APC Oke-Ogun kọyin si Gomina Ajimọbi, wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ ADC

Spread the love

Gbogbo asọtẹlẹ ti awọn eeyan n sọ nipa rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ pe afaimọ ki ẹgbẹ naa ma pin si meji bi Gomina Isiaka Ajimọbi ko ba wa nnkan ṣe si ọrọ igun Unity Forum inu ẹgbẹ naa to jẹ ti agbegbe Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ ti n wa si imuṣẹ o.

Ninu ipade ẹgbẹ naa to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ oṣu yii nile-ẹgbẹ wọn to wa laduugbo Apinitẹ niluu Ṣaki ni wọn ti pa ẹnu pọ pe awon yoo fi ẹgbẹ APC silẹ, latari bi awọn aṣiwaju ẹgbẹ ko ṣe wa ojutu si wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ, awọn yoo si lọ sinu ẹgbẹ mi-in to ba daa.

Ọkan lara agba ẹgbẹ, Alaaji Abu Gbadamọsi, ni, pẹlu bi wọn ṣe bura fun oloye Akin Oke ti igun SENACO awọn Ajimọbi fa kalẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ ti fihan pe ọwọ wọn lagbara ẹgbẹ wa.

O ni lara awọn nnkan to le fẹsẹ ẹgbẹ mulẹ ni ki ọmọ ẹgbẹ to ba fẹẹ dije fun oye kankan ninu ẹgbẹ lọọ gba fọọmu idije, ki wọn si ṣe eto idibo abẹle naa gẹgẹ bi ofin ẹgbẹ ṣe sọ. Ṣugbọn ikọ awọn Ajimọbi ko tẹle awọn ilana yii, niṣe ni Gomina kan kọ orukọ awọn to wu u fun ipo alaga kansu ati kansẹlọ, eyi to lodi sofin ẹgbẹ awọn.

Oloye Abu Gbadamọsi ni ohun to buru ju nibẹ ni pe, awọn ti Unity Forum ti awọn ra fọọmu, ti awọn si ṣe gbogbo nnkan ni ilana ti ẹgbẹ sọ ko rọna lọ, awọn ikọ SENACO ti ko ra fọọmu gan-an lo pada waa n jẹ anfaani ẹgbẹ.

Ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ lati ilu Oje-Owode, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki, Oloye Mayor Balogun, sọ pe igun Unity Forum ti kẹru wọn kuro ninu ẹgbẹ APC bayii o, inu ẹgbẹ oṣelu ADC ni wọn n lọ. O ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu mẹfa ni wọn pe awọn lati darapọ mọ wọn, ṣugbọn inu ẹgbẹ oṣelu ADC lawọn pada fẹnu ko si pe awọn n lọ gẹgẹ bii ẹgbẹ oniṣọkan, ẹgbẹ yii lawọn yoo ṣiṣẹ fun ninu eto idibo ọdun 2019 to n bọ, awọn yoo si lo eyi lati fi ajulọ han ẹgbẹ APC ti igun SENACO pe awọn ti Unity Forum gan-an lagba ẹgbẹ.

Ni bayii, idaamu ti de ba igun Ajimọbi lori igbesẹ ti igun Unity Forum gbe yii, bẹẹ ni wọn si n wo o pe o ṣee ṣe ki wọn bẹrẹ si i tako awọn loootọ lasiko ibo gomina to n bọ lọdun 2019.

(62)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.