APC lo ko gbogbo ibo kansu ipinlẹ Ọyọ *Ṣugbọn ija lawọn ọmọ ẹgbẹ naa n bara wọn ja

Spread the love

 

Ko ya ni lẹnu pe awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo wọle ninu idibo ijọba ibilẹ to waye ni ijọba ibilẹ mẹtẹẹlalelọgbọn (33) atawọn ijọba ibilẹ onidagbasoke maraarundinlogoji (35) to waye jake-jado ipinlẹ Ọyọ lọjọ kẹjila, oṣu karun-un, ọdun 2018 yii. Idi ni pe ọpọ eeyan ni ko jade dibo lọjọ naa.

Aijade dibo awọn eeyan paapaa ko ṣẹyin bi ẹgbẹ oṣelu PDP, Accord ati SDP ti wọn jẹ ọga awọn ẹgbẹ alatako ni ipinlẹ naa ko ṣe kopa ninu eto ọhun.

Ṣugbọn pẹlu bi ọsan ṣe so didun fun awọn ọmọ ẹgbẹ APC to ninu idibo yii, boya ni ko ni i jẹ idakeji rẹ ni yoo ṣẹlẹ si wọn lasiko idibo gbogboogbo ọdun to n bọ 2019. Idi ni pe ko si iṣọkan ninu ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ, ija ti wọn si n ba ara wọn ja paapaa ko fi han pe nnkan le ṣenuure fun wọn rara ninu idibo gomina atawọn aṣofin ipinlẹ naa lọdun to n bọ.

Eyi ko ṣeyin ija ajadiju ti awọn igun kan ti wọn n pe ni Unity Forum ninu ẹgbẹ naa n ba Ajimọbi atawọn eeyan rẹ ja lori agbara iṣakoso ẹgbẹ ọhun. Ija yii si le debii pe awọn igun to n ba gomina fa a yii ko da si ibo kansu ti wọn di kọja yii.

Lara awijare awọn eeyan yii ni pe wọn ko dibo abẹle lati fa awọn oluidije fun ipo kansilọ ati alaga kansu kalẹ, wọn ni Ajimọbi lo kan da yan awọn eeyan naa, ti ko si fun awọn agba ẹgbẹ kankan lanfaani lati lọwọ ninu rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu mejila pere lo kopa ninu idibo naa, ko si si awọn to laamilaaka ninu wọn. Awọn ẹgbẹ to kopa ninu idibo ọhun paapaa ko ni aṣoju ni ọpọlọpọ awọn ibudo idibo ti akọroyin wa de. Orukọ wọn gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe idibo ni ṣiṣẹ-n-tẹle ni: ANRP, ADP, APAP, APC, JMPP, KP, NRM, PDC, PPA, SPN, UDP ati YPP.

Ni igbaradi fun idibo yii, gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu wọnyi pẹlu ẹgbẹ PDP ni wọn ti jọ n ṣepade lori bi eto ọhun yoo ṣe kẹsẹjari, afi bi ibo ṣe ku ọtunla, ti awọn PDP sọ pe awọn ko ṣe mọ.

Alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Kunmi Mustapha, sọ ninu atẹjade to fi ṣowọ sawọn oniroyin n’Ibadan pe oun ko nigbagbọ ninu ajọ OYSIEC to fẹẹ ṣeto idibo ọhun, paapaa nitori bi alaga ajọ naa ṣe sọ pe idajọ ile-ẹjọ kankan ko le di oun lọwọ lati ṣeto idibo yii nigba ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ko gbọdọ ṣe e.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba Gomina Abiọla Ajimọbi fofin de igbokegbodo awọn ohun irinsẹ gbogbo jakejado ipinlẹ naa laarin aago mẹjọ aarọ di mẹta ọsan ti eto ọhun yoo pari, ọpọ eeyan ni ko tori ẹ jade dibo, inu ile ni wọn jokoo si.

