Atiku binu sọrọ si Buhari O ni, “Baba ẹ jẹ n raaye ṣe temi o!”

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn ọmọ ẹyin rẹ ko mu ọrọ ibo to n bọ yii ni kekere o. Gbogbo ọna pata ni wọn n gba lati ri i pe baba naa pada si ipo rẹ, o si ṣejọba Naijiria fun ọdun mẹrin mi-in si i. Awọn minista n fi gbogbo ara ja ni bayii, bẹẹ ni awọn oludamọran ati awọn gomina gbogbo ti mura ipolongo ti yoo milu titi lati Ọjọbọ, Alamisi, to n bọ yii, nitori ọjọ naa ni ipolongo ibo yoo bẹrẹ fawọn ti wọn ba fẹẹ du ipo aarẹ. Ohun ti ajọ to n ṣeto idibo, INEC, gbe jade ni pe lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla yii, awọn oloṣelu ti wọn ba fẹẹ du ipo aarẹ ti le bẹrẹ ipolongo wọn. Ohun to fa imurasilẹ ree, nitori awọn eeyan kan ti pinnu pe ko si ohun to le da awọn duro tabi di wọn lọwọ, wọn yoo tun gbe Buhari wọle lẹẹkan si i. Iṣoro kan naa ni wọn ni o: Atiku Abubakar ni.
Awọn ti wọn n ṣejọba yii ko fi ọwọ dẹngbẹrẹ mu ọrọ ọkunrin Atiku yii, wọn ni oun lo fẹẹ di awọn lọwọ, ṣugbọn awọn yoo fun un lokun lọrun debii pe ko ni i le lọ. Kaakiri ni wọn ti dẹ okun silẹ fun un, awọn ti wọn sun mọ ile ijọba si n leri pe ko si ọna ti yoo gbe e gba ti ọwọ ko ni i to o. Adams Oshiomhole, alaga APC, to ṣẹṣẹ bọ ninu ijangbọn awọn DSS bayii naa ti figba kan leri pe ẹgbẹ awọn ko ni i gbejọba fun PDP, koda ki wọn wọle ibo, bi yoo ti ṣe bi awọn tọhun ba wọle ni ko ṣalaye fẹnikan. Ṣugbọn awọn alagbara ninu Aso Rock ko duro de eyi, wọn n wo ọna ti wọn yoo tete fi de ọwọ Atiku mọgi, ti wọn yoo si le e danu pe ko le du ipo naa mọ, nitori awọn ohun kan to ṣe. Gbogbo agbara ni wọn fẹẹ lo le e lori, igbagbọ wọn si ni pe bi awọn ba lo agbara naa tan, yoo jawọ ninu ilakaka rẹ lati koju Buhari.
Ijẹta to ti ilu Dubai de ni wọn gbe ọkan ninu awọn eto ti wọn ti ni silẹ fun un yọ, Ọlọrun lo si yọ ọkunrin naa. Fun bii wakati kan ti ẹronpileeni to gbe e wa lati Dubai fi de ni awọn agbofinro DSS, ọlọpaa ati ṣọja fi ya bo ẹronpileeni naa, pẹlu awọn irinṣẹ loriṣiiriṣii. Wọn n tu inu ẹronpileeni naa yẹbẹyẹbẹ. Bi wọn ti n gbe maṣinni wọ abẹ awọn aga, bẹẹ ni wọn n ṣi gbogbo kọrọ to wa ninu ẹronpileeni ọhun wo, ti wọn si ni ki Atiku funra rẹ duro ko le foju ara rẹ ri oun ti awọn yoo ba ninu ẹronpileeni to gbe wa. Awọn kan ninu wọn tilẹ ni ki ọkunrin to fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ PDP naa lọọ jokoo sibi kan, ati awọn ọmọ pẹlu awọn oṣiṣẹ rẹ, ṣugbọn tọhun taku, o ni gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe, loju oun ni ki wọn ti ṣe e, oun ko ni ibi kan i lọ.
Lẹyin ti awọn eeyan naa ti lo bii wakati kan ti wọn ko si ri kinni kan, wọn tun eto naa bẹrẹ lati ilẹ, wọn si tun ṣe bi wọn ti ṣe e, o si n lọ si bii wakati meji ki wọn too jade nikọọkan, ti wọn fajuro pe awọn ko ri kinni kan ninu ẹronpileeni naa, ko maa ba tirẹ lọ. Ọrọ naa ka Atiku lara, o si binu, o ni yatọ si pe ọrọ naa jẹ ifiniwọlẹ, ẹronpileeni oun yii naa ṣa ni Buhari funra rẹ lo ni gbogbo igba to fi n ṣe kampeeni, ko si si ọjọ kan ti wọn da a duro bẹẹ ri, tabi tawọn agbofinro bẹrẹ si i yẹ iwe inu rẹ wo, ti wọn n da gbogbo nnkan rẹ ru. Ki lo waa de ti Buhari yoo jẹ ki wọn ṣe eleyii foun. Atiku ni inu oun ko dun bi Buhari ṣe n lo awọn agbofinro, paapaa awọn DSS, to jẹ owo araalu ni wọn fi n sanwo oṣu fun wọn, ṣugbọn to jẹ awọn naa gan-an nijọba yii n lo lati fi dẹruba awọn eeyan kiri.
