Arẹgbẹṣọla, ẹ tun kinni yii ro laarin ara yin

Spread the love

Ohun mẹta lo yọ silẹ fun ijọba ipinlẹ Ọṣun ati Ọyọ lati ṣe lori ọrọ ileewe ti wọn n pe ni LAUTECH, niluu Ogbomọṣọ. Akọkọ ni ki wọn maa ṣe kinni naa lọ bi wọn ti n ṣe e yii bi wọn ba ti mọ pe awọn yoo pese owo ti wọn yoo maa fi ṣakoso ati eto ileewe yunifasiti naa lọ. Ẹẹkeji ni ki awọn ijọba mejeeji jokoo, ki ijọba ipinlẹ Ọṣun kuku yọnda ileewe naa fun ijọba ipinlẹ Ọyọ, nitori Ọṣun ni yunifasiti tiwọn, Ọyọ ni ko da ni yunifasiti. Bi Ọyọ ti ko ni yunifasiti ba gba ileewe LAUTECH, nigba ti wọn ba mọ pe tawọn nikan ni, o ṣee ṣe ki wọn nawo rẹpẹtẹ si i, ki wọn si ṣe ileewe naa bii awọn ileewe giga to ku. Lọna kẹta, bi ko ba ṣee ṣe rara, ki wọn kuku lọ sọdọ ijọba apapọ, ki wọn bẹ wọn ki wọn gba ileewe naa lọwọ wọn. Idi pataki ti eyi fi yẹ bẹẹ ni pe ileewe naa ki i ṣe eyi ti awọn ijọba mejeeji yii gbọdọ jẹ ko ku mọ. O ti ni ọpọlọpọ ọmọ, awọn eeyan nla nla ti jade nileewe naa ti wọn si n gbe sabukeeti ibẹ kiri, bẹẹ ni orukọ ọkan pataki ninu awọn ọmọ Yoruba ni wọn fi n pe ileewe naa, orukọ Ladoke Akintọla. Iṣoro ti awa ri to n koju ileewe yii ju ko ju pe awọn ipinlẹ meji ni wọn n dari rẹ lọ, awọn mejeeji ko si fẹẹ fi owo silẹ, kaluku lo n sọ pe oun ni bukaata toun ti oun naa fẹẹ gbọ ni ipinlẹ oun. Bi nnkan “awa la ni in!” ṣe maa n ri niyi, nitori nnkan gbogbo wa ni ki i ni aṣeyọri kan bii nnkan tẹni funra ẹni. Ki awọn ijọba mejeeji yii too wa ni ipinlẹ naa ni wahala ti n ṣẹlẹ nibẹ, iyatọ to wa nibẹ ko kan ju pe nigba ti awọn APC n sọ pe awọn fẹẹ gbajọba, awọn gomina wọn leri pe ti awọn ba ti debẹ, awọn yoo tun LAUTECH ṣe, awọn yoo si maa ṣe akoso rẹ ti ẹnikẹni ko ni i gbọ ija awọn, wọn ni tiwọn ko ni i ri bii ti Alao Akala ati Ọlagunsoye Oyinlọla. Ṣugbọn ọdun kẹjọ ree lẹyin asọdun tawọn eeyan yii sọ nigba naa, aye si ti ri i pe ọrọ oṣelu lasan lo tẹnu wọn jade nigba naa. Ṣugbọn o ba ni ko bajẹ, Arẹgbẹ ti i ṣe gomina l’Ọṣun gbọdọ dide, ko si ba ẹni keji rẹ l’Ọyọ sọrọ, ki wọn jọ yanju ọrọ naa laarin ara wọn. Ki wọn ṣe ọkan ninu nnkan mẹta yii, ki isinmi ati idagbasoke le ba ileewe Ladoke Akintola University of Technology ti wọn n pe ni LAUTECH. Ẹ ma jẹ ki wọn ti yunifasiti naa pa lori yin o. Yoo ṣee ṣe lagbara awọn to nilẹ yii.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.