Arẹgbẹṣọla n lọ o, ṣugbọn ….

Spread the love

Gbogbo ara ipinlẹ Ọṣun lo ti mọ bayii pe bi Gomina Rauf Arẹgbẹṣọla fẹ bo kọ, yoo gbejọba ipinlẹ naa silẹ lọdun yii, yẹkinni kan ko le yẹ ẹ mọ, nitori bi ofin Naijiria ti wi niyẹn. Awọn oloṣelu Ọṣun gbogbo naa ti mọ eyi, bi wọn ti n jade ninu APC ni wọn n jade ninu PDP, ati awọn ẹgbẹ mi-in teeyan ko tilẹ ti i mọ ibi ti awọn ti n ja bọ, gbogbo awọn ti wọn si n jade yii n mura lati waa di gomina ni. Amọ ọpọlọpọ awọn ti wọn n jade wọnyi, tabi awọn ti a ti n gbọ orukọ wọn, awọn to mọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe laarin wọn ko to nnkan, tabi ka tilẹ sọ pe awọn ti wọn ti ni orukọ daadaa nidii iṣẹ ilu ko pọ laarin wọn. Bẹẹ nibi ti ọrọ ipinlẹ Ọṣun wa bayii, ẹni to ba fẹẹ ṣe gomina nibẹ, afi ko mọ gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa, ko mọ iye gbese ti Gomina Arẹgbẹṣọla ti ko ipinlẹ Ọṣun si, ko mọ iye iwe adehun to ti tọwọ bọ, ko mọ boya gbese loun yoo fi gbogbo ọdun mẹrin oun san. Nitori ka sọ tootọ, gbese wa nilẹ, bii ẹgbẹlẹ ni. Awọn iṣẹ aṣepati wa nibẹ, awọn eto adawọle-ma-yọri naa si pọ to jẹ owo lo n da wọn duro. Gbogbo eleyii ni ẹni to ba fẹẹ waa ṣe gomina gbọdọ mọ, ko wadii, ko si ti mọ bi oun yoo ṣe ṣe e ti ijọba oun yoo fi tu araalu lara, ti wọn yoo si ni awọn anfaani ati oore ti wọn yoo ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ naa. Ẹni to ba jẹ ole, to jẹ owo ti yoo ko jẹ, tabi ọla to maa n wa lara awọn gomina nikan lo n wa, ki i ṣe ipinlẹ Ọṣun yii ni yoo ti ri iyẹn o, asiko yii kọ ni ko du ipo gomina rara. Bẹẹ ni ki ẹnikẹni ma gbajọba Ọṣun tan ko maa sọ pe oun ko mọ pe bẹẹ ni nnkan ti ri, oun ko mọ pe nnkan ti bajẹ to bẹẹ. Oun ni a n sọ ti a tun n tun sọ yii o, nnkan ti bajẹ kọja jinna, gbese pọ nilẹ, iṣoro oriṣiiriṣii lo wa, ẹni to ba lọgbọn ati imọ nipa ọrọ aje, to si mọ ọna ti ilu kekere fi n di nla lai jẹ ariwo ati ẹtan lasan nikan ni yoo le ṣe kinni naa yanju o. Nitori bẹẹ, gbogbo ẹyin ti ẹ fẹẹ ṣe gomina Ọṣun, ẹ mọ ohun ti ẹ n tẹri si lati ilẹ, ki ẹ mọ ohun ti ẹ fẹẹ ki ọrun bọ. A ko fẹ alaye iranu, ati ọrọ raurau kan lẹyin ti ijọba ba ti bọ si yin lọwọ tan o.

(123)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.