APC ko ni i ra ibo nibikibi–Ẹgbẹyẹmi

Spread the love

Lopin ọsẹ to kọja lawọn to n dupo ile igbimọ aṣofin agba ati aṣoju-ṣoju l’Abuja lati ẹkun idibo Aarin-Gbungbun Ekiti, Ọnarebu Michael Ọpẹyẹmi Bamidele, Ọnarebu Ṣọla Fatọba ati Ọnarebu Wunmi Ogunlọla, bẹrẹ ipolongo alajọṣe labẹ asia All Progressives Congress (APC).

Eto naa ni wọn gbe kalẹ lati ṣepolongo fun Bamidele to n lọ sile igbimọ aṣofin agba, Fatọba to n lọ sile igbimọ aṣoju-ṣofin pẹlu Ogunlọla to jẹ ojugba rẹ, awọn mẹtẹẹta lo si fẹẹ ṣoju awọn eeyan to wa ni wọọdu mẹtadinlọgọta nijọba ibilẹ Ado-Ekiti, Irẹpọdun/Ifẹlodun, Ijero, Ẹfọn ati Iwọ-Oorun Ekiti.

Igbakeji gomina Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ni wọn fi jẹ baba isalẹ eto naa, nigba ti Oloye J.F. Alake ati Oloye Rẹmi Oguntuaṣe jẹ alaga, tawọn bii Ọjọgbọn Adio Afọlayan, Oloye Rọpo Ige atawọn mi-in jẹ alakooso.

Nigba to n sọrọ lasiko ifilọlẹ igbimọ ọhun, Ẹgbẹyẹmi gba awọn ti wọn yan niyanju lati ṣiṣẹ takuntakun ju ti asiko ibo gomina lọ. O waa sọ gbangba pe ẹgbẹ APC ko ni i ra ibo lọjọ idibo nitori eto ti Gomina Kayọde Fayẹmi bẹrẹ l’Ekiti ti to lati ni atilẹyin araalu.

Bakan naa ni Barrister Paul Ọmọtọṣọ to jẹ alaga APC l’Ekiti sọ pe ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) ti fọ, idi niyi ti APC fi gbọdọ lo anfaani naa lati gba awọn ipo oṣelu ipinlẹ naa.

Ọpẹyẹmi Bamidele waa kadii eto naa nilẹ pẹlu alaye pe ipolongo alajọṣe yii lo daa ju nitori oriire APC ni afojusun gbogbo ọmọ ẹgbẹ, ki i ṣe ogo aladaani.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun to kọja, ni aṣita ibọn ọlọpaa adigboluja kan ba Ọpẹyẹmi Bamidele lasiko ifilọlẹ ipolongo ibo Gomina Kayọde Fayẹmi, ṣugbọn tori ko o yọ.

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.