Atiku gbiyanju, boju ọjọ ṣe ri yii naa ni

Spread the love

Ọpọ eeyan ko mọ pe Atiku yoo de ibi to de yii rara. Pẹlu gbogbo ariwo to ti wa niluu yii, ati ọrọ ti wọn so nipa Atiku, ko yẹ ki ọpọlọpọ eeyan to pọ to bẹẹ yẹn dibo fun Atiku rara, nitori ole ni wọn pe e, akowojẹ ni wọn pe e, oriṣiiriṣii orukọ ni wọn si fun un. Ṣugbọn pẹlu gbogbo orukọ ti wọn pe e yii, pẹlu gbogbo ariwo rẹ ti wọn pa, ati ipolongo iwa ibajẹ gbogbo to hu, sibẹ, awọn ọmọ Naijiria jade lati dibo fun un, ibo naa si pọ debii pe o ṣẹru ba awọn ti wọn n ṣejọba. Ko si ọṣẹ ti ijọba yii yoo fi wẹ ẹ pe awọn ko ṣe ojooro, bi wọn sọ ọ, ọpọ eeyan ni ko ni i gba wọn gbọ, paapaa lori awọn ohun ti wọn ṣe. Ijọba yii kan naa lo fa igi le awọn ibo nibi ti Atiku ti lero lẹyin, awọn naa ni wọn fi agbofinro SSS mu awọn ti wọn jẹ oṣiṣẹ ati igilẹyin ọgba rẹ ti wọn ba ti mọ pe wọn wa nibi kan to le ṣe akoba fawọn, ọpọ ibo ni wọn fagile, ọpọ iwa ni wọn si hu to fihan pe wọn ko ṣe daadaa fun Atiku ati ẹgbẹ oṣelu rẹ. Bẹẹ ki i ṣe Atiku lo yẹ ki ijọba yii fi ikanra mọ, tabi pe ki wọn ṣe aidaa fun, nitori gbogbo ohun ti wọn ba ṣe fun un, ọmọ Naijria ni wọn ṣe e fun. Bẹẹ ni wọn ko le bu ọmọ Naijiria pe wọn ṣe dibo wọn fun Atiku, ọrọ lo su wọn, ibi ti nnkan n lọ ni ko ye wọn, loju wọn, ohun ti ijọba yii n ṣe ko dara. Ebi n pa ọpọ eeyan, bẹẹ ni iya si n jẹ wọn, inira to mu wọn ni wọn fi di ibo wọn fun Atiku, nitori ẹni ti wọn ro pe o le gba awọn niyẹn. Ṣugbọn bi eto ilẹ yii ṣe ri ko jẹ ki eyi ṣee ṣe. Nitori bẹẹ, ọgbọn lo yẹ ki ijọba yii fi ohun to ṣẹlẹ yii ṣe, ki wọn mọ pe Naijiria ti debi kan bayii to jẹ ijọba ti ko ba ṣe daadaa fun wọn, wọn yoo le e danu ni. Buhari ati ẹgbẹ APC gbọdọ mọ pe araalu fẹẹ le wọn lọ tefetefe, ọgbọn lawọn naa da si i ni, bi ko ba jẹ bẹẹ, wọn yoo lọ patapata ni. Amọ bi wọn ko ti lọ yii naa, ki wọn ri i pe awọn mu idẹrun ba awọn araalu, awọn si ṣe daadaa fun wọn. Bi bẹẹ kọ, iyẹn bi ara ko ba tu awọn eeyan yii naa, epe lawọn naa yoo maa ṣẹ, epe yoo si maa ja wọn ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe ni. Ẹ sọ fun Buhari ko ṣe aye e re lasiko yii o, inira kankan ko tun gbọdọ ba mẹkunnu ilẹ yii mọ.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.