Asọtẹlẹ fun ọdun 2019 Apostle Johnson Suleiman, ti ijọ Omega Fire Ministries

Spread the love
 • Ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ ASUU yoo ku.
 • Eto idibo ọdun yii yoo lọwọ kan eeru ninu.
 • Donald Trump, olori orileede ilẹ Amẹrika, ko ni i wọle saa keji.
 • Ọsan yoo doru lawọn apa ibi kan.
 • Eto idibo ọdun yii yoo jẹ laarin awọn araalu ati awọn ṣọja pẹlu ọlọpaa.
 • Ọkan pataki ninu awọn ajafẹtọọ ọmọniyan yoo koju ija si aarẹ orileede yii.
 • Awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ lọdun yii yoo ja awọn gomina ipinlẹ kan laya.
 • Aarẹ Muhammadu Buhari nilo adura lọpọlọpọ, koda, o yẹ ko lọọ fun ara nisinmi ni.
 • Ẹya Igbo lo maa jẹ aarẹ lọdun 2023.
 • Ki Aṣiwaju Bọla Tinubu gbagbe nipa ọdun 2023.
 • Awọn oṣiṣẹ eleto aabo maa gbe oludije fun ipo aarẹ kan
 • Ikọ Boko Haram yoo ṣakọlu si teṣan ọlọpaa kan.
 • Gbajumọ oloṣelu kan yoo sọnu, wọn ko si ni i ri i.
 • Ẹgbẹ oṣelu APC lo maa jawe olubori ni apa guusu orileede yii.
 • Ina yoo ṣẹ yọ nileeṣẹ iroyin kan lorileede yii.
 • Aarẹ Donald Trump yoo fidirẹmi nibi erongba rẹ lati dije dupo ni****
 • Ki orileede yii gbadura gidi nitori itajẹsilẹ yoo ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers lọdun yii.

Pasitọ E. A Adeboye ti ijọ Ridiimu

Pasitọ Adeboye, ti ijọ Ridiimu, sọ pe lowe-lowe loun yoo sọ asọtẹlẹ oun ti ọdun yii, nitori ẹru awọn oloṣelu n ba oun, ki wọn ma lọọ sọ ohun ti oun ko sọ, paapaa julọ to jẹ pe asiko oṣelu la wa yii. Awọn ẹsẹ Bibeli ni Baba Adeboye, ẹni ti awọn ọmọ ijọ rẹ maa n pe ni ‘Daddy G.O’, fi sọ ti ọdun yii. Awọn ohun to sọ niyi:

Fun bi ọdun yii yoo ṣe ri fun orileede yii: Iwe Ẹkun Jerimiah, ori kẹta, ẹsẹ kejilelogun si ikẹtalelogun.

Fun ẹni kọọkan: Iwe Isaiah ori kẹta, ẹsẹ kẹwaa si ikọkanla.

Bakan naa ni Adeboye sọ pe ki gbogbo awọn to n gbadura fun aanu Ọlọrun ma ṣe kaaarẹ rara, nitori lọdun yii, Ọlọrun yoo ṣaanu ọpọ eeyan.

Pasitọ D.K Olukọya, ti ijọ Mountain of fire

 • Ọlọrun ni ki n kilọ fun awọn ọdọ lati ṣọra, ki wọn ma baa parun lati ipasẹ ibalopo lọdun yii, nitori Ọlọrun ti ran awọn ẹmi ti yoo fiya jẹ awọn to ba n ṣe iwa agbere tabi awọn iwa ẹṣẹ to jẹ mọ ibalopọ.
 • Ọdun 2019 jẹ ọdun kan to yatọ gedengbe si awọn ọdun to ku, fun idi eyi, ki kaluku mura lati gbadura lọna ara ọtọ.
 • Awọn aṣiri ti yoo ṣe ọpọlọpọ ni kayeefi ni yoo tu jade lọdun yii.
 • Ki awọn eeyan gbadura ki wọn ma ri ẹkun omi lọdun yii.
 • Bakan naa lo ni gbogbo awọn to ṣoogun owo ni wọn yoo faragba ina Ọlọrun lọdun yii.

 

 

 

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.