buhari, wọn ni awọn alejo, ajeji pọnnbele ti ọrọ Naijiria ko kan rara, ti ko si yẹ ki wọn de ibi ti wọn ti n dibo lo pọ ninu wọn. Wọn ni awọn mi-in wa lati orilẹ-ede Nijee, bẹẹ lawọn mi-in si wa lati orilẹ-ede Chad. Imale sọrọ, ojo ku gbuu, o ni Ọlọrun ṣe ẹri oun. Nigba ti Ọlọrun yoo jẹrii awọn eeyan PDP yii loootọ, awọn eeyan nla kan wa lati orilẹ-ede Nijee, wọn waa pade Buhari ni Kano, wọn ni awọn waa ṣe atilẹyin fun un, nitori oun lawọn fẹ ko wọle. Gomina lawọn mejeeji, orilẹ-ede Nijee yii ni wọn si ti wa.

Gomina Issa Moussa ti ipinlẹ Zinder, ni Nijee, ati Gomina Zakiri Umar, ti ipinlẹ Maradi, pẹlu ọpọlọpọ ero lẹyin wọn ni wọn jọ wa si Kano lati pade Buhari, o si jọ pe awọn naa ko mu ọrọ idibo naa ni kekere rara, gbogbo iranlọwọ ti wọn ba le ṣe ni wọn fẹẹ ṣe fun Buhari. Inu Gomina Kano, Umaru Ganduje, dun lati ri awọn eeyan nla nla lati Nijee yii debii pe o paṣẹ fun ọkan ninu awọn alukoro rẹ pe ko ju kinni naa sori afẹfẹ, ko gbe e sori ẹrọ ayelujara ki gbogbo aye le foju ri i pe ki i ṣe ara Naijiria nikan lo wa lẹyin Buhari, awọn ara Nijee naa wa lẹyin ẹ, wọn fẹ ko wọle. N ni Salihu Yakassai to n ba Ganduje ṣiṣẹ ba ju kinni ọhun sori ẹrọ ayelujara, o ni awọn ti ni awọn alejo pataki lati orilẹ-ede Nijee, wọn waa ba Buhari ṣe ipolongo, ọkunrin yii lo si jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn ara Nijee ti de Naijiria, ati pe nitori Buhari ni wọn ṣe wa.

Nigba naa ni ọrọ di ibinu fun awọn ọmọ ẹgbẹ PDP, wọn ni ohun ti awọn n wi lo delẹ yii o. Wọn lo ti pẹ ti awọn ti n sọ ọ pe awọn ti a maa n ri lẹyin Buhari nni, alejo lati ilẹ okeere lo pọ ninu wọn, nitori awọn kan ti n sọ pe lati apa ibẹ naa ni Buhari funra rẹ ti wa. Uche Secondus ti i ṣe olori ẹgbẹ naa ni awọn ti n sọrọ naa tipẹ, awọn eeyan kan o kan gba awọn gbọ ni. Nigba naa ni Atiku fibinu sọrọ. Ọkunrin naa ni ko si ohun to yẹ ki INEC tun maa duro de mọ, lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ri awọn gomina ilẹ okeere yii lo ti yẹ ki wọn yọ orukọ Buhari danu ninu iwe awọn ti wọn n dije. O ni bi wọn o ba ti i ṣe bẹẹ, ki wọn tete ṣe e, nitori o ti daju pe Buhari ko ni i daabo bo iṣọkan ati iduroṣinṣin orilẹ-ede yii, yoo kan ta wa fawọn ara ilẹ okeere gbẹyin ni. O ni kawọn eeyan ba INEC sọrọ ki wọn tete yọ orukọ Buhari, nitori baba naa ti ṣẹ sofin.

Ọrọ naa dun awọn ọmọ Buhari, paapaa Lai Muhammed. Lai ni, alaye ti Atiku ati awọn eeyan rẹ n ṣe yii ko mu ọgbọn dani, ero ti wọn ri lẹyin Buhari lo n ja wọn laya. Ṣugbọn ko sẹni to le ṣalaye idi tawọn ero rẹpẹtẹ bẹẹ fi n tẹle Buhari, ti wọn si mu un bii olori-awo wọn, to jẹ ibi yoowu to ba n lọ ni wọn n tẹle e lọ. O ni Buhari paapaa ko le ṣalaye ẹ, oun naa kan ri i pe ero n wọ lẹyin oun bii omi ni. O ni lati sọ pe ki INEC yọ orukọ Buhari fihan pe oniyẹyẹ lawọn eeyan naa, wọn kan n ṣe awada akọ lasan ni. INEC paapaa tiẹ ti fesi, awọn naa ni ko si idi kan ti awọn fi fẹẹ yọ orukọ Buhari, wọn ni awọn ti wọn wa lati Nijee ti wọn n wi yẹn ko waa dibo, nigba ti wọn ko ni iwe idibo kankan, wọn kan waa ṣe ayẹyẹ fun ọrẹ wọn lasan ni, ofin ko si sọ pe keeyan ma waa ba ọrẹ ẹ ṣe ayẹyẹ. Abi ki lo tun ku.

Loootọ bi eeyan yoo ba wo ọrọ ipolongo ibo awọn mejeeji yii daadaa, yoo ri i pe ọpọlọpọ ohun ti Buhari n ri ni ilẹ Hausa ni gbogbo ibi to ba lọ, iye awọn ero rẹpẹtẹ yii naa ni Atiku n ri ni ọpọlọpọ awọn agbegbe ilẹ Ibo, boun naa ba ti de ibi kan lero n tẹle e, ti wọn yoo si maa pariwo rẹ bii ẹni pe ọmọ adugbo wọn ni. Eyi fihan pe Atiku naa yoo ri ọwọ mu ni ilẹ Ibo ju Buhari lọ,  bẹẹ ni awọn ara agbegbe Plateau si Adamawa naa si n fẹ tirẹ ju ti Buhari lọ. Ṣugbọn apapọ awọn ero ipinlẹ meji-mẹta ko ti i to ti Kano, ohun to si n ba awọn eeyan ti wọn n tẹle Atiku lẹru niyẹn, awọn ero Kano naa ko girigiri ba wọn. Ni tilẹ Yoruba ẹwẹ, bi ogunlọgọ awọn eeyan ti wa lẹyin Buhari ni ọpọ eeyan wa lẹyin Atiku naa, o si di ẹyin ti wọn ba dibo tan ki wọn too mọ ẹni to ju ẹni kan lọ ninu wọn.

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.