Andrew to fipa ba tẹgbọn-taburo lo pọ ti wa lahaamọ

Spread the love

Kootu Majisreeti to wa l’Ogudu, niluu Eko, ti paṣẹ pe ki ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Andrew Chinedu, ṣi wa lahaamọ ọgba ẹwọn, wọn lo gbabale tẹgbọn-taburo tọjọ ori wọn jẹ mẹjọ ati mẹfa.

Agbefọba to n rojọ tako Andrew lasiko ti wọn moju rẹ ba kootu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, Insipẹktọ Lucky Ihiehie, sọ pe laarin oṣu kẹfa si oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, ni Andrew huwa naa laduugbo Abayọmi, Irawọ, ni Ikorodu. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣalaye pe ẹka to n ri si lilo ọmọde nilokulo nipinlẹ Eko fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin yii ti ṣe awọn ọmọ mejeeji niṣekuṣe, eyi lawọn ṣe gba baba awọn ọmọ naa nimọran pe ko mu ẹjọ wa si teṣan. Ihihie sọ pe ile kan naa ni Andrew ati baba awọn ọmọ yii n gbe. Lasiko ti wọn ni eyi ẹgbọn n jẹwọ fun awọn ọ̀ọpaa, o ni ṣe ni Andrew maa n pe oun wọ yara rẹ lasiko ti awọn obi oun ko ba ti si nile, yoo si ba oun lopọ. O ni ti oun ko ba gba fun un, ṣe lo maa n lu oun, to si jẹ pe o maa n ṣeleri lati ra suuti fun oun.

Ihiehie sọ pe ọmọ ọdun mẹfa naa sọ pe loootọ ni ọkunrin afurasi ọdaran yii maa n fipa ba awọn lo po, eyi ti agbefọba ni o tako abala iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo rẹ, tọdun 2015.

Adajọ E. Kubeinje, ẹni ti ko gba ipẹ Chinedu, paṣẹ pe ko wa latimọle ọgba ẹwọn di ogunjọ, oṣu kẹta, ọdun yii.

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.