APC, PDP, ADC, SDP, igbe lẹnu fẹndọ yin

Spread the love

Awọn oloṣelu yii le paayan lẹrin-in ṣaa. Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC ati  PDP l’Ọṣun n pariwo, awọn ti SDP n sọrọ, koda awọn ADC naa n dundun ekute, wọn ni awọn lo yẹ ki awọn wọle ibo ana, eru wa nibi kan, ojooro wa nibi kan, wọn n ta ibo, wọn n ra ibo, nibi kan, ati awọn ọrọ runrun mi-in. Boya lawọn eeyan naa gbọ owe Yoruba to sọ pe “lara ija leyin wa” ri. Abi ki i ṣe ara ija ni, bija ba wọra tan, ti ẹni ti wọn n na deyin de ẹni to n na an, to ge e jẹ nibi ti ko daa, ti iyẹn sare ju u silẹ, ṣebi ọgbọn to mọ lo da yẹn. Ohun to maa n ṣẹlẹ ni pe awọn oloṣelu yii maa n jọ ara wọn loju, ẹni ti ko to ikan ninu wọn yoo si maa pe ara rẹ ni meji, nigba ti wọn ba si ti ri owo diẹ ha le awọn kan to wa nitosi wọn lọwọ, awọn yẹn yoo maa tan wọn, wọn yoo maa pe wọn ni Yọ-ẹsẹlẹnsi, nigba ti wọn mọ pe koda ki wọn maa fọn ipo gomina, wọn ko le fọn ọn ko kan wọn lara. N lawọn naa yoo ba maa gun lọrun-lọrun, wọn yoo ni awọn lawọn yoo wọle ibo ti awọn fẹẹ di, ero rẹpẹtẹ yoo pọ lẹyin awọn. Ṣugbọn nigba ti wọn ba dibo tan loju wọn yoo walẹ, wọn yoo ri i pe awọn ko ja mọ notin bii ọrọ awọn oloyinbo. Bawo ni iba ti rọrun to fun ẹgbẹ APC lati wọle ibo yii bi Adeoti ko ba lọ lẹyin wọn, bawo ni iba si ti rọrun to fun Adeoti funra rẹ lati beere ohun to ba fẹ lọwọ gomina to ba wọle, nigba to ba jẹ wọn jọ ja fun kinni ọhun ni. Tabi bawo ni yoo ṣe ri fun PDP bi Iyiọla Omiṣore ko ba ṣowo tirẹ lọtọ, bawo ni iba si ṣe ri fun Omiṣore to ba ṣiṣẹ ki gomina ẹgbẹ wọn wọle, yatọ si to fi lọọ da tirẹ silẹ, to si ja sọlọpọn. Bi ẹgbẹ ADC ati SDP ba parapọ ti wọn doju kọ APC tabi PDP l’Ọṣun, ibo meloo ni wọn fẹẹ ri mu, ka ma ti i waa sọ pe nigba ti wọn pin yẹlẹyẹlẹ, ti wọn pin ara wọn sọna meji, mẹta. Ariwo kinni wọn wa n pa pe awọn ko wọle! Bawo ni wọn aa ṣe wọle! Okete gbagbe iboosi, o de igba alatẹ o kawọ leri! Igbe lẹnu fẹndọ leleyii, awọn ti wọn ba fẹẹ ra beba nikan ni wọn yoo si jade bi fẹndọ ba n pariwo rẹ lọ. Ẹ lọọ bomi sara kẹ ẹ sun, eleyii ti bọ ralẹ na fun ọpọ awọn oloṣelu Ọṣun, to ba tun di ọdun mẹrin oni, wọn yoo na ọja tuntun, ẹ tete lọọ maa tuwo mi-in jọ. Ko ju bẹẹ lọ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.