Ati ọkunrin onifila gogoro ilu Abẹokuta

Spread the love

Ibikunle Amosun naa ko ro pe aye tun ku sibomi-in ju ọwọ oun nikan lọ. Ẹni to ba fẹẹ ku ko ku; ẹni to ba fẹẹ fori sọlẹ ko fori sọlẹ; ẹni to ba fẹẹ po soda mu ko po sọda mu; awọn ọrọ ẹnu Amosun ree, nitori pe ọrẹ loun ati Buhari, oun si ni alagbara ipinlẹ Ogun, ko sẹni to tun ju u lọ ninu ẹgbẹ naa mọ. Ṣugbọn Amosun ti gbagbe pe awọn kan ni wọn ni ẹgbẹ naa ki oun too wa, ati pe ẹbẹ ni oun bẹ ti oun fi di ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ AC to pada waa di APC. Ojoojumọ lo n ba Oluṣẹgun Ọṣọba ti awọn kan mọ bii ẹni to jẹ opo ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ogun ja, ko si si ẹlomiiran to lẹnu ti ko ti ṣeto lati ti ṣẹgbẹẹ kan. Nigba ti ibo gomina si n bọ ti gbogbo aye n pariwo pe Amosun nigba, Amosun lawo, oun naa ko jẹ ki wọn sọrọ ju, ohun to n sọ ni pe oun ni APC ipinlẹ naa, ohun ti oun naa ba ṣe loun ṣe, ẹni ti oun ba mu loun mu, ko sẹni ti yoo si yẹ oun lọwọ wo nidii ẹ, ẹni ti o ba fẹẹ bẹ ludo ko ma ṣafira ni. Ani nigba ti wọn dibo abẹle APC ti awọn kan jẹwọ fun un pe bo ti wu ki ọmọde tete ji to, ọna ni yoo ba kukute, ko si bi ọmọde yoo ti mọ ere i sa to ti ko ni i jẹ ọna ni yoo maa ba ilẹẹlẹ. Ọtọ lẹni ti oun mu, ẹni ti apa rẹ yoo ka, ti yoo maa paṣẹ fun, ti yoo si maa dari rẹ lati ṣe gbogbo ohun ti oun Amosun ba fẹ. Ṣugbọn lọjọ idibo lawọn ọga rẹ fagba han an, ẹlomi-in toun ko tilẹ ronu si ni wọn fa yọ lojiji, nigba ti yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti mu un. O sare jonijoni lọ si Abuja, ṣugbọn ibi ti wọn ti mu un ko daa. Nigbẹyin, wọn gba igba oyin lọwọ rẹ, wọn gbe igba ata le e lọwọ, oun naa si mọ pe ninu ẹgbẹ APC l’Ogun, bii igba ti wọn sọ oun di korofo ni, tabi ṣọja ti ko lọmọ lẹyin mọ, nitori owo to n ri fawọn eeyan ati ipo to n fi wọn si lo jẹ ki wọn maa tẹle e, bi ko ba ti si bẹẹ mọ, wọn yoo ba ẹlomiiran lọ ni. Nnkan ti bọ lọwọ Amosun, afaimọ ki fila gogoro yii ma di fila pẹrẹki, nitori ọrọ to bẹrẹ wẹrẹ yii, igbẹyin rẹ yoo le diẹ o jare. Pẹlẹ o, Amosun, diẹdiẹ lọrọ n kẹ, ẹni to ba mọ aye i jẹ ki i g’agbọn.

 

(54)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.