Arẹgbẹṣọla dolowo ojiji, o n na an yanfuyanfu

Spread the love

Awọn eeyan ro pe Gomina Raufu Arẹgbẹṣọla lahun ni, wọn ko mọ pe ko lahun, owo ni o si lọwọ rẹ. Asiko ti ibo sun mọle yii ni owo de, owo ta a wi yii naa si pọ lapọju. Kia lo ni ki wọn san owo-oṣu ti wọn jẹ awọn oṣiṣẹ, ki wọn si sanwo fun awọn to ti fẹyinti paapaa. Nigba to ṣe eleyii, ibo ku ọjọ mọkanla pere ni. Awọn oṣiṣẹ yoo gba owo wọn, wọn yoo si maa gbadun daadaa ki ọjọ ibo too pe, eleyii naa yoo tilẹ jẹ ki wọn ni okun ninu lati le lọọ dibo. Afi bii ẹni pe Arẹgbẹṣọla ti yi orukọ rẹ pada, o si ti sọ ara rẹ di akiri-ṣoore, nitori lọsẹ to kọja yii lo ko miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta (N500m) fun wọn ni ileewe LAUTECH, o ni ki wọn fi san awọn gbese wọn, ki wọn si maa na an diẹ diẹ titi ti owo nla mi-in yoo fi de. Ọrọ naa ya awọn eeyan lẹnu, Arẹgbẹ to ti ṣejọba fun bii ọdun mẹjọ, ti ko san owo-oṣu awọn oṣiṣẹ pe ri, ti ko si sanwo fawọn to ti fẹyinti, ti wọn pe e titi si ọrọ LAUTECH yii to ni oun ko lowo ti oun yoo fi ṣe e. Nibo ni owo ti waa de lojiji bayii o. Ko si ibi kan ti owo ti de lojiji bẹẹ ju pe ibo ti wọn fẹẹ di ni Satide yii lo fa owo wọle, ko si sẹnikan to mọ ibi ti owo naa ti wa. Bẹẹ ki i ṣe owo kekere o, nitori ogun biliọnu ni gomina yii gbe kalẹ pe ki wọn fi sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ, owo kekere si kọ niyẹn. Ibi yoowu ki owo yii ti wa ṣaa, afi keeyan kọkọ ba awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọṣun yọ, ka si ki wọn ku oriire, ki wọn yaa gba owo wọn ki wọn fi ṣe nnkan gidi, nitori awọn ni wọn ni in. Ṣugbọn ni ti gomina, bo ba jẹ oun naa lo wa owo yii jade, a jẹ pe ko ṣe daadaa fawọn eeyan rẹ, bo ba si jẹ ijọba apapọ, awọn Buhari, ti wọn ni wọn gbe owo wa naa ni wọn gbe e wa, eeyankeeyan lawọn naa. Bi wọn ba fẹran wọn l’Ọṣun ni, o yẹ ki wọn ti wa owo yii jade lati igba to pẹ, tabi awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ti wọn ti ku nibi ti wọn ti n reti owo ajẹmọnu wọn, ṣe owo yii wulo fun wọn mọ ni. Bẹẹ, owo ti wọn ko de yii ki i ṣe nitori ohun meji, ọrọ ibo ni, ẹtan lo ba de, wọn kan tun fẹẹ tan awọn araalu lẹẹkan si i ni. Bawo lawọn eeyan yii kuku ṣe ya bayii, o ti han pe wọn ko ni ọna mi-in ti wọn le fi wọle ibo ju ki wọn tan awọn eeyan lọ. Eleyii ko daa, nitori ohun gbogbo ta a ba gbe lori ẹtan ki i tọjọ, bẹẹ purọ n niyi, ẹtẹ lo n kangun rẹ. Ṣe awọn oloṣelu ilẹ Yoruba yii ko le ṣe ki wọn ma tan awọn eeyan jẹ ni. O ma ga o.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.