Asiko niyi fun Sarakai lati gbalu, ko maa jo

Spread the love

Ko sẹni ti ko ya lẹnu nigba ti iroyin jade pe olori awọn adigunjale ti wọn pawọn eeyan mọkanlelọgbọn nipakupa ni ilu Ọffa lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun yii, Michael Adikwu, ti ku sọgba awọn ọlọpaa. Bawọn kan ti n ni wọn lu u pa ni lawọn mi-in n ni amuwa Ọlọrun niku ẹ. Ọna yoowu ki iku rẹ jẹ ṣaa, ohun to ṣẹlẹ ni pe iku naa ko daa rara. O fi iku ṣefa jẹ ni, nitori niṣe lo yẹ ko rare ku, ko lo bii ọdun mẹwaa nibi to ti n rare, ko too waa di pe iku oro pa oun naa. Ṣugbọn wọn lo ti ku bayii. Ko si si ki awọn eeyan ma fura tabi ki wọn ma sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa iku ọmọkunrin yii, nitori lati ibẹrẹ, ọwọ oṣelu lawọn ọlọpaa ti bọ ọrọ yii. Ọrọ ti ko yẹ ko la ariyanjiyan ninu, awọn eeyan jale, wọn digun jale, wọn paayan pupọ, wọn ri wọn ko, wọn si jẹwọ, ki waa lo yẹ ko fa ariwo ninu iyẹn. Ṣugbọn nitori pe awọn ọlọpaa Naijiria n wa ọna lati ti ọran naa mọ Saraki ti i ṣe olori ile igbimọ aṣofin lọrun, wọn fi ẹtẹ silẹ, wọn n pa lapalapa kiri. Wọn ni awọn ti awọn mu, awọn tọọgi ti Saraki n lo fun oṣelu rẹ ni, o si ṣee ṣe ko jẹ oun lo ran wọn lati lọọ jale. Iyẹn ni wọn ṣe fẹẹ mu Saraki, wọn fẹẹ ti i mọle, ki Idris to jẹ ọga awọn ọlọpaa pata le sọ pe ṣe Saraki naa ri i pe Ọlọrun ti mu oun. Nitori pe Saraki jẹ oloṣelu, o dọgbọn dọgbọn, wọn ko ri i mu, o si pada yọ mọ wọn lọwọ. Ni bayii, minisita ati olootu eto idajọ nilẹ yii, Malami ti kọwe si awọn ọga ọlọpaa yii kan naa pe Saraki ko mọ ọwọ mẹsẹ ninu ọrọ naa rara, ko si eyi to kan an ninu pe awọn tọọgi Kwara lọọ jale nibi kan. Were eeyan paapaa mọ eleyii tẹlẹ, wọn mọ pe ọrọ naa ko kan Saraki, wọn mọ pe oṣelu loun n ṣe, koda ko jẹ oṣelu ole, tijẹkujẹ ati lilo ọmọọta ni. Gbogbo oloṣelu lo n lo tọọgi, koda Buhari ni awọn tọọgi ti wọn le fi ẹmi ara wọn lelẹ nitori rẹ, o si niye awọn to ku ni ọdun 2011, nigba ti ko wọle. Ọga ọlọpaa naa mọ, o kan fẹẹ fi okun we Saraki lọrun ni. Ṣugbọn ninu gbogbo eleyii, awọn araalu ni iya n jẹ. Awọn ara ilu Ọffa ni ẹgbin ọrọ naa n gun, gbogbo ọmọ Kwara ni kinni naa si n ba loju jẹ. Awọn ti wọn daran yii wa nitimọle, wọn ko dajọ wọn, bẹẹ ni ilu ko si mọ ododo nigba ti awọn adajọ ko ti i dajọ. Bi ẹlẹṣẹ ba ṣẹ, ti adajọ da a lẹbi ẹṣẹ rẹ, to si jiya to ba tọ si i, iyẹn ni i fi ọkan araalu balẹ, ki i ṣe ka ti ọrọ oṣelu bọ ọrọ ti ko ruju, ka waa sọ ọrọ naa di yẹbẹyẹbẹ. Iyẹn ki i jẹ ki ọkan awọn eeyan balẹ, nitori wọn yoo ri i pe ko si ibi ti mẹkunnu fẹẹ sa si. Ni bayii ti Saraki ti bọ ninu okun ti Idris, ọrẹ rẹ, dẹ silẹ fun un, afi ki oun naa gba ilu ko maa jo. Ṣugbọn gbogbo ọmọ Kwara ko gbọdọ sinmi o, awọn eeyan Ọffa paapaa ko gbọdọ sun, titi ti idajọ ododo yoo fi de, ti awọn oloriburuku ọmọ ole yii yoo fi gba idajọ to tọ si wọn.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.