APC kilọ fun Bọlarinwa: Ma pe ara rẹ ni alaga egbe wa mo to o ba fẹẹ ṣẹwọn

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Kwara ti Alhaji Ishọla Balogun-Fulani ko sodi ti ni Ọgbẹni Bashiru Bọlarinwa atawọn to n ko kiri n kọ lẹta si ẹwọn pẹlu bo ṣe n pe ara rẹ ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara lẹyin ti ile-ẹjọ ti fofin de wọn.

Wọn sọrọ ọhun ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lati ọwọ alukoro ẹgbẹ naa, Sulyman Buhari, lọsẹ to kọja.

O ni ile-ẹjọ ti paṣẹ fun Bọlarinwa atawọn yooku rẹ lati yee pe ara wọn ni oloye ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara. O fi kun un pe kootu naa ti paṣẹ pe igbimọ to n ṣakoso labẹ idari Ishọla Balogun-Fulani lo ni aṣẹ labẹ ofin lati tukọ ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Kwara, di ọdun 2022.

“Gbogbo araalu mọ pe Adajọ T.S Umar ti fofin de Bashiru Bọlarinwa atawọn eeyan rẹ lati ma pe ara wọn ni adari ẹgbẹ APC mọ, tabi kopa ninu ojuṣe to yẹ oloye ẹgbẹ.

“Ṣugbọn pẹlu aṣẹ ti ile-ẹjọ pa yii, iroyin to tẹ wa lọwọ fi han pe Bashiru Bọlarinwa ṣi n pe ara rẹ ni alaga APC nipinlẹ Kwara, lẹyin ti ile-ẹjọ ti da wọn lọwọ kọ. Eleyii fi han pe wọn ko bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ, nipa bayii, bebe ẹwọn ni wọn n rin.”

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.