Apaṣẹ da Ẹgbẹ Ọmọ Oodua silẹ, o ni oun ko se OPC mo

Spread the love

Adari ẹgbẹ Oodua People’s Congress (OPC) tẹlẹ l’Ekiti, Gbenga Adeniyi Adedipẹ tawọn eeyan mọ si Apaṣẹ, ti da ẹgbẹ tuntun mi-in silẹ to pe ni Ẹgbẹ Ọmọ Oodua, bẹẹ lo ni oun ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu OPC tabi Ọtunba Gani Adams to jẹ olori ẹgbẹ naa mọ.

Lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, lo ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun yii, eyi to jẹ ki iroyin bọ sigboro pe wahala mi-in tun ti fẹẹ bẹ silẹ laarin ẹgbẹ OPC l’Ekiti ati Naijiria lapapọ.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori igbesẹ to gbe ọhun, Apaṣẹ ni oun ti ṣe adari OPC to jẹ akojọpọ igun Ọtunba Gani Adams ati ti Dokita Frederick Faṣehun, ṣugbọn iwa anikanjọpọn awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa lo jẹ koun kuro nibẹ.

‘’Awọn adari OPC ko fẹran iran Yoruba, apo ara wọn ni wọn n ja fun. Nigba ti ko si aaye fun ọmọ Yoruba ninu ijọba Jonathan, Aṣiwaju Bọla Tinubu dide lati ja fun wa, ṣugbọn Ọtunba Gani Adams ati Gomina Ayọdele Fayoṣe bẹrẹ si i lo agbara ijọba lati da nnkan ru.

‘’Igba yẹn ni wọn ju emi atawọn to n ja fun Yoruba sẹwọn fun ọdun mẹta aabọ. Mo ti gba ominira bayii, mo si ti da ẹgbẹ temi silẹ. Lonii, mo fi OPC silẹ fun Gani Adams atawọn eeyan ẹ, mo di olori Ẹgbẹ Ọmọ Oodua to ti wa nipinlẹ mẹwaa ni Naijiria bayii.

‘’A ti fi orukọ ẹgbẹ yii silẹ lọdọ ijọba, ẹgbẹ All Progressives Congress la si n tẹle labẹ Aṣiwaju Tinubu, nitori awọn lọrọ Yoruba jẹ logun.

”Owo to le ni biliọnu mẹsan-an ni Ọtunba gba lọwọ ijọba Jonathan, oun lo fi ra ipo Aarẹ Ọna Kakanfo to wa. Ni bayii, mo fẹ ki gbogbo eeyan mọ bayii pe oun ati Gomina Ayọdele Fayoṣe n lepa ẹmi mi.’’

Nigba to n fesi sọrọ naa lorukọ Ọtunba Gani Adams, Ṣọla Ojo to jẹ adari OPC l’Ekiti sọ pe awọn ti le Apaṣẹ lẹgbẹ OPC lati ọdun 2014, nitori iwa ibajẹ to hu, ko si si nnkan to kan awọn pẹlu ẹgbẹ to lọọ da silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ”Lẹnu ọjọ mẹta yii lo lọọ ṣe ikede lori redio pe oun fẹẹ ṣepade kan lorukọ OPC, ṣugbọn kia la lọọ da ikede yẹn duro. Ọrọ ẹgbẹ tuntun yẹn ko kan wa, ko ṣaa ma lo orukọ Oodua. Ti ko ba yọ Oodua kuro ninu orukọ yẹn, orukọ OPC lo ṣi n lo.

”A ti gbe ọrọ yẹn lọ sọdọ kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, adari ikọ ọtẹlẹmuyẹ (DSS) atawọn agbofinro mi-in pe ko gbọdọ lo nnkan kan to ba jọ mọ ẹgbẹ wa ninu ẹgbẹ to da silẹ.”

Ibi tọrọ yii n lọ ko ti i ye ẹnikẹni, ọpọ eeyan lo si n woye pe o le da wahala mi-in silẹ, paapaa lasiko tọrọ oṣelu ti gbale-gboko nipinlẹ Ekiti yii.

 

(249)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.