Awọn ọdọkunrin nigboro Ibadan si lo oore-ọfẹ dida ti gbogbo titi da paroparo lati ṣere idaraya. Niṣe ni awọn titi kan nigboro ilu naa bii Mọkọla si Dugbẹ, atawọn titi ọlọda lawọn adugbo bii Oke-Ado, Agodi, Oniyanrin, Yemẹtu, Idi-Arẹrẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ di aaye igbabọọlu.

 

Idibo ọhun lọ ni irọwọrọsẹ to bẹẹ ti a ko gbọ iroyin to ni i ṣe pẹlu jiji apoti ibo gbe tabi awọn iṣẹlẹ idarudapọ to saaba maa n waye ninu idibo ijọba ibilẹ. Yatọ si awọn ibudo idibo bii Odò-Baalẹ ati Ìjokòdó, lagbegbe Sango, n’Ibadan, nibi ta a ti gbọ pe wọn ji apoti idibo gbe.

 

Ṣaaju ni alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Jide Ajeigbe, ti fi ọkan awọn oloṣelu balẹ pe oun ti ṣe gbogbo eto pari lati ri i pe eto idibo ọhun waye nirọwọ-rọsẹ.

Ṣugbọn nigba ti awọn oniroyin beere idi ti ko ṣe fi bẹẹ jọ pe idibo n waye, Ọgbẹni Ajeigbe sọ pe, “ojuṣe temi gẹgẹ bii alaga ajọ OYISIEC ni lati ṣagbekalẹ eto idibo, ki n si fun gbogbo awọn oludije ni anfaani kan naa lati ṣe daadaa nibi ibo. Gbogbo awọn ojuṣe wọnyi pata ni mo ti ṣe, o waa ku si awọn ẹgbẹ oṣelu lọwọ lati ṣe ipolongo ibo ati itaniji fawọn eeyan lati jade waa dibo.”

 

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti irori wọn yatọ si ti Gomina Ajimọbi atawọn eeyan ẹ ko kopa ninu idibo naa. Akọwe igun ti wọn n pe ni Unity Forum ninu ẹgbẹ ọhun, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun, sọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin pe dídágunlá ti awọn dágunlá si eto ọhun lo fa a ti ko fi jọ pe ibo waye lọjọ Satide, awọn ọmọ ẹgbẹ APC to faramọ kinni ọhun ko to nnkan.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aimọye igba la ti sọ ọ, pe ba a ba da ẹgbẹ oṣelu APC si ọna ọgọrun-un, awa ta a wa ni igun Unity Forum la ko ida aadọrin ninu ẹ, idibo to waye ni Satide yii ti tu aṣiri ohun ti awọn eeyan ko mọ tẹlẹ. Nnkan ko si gbọdọ ri bayii fun wa lasiko ibo ọdun 2019 to jẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako nla nla naa yoo kopa nibẹ.

“A nigbagbọ pe awọn adari apapọ ẹgbẹ yii yoo lo anfaani ohun to ṣẹlẹ lasiko ibo ijọba ibilẹ yii lati tete wa atunṣe si gbogbo aiṣedeede to wa ninu ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Ọyọ ṣaaju asiko ibo ọdun to n bọ.”

 

Lẹyin ti oun ati iyawo ẹ, Florence Ajimọbi, dibo tan ni ibudo idibo ogun, ni wọọdu kẹsan-an, eyi to wa ninu ọgba ileewe Community Grammar School, laduugbo Oluyole Estate, n’Ibadan, ni nnkan bii aago mejila aabọ ọsan, Gomina Ajimọbi fi idunnu ẹ han si bi eto idibo ọhun ṣe lọ nirọwọrọsẹ.

 

Ọdun 2007 ni idibo ijọba ibilẹ ti waye gbẹyin ni ipinlẹ Ọyọ lasiko ijọba Ọtunba Adebayọ Alao-Akala.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.