Ẹni kan to waa sọrọ to jẹ pe o ko ijaya ba Atiku ati awọn eeyan rẹ ni ọkunrin kan to ti wa ninu APC tẹlẹ, alukoro ẹgbẹ naa ni, Timi Frank lorukọ ẹ. O ni oun mọ ete tawọn agbofinro yii waa da, oun si mọ ohun ti wọn waa ṣe. Frank ni bi wọn ṣe wa yẹn, wọn gbe apo owo tabua to jẹ owo ilẹ okeere dani, bo ba si jẹ Atiku kuro nidii baalu rẹ ni, ọgbọn ni wọn yoo fi da awọn owo naa silẹ, ti wọn yoo ya fọto rẹ, ti wọn yoo sare gbe e sori ẹrọ ayelujara pe Atiku ti lọọ gba owo wa lati ilẹ okeere, o fẹẹ fi da Naijiria ru ni. O ni iyẹn lawọn DSS ati awọn ọlọpaa ti ko wọṣọ ṣe ya bo ẹronpileeni naa, wọn ti mura pe ti Atiku ba lọ ni wọn yoo da awọn baagi naa sinu ẹronpileeni fun un, nigba ti wọn si ti mọ pe awọn ọmọ Naijiria ko ni i wadii ọrọ ki wọn too maa bu Atiku, kia ni wọn yoo ju u sori intanẹẹti.
O ni ki i ṣe pe wọn yoo tori ọrọ naa ti Atiku mọle, wọn kan fẹẹ fi i ṣe yẹyẹ ki wọn si ba a jẹ loju awọn eeyan ni. Ọrọ naa bi awọn PDP funra wọn ninu, alukoro ẹgbẹ naa, Kọla Ologbondiyan, si jade pe awọn ko ni i gba iwa ihalẹ, ka maa dunkooko mọ ni, ati ka maa fi DSS ati awọn ṣọja dẹruba ni ti awọn Buhari fẹẹ maa ṣe yii, o ni ki gbogbo aye ma sun asunpara o, nitori bi ohunkohun ba ṣẹlẹ si Atiku, ki wọn ti mọ pe Buhari ati awọn ọmọ rẹ ni. O ni orilẹ-ede Naijiria ki i ṣe ilu ti wọn ti ko awọn eeyan ibẹ lẹru, ko si yẹ ki olori ijọba kan waa maa ṣe bii pe oun lolori ologun to ko awọn to ku lẹru, ijọba dẹmokiresi la n ṣe, aaye si wa fun kaluku lati ṣe ohun to ba wu u labẹ ofin, nigba ti ko ba ti pa ẹlomi-in lara, ti ko si ni ki awọn eeyan ma ṣe tiwọn. Kọla ni ki wọn fi Atiku silẹ, ki wọn pade rẹ lọjọ idibo, ki gbogbo aye le ri ẹni to ba lero lẹyin julọ.
O da bii pe ohun to n dun awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria yii ju ni didakẹ ti Atiku lọọ dakẹ mọ Dubai lati bii ọsẹ meji sẹyin, to ni oun n ṣe igbaradi ati ipalẹmọ fun eto iplongo oun. Nibi to wa lọhun-un yii naa ni alaga PDP, Uche Secondus, ti lọọ ba a, ti oludari eto ipolongo rẹ, Bukọla Saraki, to jẹ olori ile-igbimọ aṣofin Naijiria ti lọọ ba a, atawọn eeyan jankan jankan mi-in ninu ẹgbẹ wọn. Iroyin ti Alaroye gbọ lati ibẹ ni pe aisun ni wọn n fi ojoojumọ ṣe, wọn si ti la gbogbo eto kalẹ lori bi wọn yoo ṣe gbajọba lọwọ Buhari. Gbogbo eto yii ni wọn ti kọ sinu iwe, iwe ilana yii ni wọn yoo si tẹle lati ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Olori ẹṣọ kan sọ fun Alaroye pe iwe eto ipolongo Atiku lawọn agbofinro ti wọn bo ẹronpileeni rẹ n fọgbọn wa, wọn fẹẹ gbe iwe naa ki wọn le mọ gbogbo ohun to fẹẹ ṣe.
Ọrọ naa ko dun mọ Atiku ninu rara, awọn ti wọn sun mọ ọn si n sọ pe inu rẹ ko dun si Aarẹ Buhari, nitori o ni oun ti ṣe daadaa fun un ju ohun to waa fẹẹ ṣe foun yii lọ. O ni ko sija ninu ọrọ to wa nilẹ yii, awọn ọmọ Naijiria ni yoo fi ibo wọn sọ ẹni ti awọn ba fẹ, ẹni ti wọn ba si fẹ naa ni yoo maa ṣejọba wọn, ki waa ni Buhari yoo maa dẹ awọn agbofinro soun si, ti yoo si sọ Naijiria di ẹni yẹyẹ loju awọn orilẹ-ede agbaye gbogbo. Ko sẹni to le sọ bi ipolongo ibo naa yoo ti lọ si, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe Atiku ti pada de bayii, Buhari funra rẹ si ti mura silẹ, o si da bii pe eegun baba naa ti le ju tatẹyin wa lọ, iyẹn lawọn eeyan rẹ ṣe n sọ pe ko sibi ti oun naa ko ni i de ni Naijiria lati sọ ohun toun yoo ṣe fun wọn. Iran ọrọ naa yoo dun-un wo o, nigba ti awọn alagbara meji ba pade ara wọn.

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.