Ati Baba arugbo ti wọn pe ni Rasidi Ladọja nilẹ Ibadan

Spread the love

ti di ibi ti wọn yoo ti pin ipo, ti wọn ba ti ni ipo gomina ko tọ si Baba Ladọja, nitori pe baba ti darugbo, ija yoo de ni. Ija gidi. Bi ija ba si ti de bẹẹ, ki awọn eeyan too mọ ohun to n ṣẹlẹ, baba yoo ti gbe apamọwọ wọn, wọn yoo fa ọmburẹla tabi ọpa lọwọ, wọn yoo ni ẹni ba fẹẹ lọ ko tẹle awọn, inu ẹgbẹ mi-in ya niyẹn. Ṣugbọn loni-in yii, bi wọn ba tiẹ fi Baba Ladọja ṣe gomina Ọyọ, bawo ni baba ro pe oun yoo ti ṣe ijọba ipinlẹ naa daadaa pe arugbo tabi agbalagba kọ ni wọn fi n ṣejọba, pe ki i ṣe eegun tabi agbara ni wọn yoo lo, beeyan jẹ ọmọde to jẹ agbalagba, ko si bi o ti le ṣejọba, nitori awọn eeyan ni yoo maa gbe iṣẹ naa fun ṣe. Iṣẹ ti o ba gbe kalẹ ni Naijiria yii, boya iṣẹ tirẹ tabi ti ijọba, ti o ko ba ti le ṣe eyi to pọ nibẹ funra tiẹ, iṣẹ naa yoo bajẹ ni, awọn eeyan ti o ba ko jọ ni wọn yoo ba iṣẹ naa jẹ pata. Bo si jẹ iṣẹ ijọba ni, amojuto lo ni iṣẹ naa, ki i ṣe ki eeyan gbe iṣẹ fawọn eeyan ki oun sun lọ. Wọn ko ni i ṣe iṣẹ naa, wọn yoo si nawo to ba yẹ ki wọn fi ṣe e. Ẹni to le lọ sọtun-un to le lọ sosi, to ni agbara Nigba ti wọn ba n sọrọ awọn oloṣelu alarinkiri ni ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ, yoo ṣoro ki ẹnikan too gba ade irin-ajo bẹẹ ju Ọlọla Raṣidi Ladọja lọ. Meloo leeyan yoo ka ninu eyin adipele ni, ti inu ọrun, ti ode ọjọ, ọtalelegbeje erigi lo si fi ori mulẹ ti ko yọ jade rara. Ohun to mu ọrọ baba yii yatọ ni pe ohun kan naa ni wọn n wa kiri, bi wọn yoo ṣe di gomina Ọyọ ni. Bi wọn ba da ẹgbẹ kan silẹ, ti wọn si n ṣe e to n dara lọ, tabi ti wọn ba wa ninu ẹgbẹ kan ti wọn ti jọ n ṣe aṣepọ, ti awọn eeyan si ti n ro pe kinni naa yoo ṣee ṣe lasiko yii, to ba si i. Ko si awọn oponu eeyan to ju ẹni to ba n sọ lati kawe loru, to le ji ni fẹẹrẹ ko ronu, ti oorun ti yoo sun le ma ju wakati mẹta lọ lọjọ mi-in, iru ẹni bẹẹ lo le ṣejọba ko dara, nitori pe iṣẹ rẹpẹtẹ lo wa nilẹ ti ẹnikẹni ko ti i ṣe. Ki Ladọja too ni isinmi, o di ọjọ to ba gba pe oun ko le ṣe gomina mọ, to duro sidii ẹgbẹ oṣelu kan, to si fa awọn ọmọ keekeekee kalẹ, to n fun wọn nimọran to dara. Ẹni to ba si n ti baba yii pe afi ko tun ṣe gomina Ọyọ, oluwa-rẹ kan fẹẹ pa baba onibaba ni. Iyẹn ko si daa, nitori ẹni to ba paayan, wọn yoo pa oun naa ni o. Ṣikeena!

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.